ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/04 ojú ìwé 6
  • Múra Lọ́nà Tó Dára, Tó sì Gbayì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Múra Lọ́nà Tó Dára, Tó sì Gbayì
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Aṣọ Tí Ó Wà Létòletò Ń Fi Hàn Pé A Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ẹ Máa Gbé Jèhófà Lárugẹ Nínú Ìjọ Ńlá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ǹjẹ́ Ìmúra Rẹ Ń Fògo fún Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 9/04 ojú ìwé 6

Múra Lọ́nà Tó Dára, Tó sì Gbayì

1. Bí a ṣe ń múra sílẹ̀ láti lọ sí àpéjọ àgbègbè, kí nìdí tó fi yẹ ká ronú nípa ìrísí wa?

1 “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mà ṣèèyàn o! Ọmọlúwàbí làwọn èèyàn yín, wọ́n sì ń wọṣọ tó bójú mu, kódà wọ́n tún ń bọ̀wọ̀ fúnni.” Ohun tí aṣojú òtẹ́ẹ̀lì kan sọ nìyẹn nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n lọ sí àpéjọ àgbègbè kan lọ́dún tó kọjá. Ní àpéjọ àgbègbè mìíràn, òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì kan sọ pé: “Ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn yín ń wọṣọ tí inú Ọlọ́run dùn sí.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn èèyàn ń kíyè sáwọn tó ń wá sí àpéjọ àgbègbè. Nítorí náà, ó yẹ ká wọṣọ “lọ́nà tí ó yẹ ìhìn rere.” Èyí sábà máa ń jẹ́ káwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí yìn wá, ó sì tún ń fi hàn gbangba pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run la jẹ́. (Fílí. 1:27) Bí a ṣe ń múra sílẹ̀ láti lọ sí àpéjọ àgbègbè, ó yẹ ká ronú nípa ìrísí wa ṣáájú àkókò.

2. Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn láti wọṣọ àti láti múra lọ́nà mímọ́?

2 Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà.” (Ják. 3:17) Kì í sábà rọrùn láti múra lọ́nà mímọ́. Ayé oníwà pálapàla tí Sátánì ń ṣàkóso ló ń mú káwọn èèyàn máa wọ aṣọkáṣọ, aṣọ tí kò bójú mu. (1 Jòh. 2:15-17) Nítorí náà, nígbà tá a bá ń ronú nípa aṣọ àti ìmúra wa, ó yẹ ká fiyè sí ìmọ̀ràn Bíbélì pé ká “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú . . . nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Títù 2:12) Ẹ má ṣe jẹ́ ká fi ìrísí wa dá ọkàn àwọn ẹlòmíràn láàmú láé, yálà àwọn arákùnrin wa ni o, àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì tàbí ilé oúnjẹ ni o, tàbí àwọn ẹlòmíràn tí ń kíyè sí wa.—1 Kọ́r. 10:32, 33.

3. Àwọn ìbéèrè wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti yẹ bí ìrísí wa ṣe rí wò?

3 Aṣọ Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì, Tó sì Wà Létòlétò: Nígbà tó o bá ń múra sílẹ̀ fún àpéjọ, bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ aṣọ mi wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, àbí ńṣe ló máa jẹ́ káwọn èèyàn máa fi ojú tí kò tọ́ wò mí? Ǹjẹ́ ó fi hàn pé mo gba tàwọn ẹlòmíràn rò? Ǹjẹ́ ẹ̀wù mi ò ti lọ sílẹ̀ jù níbi igbáàyà tàbí kò délẹ̀ tó? Ǹjẹ́ aṣọ mi ń ṣí ara mi sílẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ tàbí ó ti fún pinpin mọ́ mi lára jù? Ṣé aṣọ mi mọ́, ṣé kò sì máa rùn? Nígbà tí mo bá lọ jẹun ní òtẹ́ẹ̀lì tàbí nílé oúnjẹ, tàbí tí mò ń sinmi lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ, ǹjẹ́ aṣọ tí mo fẹ́ wọ̀ á mọ́ tónítóní, á sì bójú mu, àbí ńṣe ló máa rí wúruwùru, tàbí kó jẹ́ aṣọ ìgbàlódé tí ò bójú mu fún ẹni tó wá sí àpéjọ tó lo káàdì àyà? Ǹjẹ́ aṣọ tí mo máa wọ̀ lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ á jẹ́ kí ojú tì mí ká ní mo fẹ́ jẹ́rìí fáwọn èèyàn níbikíbi tí mo bá ti rí wọn?’—Róòmù 15:2, 3; 1 Tím. 2:9.

4. Báwo làwọn ẹlòmíràn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè múra lọ́nà mímọ́?

4 Ìmọ̀ràn àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú yóò ṣe wá láǹfààní. Kí àwọn aya bi ọkọ wọn nípa ojú táwọn ẹlòmíràn lè fi wo aṣọ tí wọ́n bá wọ̀. Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lè ran àwọn ọ̀dọ́langba wọn lọ́wọ́ lórí èyí. Síwájú sí i, àwọn àgbà obìnrin tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn lè “pe orí àwọn ọ̀dọ́bìnrin wálé . . . láti jẹ́ ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, oníwà mímọ́” nínú ìmúra wọn “kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.” (Títù 2:3-5) Bó o bá wo àwọn ìwé wa, wàá rí àwọn àwòrán tó lè jẹ́ ká mọ irú aṣọ tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó sì wà létòlétò.

5. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè mú ìyìn bá Jèhófà nígbà àpéjọ?

5 Mú Ìyìn Bá Jèhófà: Yàtọ̀ sáwọn tó ń kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ, gbogbo wa ni àpéjọ àgbègbè ń fún ní àǹfààní àtàtà láti yin Jèhófà. Òótọ́ ni pé ìwà àti ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni ń bọlá fún un. Àmọ́, ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kíyè sí wa máa ń kọ́kọ́ rí ni aṣọ tá a wọ̀ àti bá a ṣe múra. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa mú ìyìn bá Jèhófà nípa jíjẹ́ kí ìmúra wa dára, kó sì gbayì.—Sm. 148:12, 13.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ohun Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Kí Ìmúra Wa Lè Gbayì

◼ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

◼ Yíyẹ ara wa wò

◼ Àkíyèsí àwọn ẹlòmíràn

◼ Ìwé àwa Kristẹni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́