ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/05 ojú ìwé 4-5
  • Ẹ Máa Gbé Jèhófà Lárugẹ Nínú Ìjọ Ńlá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Gbé Jèhófà Lárugẹ Nínú Ìjọ Ńlá
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn Nípa Ṣíṣe Ohun Tó Buyì Kún Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpéjọ Àgbègbè Jẹ́ Àkókò Ìjọsìn Aláyọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ṣó O Ti Múra Tán Láti Jẹ Àsè Tẹ̀mí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 9/05 ojú ìwé 4-5

Ẹ Máa Gbé Jèhófà Lárugẹ Nínú Ìjọ Ńlá

1, 2. Àǹfààní wo ni àpéjọ àgbègbè máa ń fún wa, báwo la sì ṣe lè lo àǹfààní yìí lọ́nà rere?

1 Àwọn àpéjọ àgbègbè tá à ń ṣe lọ́dọọdún ń fún wa láǹfààní àgbàyanu láti yin Jèhófà lógo. Bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa náà ló ṣe rí lára Dáfídì nígbà tó kọrin pé: “Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ nínú ìjọ ńlá; èmi yóò máa yìn ọ́ láàárín àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye.” (Sm. 35:18) Ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run,” tá à ń wọ̀nà fún, báwo la ṣe lè rí i dájú pé à ń yin Jèhófà lógo gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tó wà ní ìṣọ̀kan?

2 Ìwà wa àti ìmúra wa tún jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà máa yin Jèhófà lógo. Ìgbìmọ̀ àpéjọ níbì kan tá a ti ṣe àpéjọ àgbègbè sọ pé: “Àwọn ará wọṣọ wọ́n sì múra lọ́nà tó dáa. Àwọn àtàwọn ọmọ wọn tètè dé sórí ìjókòó, wọ́n sì hùwà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ títí tí àpéjọ àgbègbè fi parí.” Nípa ìmúra wa, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa, àti ìwà wa, gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè ṣe ipá tiwa láti mú káwọn èèyàn máa tipasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípa wa yin Jèhófà lógo, nítorí pé irú ìyìn bẹ́ẹ̀ tọ́ sí Ọlọ́run wa.—1 Pét. 2:12.

3, 4. Báwo ni wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì á ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti máa múra lọ́nà tó yẹ àwọn Kristẹni òjíṣẹ́, yálà ní àpéjọ tàbí lẹ́yìn tí àpéjọ bá parí?

3 Ìrísí Wa: Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ló lè mú ká wọṣọ ká sì túnra ṣe lọ́nà tí yóò mú ìyìn wá bá Jèhófà. (1 Tím. 2:9) Lójú ìwé 132, ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà ò ní fẹ́ kóun máa mọ̀ọ́mọ̀ mú àwọn ẹlòmíràn bínú, kò sì ní fẹ́ kóun máa pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara òun.” Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ó ti dàṣà àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa wọṣọ tí kò bojú mu. Àmọ́, Jèhófà mọrírì bá a ṣe ń sapá láti máa ṣojú fún òun lọ́nà tó bójú mu. (Ìṣe 15:14) Nígbà tá a bá pé jọ síwájú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tó máa buyì kún Ẹni gíga jù lọ láyé àti lọ́run. (1 Kíró. 29:11) Fún ìdí èyí, kò ní bójú mu fún wa láti máa lo báàgì, ẹ̀wù tàbí àwọn nǹkan míì tí wọ́n fi ń polówó sìgá àtàwọn ohun èlò míì tí wọ́n fi ń polówó ọjà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í mu sìgá.

4 Ó tún yẹ ká fiyè sí irú aṣọ tá à ń wọ̀ lẹ́yìn tí ìpàdé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bá parí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè fẹ́ láti wọ aṣọ ìṣeré nígbà tá a bá ń najú tàbí nígbà tá a bá fẹ́ lọ wá nǹkan jẹ nílé oúnjẹ, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì pé kí aṣọ wa àti ìmúra wa rí bíi tàwọn “tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” (1 Tím. 2:10) Kì í ṣe ìmúra tó gbajúmọ̀ nínú ayé ló yẹ ká fi pinnu irú aṣọ tó yẹ ká máa wọ̀. (1 Jòh. 2:16, 17) Àwòrán àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó wọṣọ níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó bá onírúurú ipò mu, tó sì rí nigínnigín wà nínú àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ń ṣe jáde. Bá a bá tún ń lo káàdì tá à ń lẹ̀ máyà nígbà tá a bá wà ní ìlú ibi tá a ti ń ṣe àpéjọ, á máa rán wa létí ní gbogbo ìgbà pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni wá.—2 Kọ́r. 6:3, 4.

5, 6. Báwo la ṣe lè máa fọ̀wọ̀ hàn fún tábìlì tẹ̀mí ti Jèhófà?

5 Ẹ Máa Bọ̀wọ̀ fún Tábìlì Jèhófà: Olúwa ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run ti tẹ́ tábìlì oúnjẹ síwájú wa. (Aísá. 25:6; 1 Kọ́r. 10:21) Bá a bá ní ìmọrírì gíga fún àǹfààní tá a ní láti jẹun lórí tábìlì tẹ̀mí ti Jèhófà, kò sí ohun tí yóò dí wa lọ́wọ́ tá ò fi ní wà níbẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọ náà. Ṣó o ti ṣètò ilé tó o máa dé sí, ọkọ̀ tí wàá wọ̀, àti bó o ṣe máa gbàyè lẹ́nu iṣẹ́? Ṣó o ti ya àkókò sọ́tọ̀ fún mímúra sílẹ̀ àti rírìnrìn-àjò kó o bàa lè tètè dé síbi tá a ó ti ṣe àpéjọ kó o lè ríbi jókòó, kó o lè bá àwọn ará fara rora, kẹ́ ẹ sì jọ fi orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ yin Jèhófà?—Sm. 147:1.

6 Ọ̀wọ̀ tá a ní fún tábìlì Jèhófà á sún wa láti tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́ kò sì ní jẹ́ ká máa báwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ wótòwótò, ká máa jẹun, tàbí ká máa rìn káàkiri Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Àwọn òbí kò gbọ́dọ̀ wọ bàtà tó máa ń dún tàbí ohunkóhun tó ba fara jọ irú bàtà bẹ́ẹ̀ fáwọn ọmọ wọn kéékèèké nítorí pé wọn kì í jẹ́ káwọn èèyàn pọkàn pọ̀. Lákòókò tiwa yìí, Jèhófà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tá a nílò nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye. (Mát. 24:45) Kí ẹnikẹ́ni nínú wa má ṣe jẹ́ kí apá èyíkéyìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fo òun ru. Kí ẹ̀yin òbí jókòó ti àwọn ọmọ yín kẹ́ ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jàǹfààní kíkún rẹ́rẹ́.—Diu. 31:12.

7. Kí là ń fẹ́ kí gbogbo wa ṣe lákòókò oúnjẹ ọ̀sán, kí sì nìdí tá a fi fẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

7 A dá a lábàá pé kẹ́ ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán yín dání dípò tẹ́ ẹ ó fi fi Gbọ̀ngàn Àpéjọ sílẹ̀ láti wá oúnjẹ lọ síbòmíràn lákòókò ìsinmi ọ̀sán. À ń fi àkókò yìí lu ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ sí àpéjọ tọdún tó kọjá lọ́gọ ẹnu pé wọn ṣeun nítorí pé wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí. Á dára púpọ̀ gan-an ni bí olúkúlùkù bá tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dún yìí! Àmọ́, kí ẹ jọ̀wọ́ má ṣe gbàgbé láti nu ohunkóhun tó bá dà sílẹ̀, kẹ́ ẹ sì rí sí i pé ilẹ̀ Gbọ̀ngàn Àpéjọ wà ní mímọ́ tónítóní. (Héb. 13:17) Ìṣètò yìí á mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tí ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn ará wa, á sì mú ká jọ máa wà ní ìṣọ̀kan àti ní àlàáfíà lọ́nà tó ń bọlá fún Jèhófà.—Sm. 133:1.

8, 9. Àǹfààní wo la tún máa ń ní láti yin Jèhófà ní àpéjọ àgbègbè?

8 Wíwàásù Láìjẹ́ bí Àṣà: Bá a bá ń lọ sí àpéjọ tàbí tá a bá ń darí bọ̀ látibẹ̀, ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa ń ní láti fi ètè wa yin Jèhófà. (Héb. 13:15) Yálà à ń jẹun nílé oúnjẹ ni o tàbí à ń bá onílé tàbí òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì kan sọ̀rọ̀, tàbí a wà nínú ọkọ̀ èrò, ẹ jẹ́ ká máa wá bá a ṣe lè jẹ́rìí fún wọn. Ọkàn wa máa ń kún fọ́fọ́ fáwọn ìsọfúnni ṣíṣeyebíye tá a ti gbọ́ ní àpéjọ. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká sọ àwọn ohun rere tá a ti gbọ́ náà fáwọn tá a bá bá pàdé níbikíbi.—1 Pét. 3:15.

9 Ara wa ti wà lọ́nà láti gbádùn àǹfààní tá a ní láti máa yin Jèhófà ní “àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.” (Sm. 26:12) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pawọ́ pọ̀ láti gbé Jèhófà ga ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè

◼ Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ: Àpéjọ á bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án kọjá ogun ìṣẹ́jú [9:20 a.m.] lówùúrọ̀ ọjọ́ Friday, á sì bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án géérégé [9:00 a.m.] lówùúrọ̀ ọjọ́ Sátidé àti Sunday. Ní ìṣẹ́jú díẹ̀ kí àpéjọ tó bẹ̀rẹ̀, alága á jókòó sórí pèpéle, orin Ìjọba Ọlọ́run á sì máa lọ lábẹ́lẹ̀ láti fi hàn pé àpéjọ máa tó bẹ̀rẹ̀. Olúkúlùkù ti gbọ́dọ̀ wa lórí ìjókòó lákòókò yẹn kí àpéjọ náà bàa lè bẹ̀rẹ̀ bó ṣe yẹ. Àpéjọ á parí ní agogo márùn-ún ku ìṣẹ́jú márùn-ún [4:55 p.m.] nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday, á parí ní agogo márùn-ún ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [4:35 p.m.] nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Sátidé, á sì parí ní agogo mẹ́rin ku ogún ìṣẹ́jú [3:40 p.m.] nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Sunday.

◼ Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Jọ̀wọ́, gbọ́ ohun tí àwọn tó ń bójú tó ibi ìgbọ́kọ̀sí bá sọ fún ọ kí gbogbo nǹkan lè wà létòlétò.

◼ Gbígba Ààyè Ìjókòó: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ kan náà, tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbé nínú ilé kan náà nìkan lo lè gba àyè sílẹ̀ fún.

◼ Fífowó Ṣètìlẹ́yìn: Owó kékeré kọ́ là ń ná kí àpéjọ àgbègbè tó lè wáyé. A lè fi ìmọrírì wa hàn nípa fífínnú fíndọ̀ fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tàbí ní àpéjọ àgbègbè. Bó o bá fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn ní àpéjọ àgbègbè, ẹni tó o máa kọ ọ́ síbẹ̀ pé kí wọ́n sanwó náà fún ni “Watch Tower.”

◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: A dá a lábàá pé kẹ́ ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tẹ́ ẹ ó fi fi Gbọ̀ngàn Àpéjọ sílẹ̀ láti lọ wá oúnjẹ rà lákòókò ìsinmi ọ̀sán. O lè jẹ oúnjẹ rẹ nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Jọ̀wọ́ má ṣe ṣe ilẹ̀ yánmọyànmọ, má sì ṣe já bébà tàbí ọ̀rá sílẹ̀. Bí gbogbo wa bá ń jẹun ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, a ó lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tí ń gbéni ró, a ó sì lè wà níbẹ̀ nígbà tí ìpàdé bá bẹ̀rẹ̀ lọ́sàn-án. Bó bá pọn dandan, ẹ lè gbé kúlà oúnjẹ kékeré táá ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó lọ sí àpéjọ. A ò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà oúnjẹ gbẹ̀ǹgbẹ̀ gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

◼ Gbígba Ohùn Sílẹ̀: A kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni so ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ èyíkéyìí mọ́ wáyà iná tàbí ti ẹ̀rọ tá à ń lò ní àpéjọ. Kí ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ lo ẹ̀rọ tó ń gbohùn sílẹ̀ rí i pé òun kò fi dí ẹlòmíì lọ́wọ́.

◼ Fọ́tò Yíyà: Bó o bá máa ya fọ́tò, má ṣe lo iná tó ń bù yẹ̀rì bí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́. Má ṣe kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti lọ ya fọ́tò nígbà tí àpéjọ ṣì ń lọ lọ́wọ́, má sì ṣe pe àwọn onífọ́tò wá sínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ.—Jòh. 2:16.

◼ Ẹ̀rọ Atanilólobó àti Fóònù Alágbèéká: Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ yìí dí àwọn ará lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀.

◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ fún olùtọ́jú èrò tó bá wà nítòsí, òun náà á sì sọ fún wọn ní Ẹ̀ka Ìtọ́jú Ojú Ẹsẹ̀ káwọn òṣìṣẹ́ àpéjọ wa tí wọ́n ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó kí wọ́n sì ṣèrànlọ́wọ́ tó bá yẹ kí wọ́n ṣe.

◼ Àwọn Ilé Elérò Púpọ̀: Fi èso tẹ̀mí sílò bó o bá ti dé sí ibi tí a ó ti ṣe àpéjọ, tí wọ́n sì ń fi ibi tó o máa dé sí hàn ọ́. Má ṣe dé sínú ilé elérò púpọ̀ tí wọ́n kọ́ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí kì í bá ṣe ibẹ̀ ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní kó o dé sí. Ibi tí wọ́n bá sọ pé o ti lè dáná nìkan ni kó o ti máa dáná o. A ti rí i gbọ́ pé àwọn kan máa ń dáná nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí kò fi hàn pé wọ́n ní ìmọrírì fáwọn nǹkan tẹ̀mí.—Lúùkù 10:38-42.

◼ Ìtẹ̀jáde Tuntun: Bẹ́ ẹ bá ń tò láti gba ìtẹ̀jáde tuntun, ẹ má ṣe máa dà gìrọ́gìrọ́, ẹ má ṣe máa ti ara yín, ẹ má sì ṣe rọ́ àwọn èèyàn. Ńṣe ni kẹ́ ẹ fẹ̀sọ̀ tò sórí ìlà. Àwa náà ń sapá láti rí i pé olúkúlùkù tó wá sípàdé rí àwọn ìtẹ̀jáde tuntun gbà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́