ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/09 ojú ìwé 1-6
  • Ṣó O Ti Múra Tán Láti Jẹ Àsè Tẹ̀mí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó O Ti Múra Tán Láti Jẹ Àsè Tẹ̀mí?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpéjọ Àgbègbè Jẹ́ Àkókò Ìjọsìn Aláyọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • A Máa Gbádùn Ìtura Nípa Tẹ̀mí fún Ọjọ́ Mẹ́ta
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn Nípa Ṣíṣe Ohun Tó Buyì Kún Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 9/09 ojú ìwé 1-6

Ṣó O Ti Múra Tán Láti Jẹ Àsè Tẹ̀mí?

1. Irú ìmúrasílẹ̀ wo lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣe fún àsè?

1 Ọ̀pọ̀ ìmúrasílẹ̀ lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè se àsè. Ó gbọ́dọ̀ ra àwọn èlò oúnjẹ, kó fi se oúnjẹ aládùn, ẹ̀yìn náà ló máa bu oúnjẹ náà fáwọn èèyàn. Ó gbọ́dọ̀ fètò sí bó ṣe máa bu oúnjẹ náà. Ó sì gbọ́dọ̀ wá ibi tó bójú mu tí wọ́n ti máa jẹ ẹ́. Àwọn tó máa jẹ oúnjẹ náà gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀, àgàgà tí ibi àsè náà bá jìn síbi tí wọ́n ń gbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ìsapá gidigidi káwọn ẹbí, ará àtọ̀rẹ́ tó lè jùmọ̀ jẹ oúnjẹ aládùn tó máa ṣara lóore, irú ìsapá bẹ́ẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Láìpẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa péjọ ní àwùjọ ńlá àti àwùjọ kéékèèké láti gbádùn àsè tẹ̀mí tí wọ́n ti ń wọ̀nà fún gidigidi, ìyẹn Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Ṣọ́nà!” A ti ṣiṣẹ́ ribiribi láti múra àpéjọ yìí sílẹ̀ kí gbogbo nǹkan bàa lè wà ní sẹpẹ́. Gbogbo wa la ké sí. Kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bàa lè wà níbẹ̀, ká sì jàǹfààní tó pọ̀ jù lọ, àwa náà gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀.—Òwe 21:5.

2. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká má bàa pa ọjọ́ kankan jẹ lára ọjọ́ tí àsè tẹ̀mí wa fi máa wáyé?

2 Jàǹfààní Tó Pọ̀ Jù Lọ: Ṣó o ti parí ètò tó ò ń ṣe kó o bàa lè wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tí àsè tẹ̀mí náà fi máa wáyé? Bó bá pọn dandan, fi tó ọ̀gá ẹ níbiiṣẹ́ létí pé o kò fẹ́ pa ọjọ́ kankan jẹ lára ọjọ́ tí àpéjọ náà fi máa wáyé, tó fi mọ́ ọjọ́ tó máa bẹ̀rẹ̀. Ṣó o ti ṣètò ọkọ̀ tó o máa wọ̀ lọ àti ibi tó o máa dé sí? Káwọn alàgbà rí i dájú pé àwọn pèsè ìrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera àtàwọn míì tó bá nílò ìrànlọ́wọ́.—Jer. 23:4; Gál. 6:10.

3. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ lọ sí àpéjọ tí a kò bá yàn wá sí?

3 Àpéjọ àgbáyé máa wáyé láwọn orílẹ̀-èdè kan. Ẹ má ṣe gbàgbé pé a ti yan àwọn ìjọ àtàwọn aṣojú tó máa lọ sáwọn àpéjọ àgbáyé. Ẹ̀ka ọ́fíísì ti fara balẹ̀ gbéṣirò lé iye àwọn èèyàn tí wọ́n fẹ́ kó lọ síbẹ̀, kí èrò má bàa pọ̀ ju iye ìjókòó tó wà níbẹ̀ àti iye yàrá òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n lè rí lò. Báwọn akéde bá lọ sí àpéjọ tí a kò yàn wọ́n sí, ńṣe ni èrò tó máa wà níbẹ̀ á pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.

4. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbára dì fún ìgbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan máa bẹ̀rẹ̀?

4 Múra sílẹ̀ kó o bàa lè máa tètè dé sí àpéjọ náà lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, kó o sì wá ibi tó o máa jókòó sí kí àpéjọ náà tó bẹ̀rẹ̀. Kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti wo àwọn ohun tó wà nínú ìwé ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Èyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti múra ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀ fún ohun táwọn olùbánisọ̀rọ̀ máa sọ. (Ẹ́sírà 7:10) Nígbà tí alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ní ká tẹ́tí sí ohùn orin tó máa ń ṣáájú ìtòlẹ́sẹẹsẹ, ẹ wà ní sẹpẹ́ láti gbádùn ohùn orin náà, kẹ́ ẹ sì gbára dì láti kópa nínú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀.

5. Báwo ni ìdílé wa ṣe lè jàǹfààní tó pọ̀ jù lọ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ?

5 Báwọn òbí bá jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́, ó máa ṣeé ṣe fún wọn láti rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ. (Diu. 31:12) A rọ olúkúlùkù láti máa fojú bá kíka Ìwé Mímọ́ lọ nínú Bíbélì tiwọn. Ṣíṣe àkọsílẹ̀ ṣókí tún lè ṣèrànwọ́ láti mú kó o pọkàn pọ̀. Tó bá yá, àwọn àkọsílẹ̀ náà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rántí àwọn kókó pàtàkì inú àsọyé náà. Ṣọ́ra fún títàkúrọ̀ sọ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́, má sì ṣe máa rìn lọ rìn bọ̀. Bó o bá ní tẹlifóònù alágbèéká, má ṣe jẹ́ kó pín ọkàn rẹ tàbí ọkàn àwọn ẹlòmíì níyà nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́. Lẹ́yìn àpéjọ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, o ò ṣe jíròrò àwọn ohun tó o gbádùn gan-an nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà pẹ̀lú àwọn míì?

6. Apá wo ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú àwọn àpéjọ wa, báwo la sì ṣe lè jẹ ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àǹfààní látinú apá yìí?

6 Ní àpéjọ àgbègbè, a máa ń láǹfààní láti gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, irú èyí tí kò wọ́pọ̀ nínú ayé. (Sm. 133:1-3; Máàkù 10:29, 30) O ò ṣe ní in lọ́kàn láti dojúlùmọ̀ ẹni tó bá jókòó tì ẹ́, kẹ́ ẹ sì jọ wọnú ìjíròrò lákòókò ìsinmi ọ̀sán? Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àǹfààní tó wà nínú gbígbé oúnjẹ níwọ̀nba wá sí àpéjọ àti jíjẹ ẹ́ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ dípò jíjáde lọ ra oúnjẹ níta. Rí i dájú pé o ò jẹ́ kí àǹfààní àtigbádùn pàṣípààrọ̀ ìṣírí pẹ̀lú àwọn ará fò ẹ́ ru.—Róòmù 1:11, 12.

7. Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo ló yẹ ká ṣe nípa irú aṣọ tó yẹ ká wọ̀?

7 Ìmúra: Ó gbàfiyèsí pé Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣe ìṣẹ́tí sétí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ wọn, kí wọ́n sì fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sókè ìṣẹ́tí apá gbígbárìyẹ̀ náà. (Núm. 15:37-41) Àmì tó ṣeé fojú rí yìí ló máa ń rán wọn létí pé wọ́n jẹ́ èèyàn tí Jèhófà yà sọ́tọ̀ láti sìn ín. Bákan náà ló rí pẹ̀lú àwa náà lónìí, ńṣe ni aṣọ tó buyì kúnni, tó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tá à ń wọ̀ lọ sí àpéjọ máa ń mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé. Ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro lèyí sì jẹ́ fáwọn tó ń wò wá, bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé a lọ sílé oúnjẹ lẹ́yìn àpéjọ. Torí náà, ẹ fara balẹ̀ ronú lórí irú aṣọ tẹ́ ẹ máa wọ̀.

8. Báwo la ṣe lè wàásù fáwọn èèyàn ní ìlú tí àpéjọ ti wáyé?

8 Jẹ́rìí: Bá a bá múra sílẹ̀, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn ní ìlú tí àpéjọ náà ti wáyé. Arákùnrin kan tóun àtìyàwó ẹ̀ lọ wá nǹkan jẹ ní búkà lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wulẹ̀ nàka sí báàjì tó fi sáyà, ó sì béèrè lọ́wọ́ ẹni tó gbé oúnjẹ fún wọn pé: “Ṣó o ti rí báàjì yìí láyà ọ̀pọ̀ èèyàn?” Ẹni náà fèsì pé òun ti kíyè sí i, àmọ́ òun ò mọ ohun tó mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fi irú báàjì kan náà sáyà. Bí ìjíròrò ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, arákùnrin yìí sì ké sí ẹni náà láti wá sí àpéjọ.

9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bí Jèhófà ṣe gbà wá lálejò?

9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará wa ló máa sọ àwọn àsọyé, tí wọ́n á sì bójú tó ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àtàwọn àṣefihàn, Baba wa ọ̀run, Jèhófà, ló ń fi ìfẹ́ pèsè àsè tẹ̀mí tó ń wáyé lọ́dọọdún yìí. (Aísá. 65:13, 14) Bá a bá ń pésẹ̀ síbẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, tá a sì ń jadùn oúnjẹ tẹ̀mí tí Ọlọ́run ti pèsè láti fi bọ́ wa yó, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì bí Jèhófà ṣe gbà wá lálejò. Ṣó o ti parí ètò tó ò ń ṣe kó o bàa lè pésẹ̀ síbẹ̀?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè

◼ Àkókò Ìpàdé: Aago mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú [9:20] ni àpéjọ á máa bẹ̀rẹ̀ láràárọ̀ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà tí wọ́n bá ti ṣèfilọ̀ ohùn orin tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ àpéjọ, ó yẹ kí olúkúlùkù wa lọ jókòó kí àpéjọ náà lè bẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ á parí ní aago márùn-ún ku ìṣẹ́jú márùn-ún [4:55] ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday àti ọjọ́ Sátidé, á sì parí ní aago mẹ́rin [4:00] ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ Sunday. Láwọn ibi tí àpéjọ àgbáyé á ti wáyé, àpéjọ ti ọjọ́ Thursday máa bẹ̀rẹ̀ ní aago kan kọjá ogún ìṣẹ́jú [1:20] ní ọ̀sán, ó sì máa parí ní aago márùn-ún ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [4:45] ní ìrọ̀lẹ́.

◼ Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Ní gbogbo ibi tí àpéjọ ti máa wáyé, àwọn olùtọ́jú èrò máa darí wa síbi tá a máa gbé ọkọ̀ wa sí. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 14:40.

◼ Àwọn Tó O Lè Gbàyè Sílẹ̀ Fún: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ kan náà, tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbé nínú ilé kan náà nìkan lo lè gbàyè sílẹ̀ fún.

◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Ẹ jọ̀wọ́ ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tẹ́ ẹ fi máa kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti lọ wá oúnjẹ rà lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó máa ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. A kò sì gba ọtí líle láyè.

◼ Ọrẹ: A lè fi hàn pé a mọrírì ètò tá a ṣe láti mú kí àpéjọ yìí wáyé bá a bá fínnú fíndọ̀ fowó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tàbí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Kí ẹni tó bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn ní àpéjọ àgbègbè fi hàn pé ètò Ọlọ́run ni òun fẹ́ kí wọ́n sanwó náà fún nípa kíkọ “Watch Tower” sórí sọ̀wédowó náà. Kẹ́ni náà kọ Watch àti Tower lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o, kó má ṣe kọ ọ́ pa pọ̀.

◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ fún olùtọ́jú èrò tó bá wà nítòsí, ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti gbé aláìlera náà lọ sí Ẹ̀ka Ìtọ́jú Pàjáwìrì káwọn òṣìṣẹ́ àpéjọ wa tí wọ́n ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó, kí wọ́n bàa lè ṣèrànlọ́wọ́ tó bá yẹ kí wọ́n ṣe.

◼ Gbígba Ohùn Sílẹ̀: A kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni so ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ èyíkéyìí mọ́ wáyà iná tàbí ti ẹ̀rọ tá à ń lò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, kí ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ lo ẹ̀rọ tó ń gbohùn sílẹ̀ rí i pé òun ò fi dí ẹlòmíì lọ́wọ́.

◼ Kẹ̀kẹ́ Tí Wọ́n Fi Ń Ti Àwọn Ọmọ Ọwọ́ Kiri: A kò fàyè gba kẹ̀kẹ́ tí wọ́n fi ń ti àwọn ọmọ ọwọ́ kiri ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Àmọ́, ẹ lè lo bẹ́líìtì ààbò, èyí tí òbí lè dè mọ́ ara ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tá á wá gbé ọmọ sínú ẹ̀.

◼ Àwòkẹ́kọ̀ọ́: Ó máa fi hàn pé àwọn arábìnrin nífẹ̀ẹ́ àwọn ará bí wọn ò bá jẹ́ kí gèlè wọn ga débi tó fi máa dí àwọn tó bá jókòó sẹ́yìn wọn lójú lọ́sàn-án Sunday nígbà tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó mọ níwọ̀n tá à ń lò báyìí títí kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a tún lè lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ.—1 Kọ́r. 10:24.

◼ Lọ́fíńdà: Ó máa fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò tá ò bá lo àwọn lọ́fíńdà olóòórùn líle tó pọ̀ jù, torí èyí lè ṣàkóbá fún àwọn tó níṣòro èémí.—Fílí. 2:4.

◼ Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò: Bẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan nígbà àpéjọ àgbègbè tí ẹni náà sì fìfẹ́ hàn, ẹ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tá a fi ń kọ ìsọfúnni nípa èyí, ìyẹn fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43). Kí àwọn akéde mú fọ́ọ̀mù kan tàbí méjì wá sí àpéjọ. Ẹ lè mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ bá ti kọ ọ̀rọ̀ sí fún wọn ní Ilé Ìgbàwé tàbí kẹ́ ẹ fún akọ̀wé ìjọ yín nígbà tẹ́ ẹ bá pa dà délé.

◼ Búkà Oúnjẹ Àtàwọn Tó Ń Tajà Níwájú Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ẹ jẹ́ kí ìwà rere yín bọlá fún orúkọ Jèhófà tẹ́ ẹ bá wà láwọn búkà oúnjẹ. Kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu láti lọ ra oúnjẹ ní búkà tàbí lọ́wọ́ àwọn tó ń kiri ọjà nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́. Bí a bá rí ẹni tó fẹ́ ra ohunkóhun, ohun tó máa dáa jù lọ ni pé kó ṣe bẹ́ẹ̀ kí àpéjọ tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn tí àpéjọ bá ti parí.

◼ Ilé Gbígbé: (1) Fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù bó o bá ti dé síbi tí a ó ti ṣe àpéjọ, tí wọ́n sì ń fi ibi tó o máa dé sí hàn ẹ́. (2) Má ṣe dé sínú ilé tí wọ́n kọ́ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ò bá ní kó o dé síbẹ̀. Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn nípa dídé sí kìkì ibi tí wọ́n bá ní kó o dé sí. (3) Má ṣe jẹ́ kí ilẹ̀ ṣú ẹ sí yàrá tó wà fún àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin nìkan, o kò sì gbọ́dọ̀ sùn síbẹ̀. (4) Bí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú nípa ibi tí wọ́n fi ẹ́ sí, rí i dájú pé o tètè fi tó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé létí kó o tó kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. (5) Bó bá jẹ́ pé òtẹ́ẹ̀lì lo dé sí, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábòójútó òtẹ́ẹ̀lì náà. (6) Ibi tí wọ́n bá sọ pé o ti lè dáná nìkan ni kó o ti máa dáná. (7) Má ṣe dáná nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́, torí ìyẹn á fi hàn pé o kò ní ìmọrírì fáwọn nǹkan tẹ̀mí.—Lúùkù 10:38-42.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́