ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/12 ojú ìwé 1-4
  • Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Máa Gbádùn Ìtura Nípa Tẹ̀mí fún Ọjọ́ Mẹ́ta
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Fi Ìwà Rẹ Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpéjọ Àgbègbè Jẹ́ Àkókò Ìjọsìn Aláyọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • “Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 8/12 ojú ìwé 1-4

Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́

1. Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń láǹfààní láti ronú lé lórí kí wọ́n sì jíròrò nígbà àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún?

1 Láyé àtijọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kóra jọ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún láti ṣe àjọyọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin nìkan ni Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n wá síbi àjọyọ̀ yìí, gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ló sábà máa ń lọ sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè jọ gbádùn àjọyọ̀ náà. (Diu. 16:15, 16) Irú àwọn àjọyọ̀ yìí máa ń fún wọn láǹfààní láti ronú lórí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì kí wọ́n sì tún jọ jíròrò wọn. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ yìí? Ọ̀kan lára rẹ̀ ni pé, Jèhófà jẹ́ Olùpèsè tó lawọ́, tó sì nífẹ̀ẹ́. (Diu. 15:4, 5) Òmíràn ni pé Jèhófà jẹ́ afinimọ̀nà àti aláàbò tí kì í jáni kulẹ̀. (Diu. 32:9, 10) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún lè ronú lórí ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí pé àwọn gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbé ayé òdodo torí pé àwọn ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run. (Diu. 7:6, 11) Lóde òní, àwa náà ń jàǹfààní bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn àpéjọ àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún.

2. Báwo ni àpéjọ àgbègbè náà ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye òtítọ́?

2 Àpéjọ Náà Ń Jẹ́ Ká Túbọ̀ Lóye Òtítọ́: Láwọn àpéjọ wa, a máa ń gbádùn àwọn àsọyé, àwòkẹ́kọ̀ọ́, àṣefihàn àtàwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. (Jòh. 17:17) Ní báyìí, iṣẹ́ ti lọ gan-an lórí àpéjọ àgbègbè wa ti ọdún yìí. Ètò Jèhófà ti ń múra àpéjọ náà sílẹ̀ lọ́nà tó fi máa ṣèrànwọ́ fún gbogbo èèyàn jákèjádò ayé. (Mát. 24:45-47) Ǹjẹ́ ó ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o ti wà ní àpéjọ náà, kó o máa gbọ́, kó o sì máa rí àwọn ohun tá a fẹ́ gbé jáde nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà?

3. Tá a bá fẹ́ jàǹfààní àpéjọ náà, kí ló yẹ ká ṣe?

3 Tá a bá fẹ́ jàǹfààní àpéjọ náà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, àfi ká rí i pé a wà níbẹ̀ jálẹ̀ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ká sì fọkàn sí ohun tó ń lọ dáadáa. Bí o kò bá tíì gbàyè níbi iṣẹ́, á dára kó o sọ fún ọ̀gá rẹ pé o fẹ́ gbàyè. Nígbà àpéjọ náà, rí i dájú pé o sùn dáadáa ní alaalẹ́, kí oorun má bàa kùn ọ́ nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé táwọn bá ń wo ojú olùbánisọ̀rọ̀, táwọn sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí, ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn lè máa fọkàn bá ọ̀rọ̀ náà lọ. Má ṣe jẹ́ kí fóònù rẹ tàbí ohun èlò atanilólobó mìíràn dí ẹ lọ́wọ́, má sì ṣe jẹ́ kó dí àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ ní àpéjọ náà. Ṣọ́ra fún rírojọ́, fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, jíjẹun tàbí mímu ọtí nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́.

4. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní àpéjọ náà?

4 Ní àwọn ọdún Sábáàtì, nígbà tí àwọn ìdílé Ísírẹ́lì bá pé jọ láti tẹ́tí sí kíka Òfin nígbà Àjọyọ̀ Àtíbàbà, “àwọn ọmọ [wọn] kéékèèké” máa ń wà pẹ̀lú wọn “kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́.” (Diu. 31:12) Ẹ wo bó ṣe máa ń wúni lórí tó tá a bá rí i tí àwọn ìdílé jókòó pa pọ̀ láwọn àpéjọ àgbègbè wa, tí àwọn ọmọdé wà lójúfò tí wọ́n sì ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ tó ń lọ! Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ lo àwọn àkọsílẹ̀ yín láti jíròrò àwọn kókó pàtàkì tẹ́ ẹ gbádùn nínú ìpàdé ọjọ́ náà. Nítorí pé “ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí,” a rọ ẹ̀yin òbí pé kẹ́ ẹ bójú tó àwọn ọmọ yín kéékèèké dáadáa, títí kan àwọn tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún. Ẹ má ṣe ‘jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ fàlàlà,’ lásìkò ìsinmi ọ̀sán àti nígbà tẹ́ ẹ bá wà níbi tẹ́ ẹ dé sí.—Òwe 22:15; 29:15.

5. Báwo ni ìwà rere tá a bá hù níbi tá a dé sí ṣe lè mú kí àwọn èèyàn mọyì òtítọ́?

5 Ìwà Rere Wa Ń Mú Káwọn Èèyàn Mọyì Òtítọ́: Ìwà rere tá a bá hù níbi tá a ti lọ ṣe àpéjọ máa mú káwọn èèyàn túbọ̀ mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́. (Títù 2:10) Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì máa ń kíyè sí àwọn tó bá pa ìlànà òtẹ́ẹ̀lì wọn mọ́, tí wọ́n jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì ṣe sùúrù pẹ̀lú wọn. (Kól. 4:6) Nígbà tí àwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì ń ṣètò láti gba òtẹ́ẹ̀lì kan lọ́dún tó kọjá, ẹni tó ń bójú tó ọjà títà níbẹ̀ sọ pé: “Ó máa ń wù wá láti gba àwọn èèyàn yín sí  òtẹ́ẹ̀lì wa, torí pé èèyàn dáadáa ni wọ́n. Wọ́n níwà ọmọlúwàbí, wọ́n sì jẹ́ onínúure, wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ wa, wọn kì í sì í lo òtẹ́ẹ̀lì wa nílòkulò.”

6. Báwo la ṣe lè mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọyì òtítọ́ nípasẹ̀ ìmúra wa ní àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ?

6 Tá a bá de báàjì àpéjọ wa mọ́ àyà, kì í ṣe pé ó kàn máa jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa àpéjọ náà tàbí kó mú kí àwọn ará wa dá wa mọ̀ nìkan, àmọ́ ó tún máa jẹ́rìí fún àwọn tó ń rí wa. Àwọn tó ń gbé ní àwọn àdúgbò tá a ti máa ṣe àpéjọ wa máa kíyè sí pé àwọn tó de báàjì àpéjọ mọ́ àyà múra lọ́nà tó mọ́ tónítóní, tó yẹ ọmọlúwàbí, aṣọ wọn kò rí wúruwùru, wọn kò sì múra lọ́nà tó máa ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, bó ṣe wọ́pọ̀ nínú ayé. (1 Tím. 2:9, 10) Torí náà, ẹ jẹ́ ká kíyè sí ìwọṣọ àti ìmúra wa nígbà tá a bá wà láwọn ìlú tá a ti máa ṣe àpéjọ wa àti nígbà tá a bá dé sí òtẹ́ẹ̀lì. Kò ní bójú mu tá a bá wọ ṣòkòtò péńpé tàbí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ alápá péńpé tàbí ẹ̀wù tí kò lápá. Ibi yòówù ká lò fún àpéjọ náà, yálà a ṣe é nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ṣeé lò fún àpéjọ, ìmúra wa gbọ́dọ̀ bójú mu. Tó bá wù wá láti pààrọ̀ aṣọ lẹ́yìn tí àpéjọ bá parí tá a sì fẹ́ lọ sílé oúnjẹ, ẹ́ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé àpéjọ àgbègbè la wá ṣe níbẹ̀, torí náà a ò gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tí kò bójú mu.

7. Báwo la ṣe lè gbádùn ìṣọ̀kan tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará wa nígbà àpéjọ àgbègbè wa?

7 Nígbà àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe, wọ́n máa ń gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn olùjọsìn bíi tiwọn, àwọn tí wọ́n wá láti apá ibòmíì ní orílẹ̀-èdè wọn àti káàkiri àgbáyé, èyí sì máa ń mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan. (Ìṣe 2:1, 5) Láwọn àpéjọ àgbègbè wa, a máa ń gbádùn ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará wa. Ìfẹ́ tó wà láàárín wa nínú Párádísè tẹ̀mí tá a wà yìí máa ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu gan-an. (Sm. 133:1) Dípò ká kúrò nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà láti lọ jẹun ní ọ̀sán, á dáa ká gbé oúnjẹ ọ̀sán wa dání, ká lè wà ní àpéjọ náà láti ní ìfararora, ká sì jọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n jókòó sí tòsí wa.

8. Tó bá ṣeé ṣe fún wa, kí nìdí tó fi dáa pé ká yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ láwọn àpéjọ wa?

8 Ó sábà máa ń wú àwọn tó ń wò wá lórí bí wọ́n ṣe máa ń rí i pé a wà létòlétò nígbà àpéjọ àgbègbè wa, ní pàtàkì nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé ńṣe ni àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ yọ̀ǹda ara wọn. Ǹjẹ́ o lè ‘fi tinútinú yọ̀ǹda ara rẹ’ láti ṣiṣẹ́ ní àpéjọ àgbègbè? (Sm. 110:3) Àwọn ìdílé kan sábà máa ń yọ̀ǹda ara wọn lápapọ̀ kí wọ́n lè lo àǹfààní yẹn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ béèyàn ṣe lè ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì. Bó o bá jẹ́ ẹni tó ń tijú, yíyọ̀ǹda ara rẹ láwọn àpéjọ àgbègbè á jẹ́ kó o lè bá ọ̀pọ̀ àwọn tó wá sí àpéjọ náà sọ̀rọ̀. Arábìnrin kan sọ pé: “Yàtọ̀ sí àwọn mọ̀lẹ́bí mi àtàwọn ọ̀rẹ́ díẹ̀, mi ò mọ ọ̀pọ̀ èèyàn níbẹ̀. Àmọ́ nígbà tí mo yọ̀ǹda ara mi ní ẹ̀ka ìmọ́tótó, mo wá mọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó pọ̀. Mo gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an ni!” Tá a bá túbọ̀ ní àwọn ọ̀rẹ́ míì kún àwọn ọ̀rẹ́ tá a ní, nípa yíyọ̀ǹda ara wa ní àpéjọ àgbègbè, ìyẹn á jẹ́ kí ayọ̀ wa túbọ̀ pọ̀ sí i. (2 Kọ́r. 6:12, 13) Bí o kò bá tíì yọ̀ǹda ara rẹ rí, béèrè ohun tó o lè ṣe lọ́wọ́ àwọn alàgbà tí wàá fi lè tóótun láti yọ̀ǹda ara rẹ.

9. Báwo la ṣe máa pe àwọn èèyàn wá sí àpéjọ àgbègbè?

9 Pe Àwọn Èèyàn Láti Wá Gbọ́ Òtítọ́: Bá a ti ṣe ní àwọn ọdún tó kọjá, tó bá ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ká lọ sí àpéjọ àgbègbè wa, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni láti pe àwọn èèyàn sí àpéjọ náà. Á dáa kí àwọn ìjọ rí i pé àwọn pín ìwé ìkésíni yìí dé gbogbo ibi tí wọ́n bá lè pín in dé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. (Wo àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Báwo La Ṣe Máa Pín Ìwé Ìkésíni?”) Kẹ́ ẹ kó ìwé ìkésíni tó bá ṣẹ́ kù sọ́wọ́ yín wá sí àpéjọ. Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ bá wá sí àpéjọ náà á lè rí i lò nígbà tẹ́ ẹ bá ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà ní ìlú tẹ́ ẹ ti máa ṣe àpéjọ.

10. Sọ àwọn ìrírí tó fi hàn pé bí a ṣe ń pín ìwé ìkésíni lọ́dọọdún máa ń mú kí àwọn èèyàn wá sí àpéjọ wa?

10 Ǹjẹ́ àwọn tá a fún ní ìwé ìkésíni tiẹ̀ máa ń wá sí àpéjọ wa? Níbi àpéjọ wa kan, ọ̀kan lára àwọn tó ń bójú tó èrò mú tọkọtaya kan lọ síbi tí wọ́n máa jókòó sí. Wọ́n sọ fún arákùnrin náà pé ẹnì kan ló fún àwọn ní ìwé ìkésíni náà, àwọn sì “ronú pé ó máa dáa kí àwọn wá síbẹ̀.” Ìrìn àjò ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogún [320] kìlómítà ni wọ́n rìn kí wọ́n lè wá sí àpéjọ náà! Ìrírí míì ni ti arábìnrin wa kan tó fún ọkùnrin kan ní ìwé ìkésíni lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, ó wu ọkùnrin yìí gan-an láti mọ ohun tó fẹ́ wáyé níbi àpéjọ náà. Torí náà, arábìnrin yìí lo àǹfààní yẹn láti jíròrò ohun tó wà nínú ìwé ìkésíni náà pẹ̀lú rẹ̀. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà nígbà tí arábìnrin wa wà ní àpéjọ náà, ó rí ọkùnrin yẹn àti ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n mú ìwé tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde dání!

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa pésẹ̀ sí àwọn àpéjọ àgbègbè wa lọ́dọọdún?

11 Àwọn àjọyọ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe lọ́dọọdún jẹ́ ètò onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè “máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́.” (Jóṣ. 24:14) Bákan náà, pípésẹ̀ sí àwọn àpéjọ àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún máa ń jẹ́ ká lè máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́,” ó sì jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa. (3 Jòh. 3) Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún ìsapá gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ bí wọ́n ti ń múra láti wá sí àpéjọ àgbègbè yìí kí wọ́n sì jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́!

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 2]

Ìwà rere tá a bá hù níbi tá a ti lọ ṣe àpéjọ máa mú káwọn èèyàn túbọ̀ mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Tó bá ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ká lọ sí àpéjọ àgbègbè wa, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni láti pe àwọn èèyàn sí àpéjọ náà

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 2-4]

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2012

◼ Àkókò Ìpàdé: Aago mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú [9:20] ni ìpàdé máa bẹ̀rẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà tí wọ́n bá ti ṣèfilọ̀ ohùn orin tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ àpéjọ, ó yẹ kí olúkúlùkù wa lọ jókòó ká lè bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ náà máa parí ní aago márùn-ún ku ìṣẹ́jú márùn-ún [4:55] ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday àti ọjọ́ Sátidé, ó sì máa parí ní aago mẹ́rin ku ogún ìṣẹ́jú [3:40] ní ọ̀sán Sunday.

◼ Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Ní gbogbo ibi tí àpéjọ ti máa wáyé, àwọn olùtọ́jú èrò máa darí yín síbi tẹ́ ẹ máa gbé ọkọ̀ sí. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 13:4, 5.

◼ Àwọn Tó O Lè Gbàyè Sílẹ̀ Fún: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ kan náà tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbénú ilé kan náà àtàwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan lo lè gbàyè sílẹ̀ fún.—1 Kọ́r. 13:5.

◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tẹ́ ẹ fi máa kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti lọ wá oúnjẹ rà lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó máa ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

◼ Ọrẹ: A lè fi hàn pé a mọyì ètò tá a ṣe láti mú kí àpéjọ yìí wáyé bá a bá fínnú fíndọ̀ fi owó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Kí ẹni tó bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn ní àpéjọ àgbègbè fi hàn pé “Watch Tower” ni òun fẹ́ kí wọ́n sanwó náà fún. Kí ẹni náà kọ Watch àti Tower lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o.

◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá wáyé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún olùtọ́jú èrò tó bá wà nítòsí, ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti gbé aláìlera náà lọ sí Ẹ̀ka Ìtọ́jú Pàjáwìrì, káwọn òṣìṣẹ́ àpéjọ wa tí wọ́n ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó, kí wọ́n sì lè ṣèrànwọ́ tó bá yẹ.

◼ Lílo Oògùn: Tó o bá ní oògùn tí ò ń lò, jọ̀wọ́ mú èyí tó máa tó ẹ lò dání wá sí àpéjọ, torí pé a lè máà ní irú oògùn bẹ́ẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Kí àwọn tó bá ń lo abẹ́rẹ́ fún ìtọ̀ ṣúgà rí i dájú pé àwọn tọ́jú abẹ́rẹ́ náà dáadáa, kí wọ́n má ṣe jù ú sínú àwọn ike ìkólẹ̀sí tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ilé gbígbé.

◼ Bàtà: Kó o má bàa fara pa, ó máa dáa kó o wọ bàtà tí kò fi bẹ́ẹ̀ ga, tó máa jẹ́ kó o lè rìn dáadáa.

◼ Lọ́fíńdà: A máa fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò tí a bá ṣọ́ra fún lílo àwọn lọ́fíńdà olóòórùn líle, kí a má bàa ṣàkóbá fún àwọn tó níṣòro èémí.—1 Kọ́r. 10:24.

◼ Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò (S-43): Bẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan nígbà àpéjọ àgbègbè tí ẹni náà sì fìfẹ́ hàn, ẹ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù padà-lọ-ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43). Kí àwọn akéde mú fọ́ọ̀mù yìí kan tàbí méjì dání wá sí àpéjọ. Ẹ lè mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ bá ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sí fún wọn ní Ilé Ìgbàwé tàbí kẹ́ ẹ fún akọ̀wé ìjọ yín ní gbàrà tẹ́ ẹ bá pa dà délé.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù May 2011, ojú ìwé 3.

◼ Àwọn Búkà Oúnjẹ Àtàwọn Tó Ń Tajà Níwájú Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ẹ jẹ́ kí ìwà rere wa bọlá fún orúkọ Jèhófà. Kò bọ́gbọ́n mu láti lọ ra oúnjẹ ní búkà tàbí lọ́wọ́ àwọn tó ń kiri ọjà nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.

◼ Ilé Gbígbé: Ibi yòówù ká dé sí, yálà ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí òtẹ́ẹ̀lì, ó máa dáa ká fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé àtàwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì. (Gál. 5:22, 23) Wọ́n ń bójú tó ọ̀pọ̀ èèyàn. Nítorí náà, wọ́n máa mọyì rẹ̀ tá a bá lo inú rere àti sùúrù, tá a sì fòye bá wọn lò. A lè fi hàn pé a gba tiwọn rò láwọn ọ̀nà tó tẹ̀ lé e yìí:

(1) Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe gbà ju iye yàrá tẹ́ ẹ nílò lọ, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí iye èèyàn tó máa wà pẹ̀lú yín nínú yàrá pọ̀ ju iye èèyàn tí wọ́n gbà láyè lọ.

(2) Má ṣe wọ́gi lé ètò tó o ṣe láti dé sí òtẹ́ẹ̀lì, àyàfi tí ọ̀ràn pàjáwìrì bá wáyé, kó o sì sọ fún àwọn tó ń bójú tó òtẹ́ẹ̀lì náà, ní gbàrà tí ọ̀ràn náà bá wáyé.—Mát. 5:37.

(3) Ibi tí wọ́n bá sọ pé kó o ti dáná nìkan ni kó o ti máa dáná. Má ṣe dáná nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́, torí ìyẹn kò ní fi hàn pé o mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí.—Lúùkù 10:38-42.

(4) Kí àwọn òbí bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa nígbà tí wọ́n bá wà ní òtẹ́ẹ̀lì tàbí ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ibòmíì.

(5) Má ṣe dé sínú ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kò bá sọ pé kó o dé síbẹ̀. Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, kó o dé sí kìkì ibi tí wọ́n bá ní kó o dé sí. Kí àwọn arákùnrin má ṣe wà nínú yàrá tó wà fún àwọn arábìnrin títí di alẹ́, wọn kò sì gbọ́dọ̀ sùn síbẹ̀. Àwọn arábìnrin pẹ̀lú kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

(6) Bí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú nípa ibi tí wọ́n fi ọ́ sí, rí i dájú pé o tètè fi tó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé létí kó o tó kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

◼ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Kí ẹni tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọ àgbègbè. Àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] pẹ̀lú lè yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n lè ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí tàbí alágbàtọ́ wọn tàbí àgbàlagbà míì tá a bá fà wọ́n lé lọ́wọ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Báwo La Ṣe Máa Pín Ìwé Ìkésíni?

Ká bàa lè pín ìwé ìkésíni yìí dé ibi gbogbo ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ó lè gba pé ká sọ ọ̀rọ̀ wa ní ṣókí. Lẹ́yìn tá a bá ti kí onílé, a lè sọ pé: “Ibi gbogbo kárí ayé la ti ń fi ìwé yìí pe àwọn èèyàn. Tiyín rèé. Ẹ máa rí àlàyé púpọ̀ sí i nínú ìwé yìí.” Fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀. Tẹ́ ẹ bá ń pín ìwé ìkésíni náà láwọn òpin ọ̀sẹ̀, kẹ́ ẹ tún fi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn, tẹ́ ẹ bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́