Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 13
Orin 63 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 25 ìpínrọ̀ 1 sí 7 àti àwọn àpótí tó wà lójú ìwé 199 àti 200 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 28-31 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 28:17-26 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tí Kì Í Ṣe Òótọ́ Àtohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Jésù Kristi (5 min.)
No. 3: Àwọn Ohun Tá A Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀ Ká Tó Lè Máa Kópa Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?—td 37B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Múra Ọkàn Onílé Sílẹ̀ De Ìgbà Tí Wàá Pa Dà Lọ. Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí: (1) Nígbà tá a bá kọ́kọ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, kí nìdí tó fi dáa pé ká múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ de ìgbà tá a máa pa dà lọ bẹ̀ ẹ́ wò, báwo la sì ṣe lè múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀? (2) Báwo la ṣe lè yan ìbéèrè tí onílé máa nífẹ̀ẹ́ sí, tá a máa dáhùn nígbà tá a bá pa dà lọ bẹ̀ ẹ́ wò? (3) Kí nìdí tó fi dáa pé ká jọ fohùn ṣọ̀kan lórí àkókò tá a máa pa dà lọ, tó bá sì ṣeé ṣe ká tún gba nọ́ńbà fóònù onílé tàbí àdírẹ́sì tó fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? (4) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbìyànjú láti tètè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ onílé bóyá lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tá a bá a sọ̀rọ̀? (5) Kí làwọn ìsọfúnni tá a lè kọ sílẹ̀ nípa onílé lẹ́yìn tá a kọ́kọ́ wàásù fún un?
20 min: “Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Jíròrò “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2012.” Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 9, ké sí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn pé kó ṣàlàyé ètò tí ìjọ ṣe láti pín ìwé ìkésíni sí àpéjọ àgbègbè.
Orin 119 àti Àdúrà