ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/03 ojú ìwé 5
  • Aṣọ Tí Ó Wà Létòletò Ń Fi Hàn Pé A Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aṣọ Tí Ó Wà Létòletò Ń Fi Hàn Pé A Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwọṣọ àti Mímúra ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Múra Lọ́nà Tó Dára, Tó sì Gbayì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 9/03 ojú ìwé 5

Aṣọ Tí Ó Wà Létòletò Ń Fi Hàn Pé A Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run

1. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì àpéjọ àgbègbè wa tí ń bọ̀?

1 Láìpẹ́ Jèhófà yóò gbà wá lálejò ní Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” ti ọdún 2003. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà pè wá wá síbi àsè tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ bẹ́ẹ̀! A lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àti pé a mọrírì àwọn ohun tẹ̀mí tó pèsè fún wa nípa irú aṣọ tí a ó wọ̀ àti ọ̀nà tí a ó gbà múra.—Sm. 116:12, 17.

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká wà ní mímọ́ tónítóní kí ìmúra wa máà sì rí wúruwùru?

2 Mọ́ Tónítóní, Kí O sì Wà Létòlétò: Ó yẹ kí ìrísí wa gbé irú ẹni tí Ọlọ́run wa jẹ́ yọ, pé ó jẹ́ ẹni mímọ́ àti ẹni ètò. (1 Kọ́r. 14:33; 2 Kọ́r. 7:1) Ó yẹ kí àwa alára, irun wa àti èékánná wa mọ́ tónítóní, kí ìmúra wa má sì rí wúruwùru. Ìmúra jákujàku ni àṣà tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn lóde òní. Ṣùgbọ́n, pé gbajúmọ̀ òṣèré kan tàbí àwọn tó gbajúgbajà nídìí eré ìdárayá ń múra wúruwùru ò túmọ̀ sí pé kí Kristẹni kan máa wá múra lọ́nà yẹn. Bí a bá ń tẹ̀ lé àṣà aṣọ wíwọ̀ tó lòde, ó lè mú kó ṣòro fún àwọn èèyàn láti rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run tòótọ́ náà àtàwọn tí kò sìn ín.—Mál. 3:18.

3. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé a múra gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Tímótì 2:9, 10 ṣe sọ?

3 Ìmúra Tó Yẹ Àwọn Kristẹni Òjíṣẹ́: Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì tó jẹ́ Kristẹni alábòójútó, ó sọ pé kí “àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòlétò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, . . . lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.” (1 Tím. 2:9, 10) Kí aṣọ wa tó lè bójú mu, ó gba ìrònú gan-an. Kò yẹ kí aṣọ wa rí wúruwùru, ó yẹ kó mọ́ tónítóní, kó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kó má ṣe jẹ́ ti aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ tàbí kò dà bíi tàwọn oníṣekúṣe.—1 Pét. 3:3.

4, 5. Ìkìlọ̀ wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣègbọràn sí?

4 Pọ́ọ̀lù tún kìlọ̀ pé kò yẹ ká ṣàṣejù ní ti “àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an.” (1 Tím. 2:9) Ohun tó bọ́gbọ́n mu fáwọn obìnrin Kristẹni ni pé kí wọ́n wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ohun ọ̀ṣọ́, èròjà ìṣaralóge àtàwọn nǹkan mìíràn tá a fi ń ṣe ara lọ́ṣọ̀ọ́.—Òwe 11:2.

5 Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni obìnrin wúlò fún àwọn ọkùnrin Kristẹni pẹ̀lú. Ó yẹ kí àwọn arákùnrin yẹra fún àṣà tó bá ti ayé lọ. (1 Jòh. 2:16) Bí àpẹẹrẹ, ní àwọn orílẹ̀ èdè kan, àṣà tó wọ́pọ̀ ni pé káwọn èèyàn máa mọ̀ọ́mọ̀ wọ aṣọ tó tóbi jù wọ́n lọ, àmọ́ irú ìmúra yìí ò yẹ òjíṣẹ́ Ọlọ́run.

6. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká múra bí ọmọlúwàbí nígbà tá a bá ń lọ tàbí à ń bọ̀ láti àpéjọ, ní ibi àpéjọ àti lẹ́yìn ìpàdé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan? (b) Irú káàdì àyà wo ló yẹ ká lò?

6 Nígbà Tí A Bá Ń Ṣe Àwọn Nǹkan Míì Lẹ́yìn Ìpàdé: Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ń wá sí àpéjọ ló ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá dọ̀ràn aṣọ àti ìmúra. Àmọ́, ìròyìn ń fi hàn pé àwọn kan kì í bìkítà nípa ìmúra wọn nígbà tí wọ́n bá ń lọ tàbí wọ́n ń bọ̀ láti àpéjọ tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn nǹkan míì lẹ́yìn ìpàdé. Ní ti tòótọ́, ìrísí wa, yálà nígbà tá a bá wà nípàdé tàbí ní àwọn ìgbà mìíràn, máa ń ní ipa lórí ojú táwọn ẹlòmíràn fi ń wo àwọn èèyàn Ọlọ́run. Níwọ̀n bí a ti máa ń lo káàdì àyà tí a ṣe fún àpéjọ, ó yẹ ká máa múra lọ́nà tó yẹ Kristẹni òjíṣẹ́ nígbà gbogbo. (Kìkì káàdì àyà tí ètò àjọ ṣe nìkan ni ká lò. Nígbà kan, káàdì àyà tí kì í ṣe èyí tí ètò àjọ ṣe, tí àwọ̀ rẹ̀ àti ọ̀nà tá a gbà ṣe é yàtọ̀ làwọn kan lò. Ẹ má ṣe lo irú káàdì bẹ́ẹ̀. Bí ìjọ bá fẹ́ káàdì àyà àti ike káàdì sí i, kí wọ́n kọ̀wé béèrè fún un láti ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa lílo fọ́ọ̀mù Literature Request S-14.) Èyí sábà máa ń mú káwọn èèyàn yìn wá, ó sì máa ń mú kí àyè ṣí sílẹ̀ láti wàásù.—1 Kọ́r. 10:31-33.

7. Ipa wo ni aṣọ wa tó wà létòlétò lè ní lórí àwọn ẹlòmíràn?

7 Bí ẹ̀rín músẹ́ ṣe ń mú ojú wa dán, bẹ́ẹ̀ ni aṣọ tó wà létòlétò ṣe ń bu iyì kún ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀ àti ètò àjọ tá à ń ṣojú fún. Àwọn tí yóò rí wa nígbà Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” ti ọdún yìí lè fẹ́ láti béèrè ìdí tá a fi yàtọ̀, wọ́n sì lè wá sọ lẹ́yìn náà pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ [a sì ti rí i] pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.” (Sek. 8:23) Ǹjẹ́ kí irú aṣọ tá a wọ̀ àti ọ̀nà tí olúkúlùkù wa gbà múra fi hàn pé a bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Jẹ́ Kí Ìrísí Rẹ Buyì Kúnni

▪ Nígbà tó o bá ń lọ tàbí ò ń bọ̀ láti ibi àpéjọ

▪ Ní ibi àpéjọ

▪ Nígbà tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan míì lẹ́yìn ìpàdé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́