ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/13 ojú ìwé 3-5
  • Fi Ìwà Rẹ Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ìwà Rẹ Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • A Máa Gbádùn Ìtura Nípa Tẹ̀mí fún Ọjọ́ Mẹ́ta
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 8/13 ojú ìwé 3-5

Fi Ìwà Rẹ Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga

1. Kí ló máa ń jẹ́ káwọn èèyàn tètè kíyè sí wa tá a bá lọ sí àwọn àpéjọ àgbègbè wa?

1 Tá a bá ń lọ sáwọn àpéjọ àgbègbè wa, àwọn èèyàn máa ń tètè kíyè sí wa. Àwọn oníròyìn máa ń gbé ìròyìn jáde nípa wa ní ọ̀pọ̀ ìlú tá a ti máa ń ṣe àpéjọ. Àwọn èèyàn máa ń rí wa láwọn ibi tá a bá dé sí àtàwọn ilé oúnjẹ tó bá wà ní àgbègbè náà. Àwọn tó sì ń gbé nítòsí ibẹ̀ máa ń kíyè sí ọ̀pọ̀ èèyàn tó fi báàjì àpéjọ àgbègbè náà sáyà. Ẹ jẹ́ ká ran ara wa létí àwọn nǹkan kan tó máa jẹ́ ká lè fi ìwà wa gbé orúkọ Ọlọ́run ga nígbà tá a bá wà ní ìlú tá a ti fẹ́ ṣe àpéjọ àgbègbè.—1 Pét. 2:12.

2. Báwo la ṣe lè fi ìmúra tó bójú mu gbé orúkọ Ọlọ́run ga ní ìlú tá a ti fẹ́ ṣe àpéjọ àgbègbè?

2 Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu: Bí ìmúra wa ṣe máa ń bójú mu tá a bá lọ fún àpéjọ wa máa ń wú àwọn èèyàn lórí gan-an. Àmọ́ ìmúra wa láwọn ìgbà míì tún lè ní ipa réré lórí irú ojú tí wọ́n á fi wò wá, irú bí ìgbà tá a bá dé síbi tá a fẹ́ sùn sí, tá a bá lọ sílé oúnjẹ, tá a bá lọ ra nǹkan àti láwọn ìgbà míì. Òótọ́ ni pé láwọn ibi tá a mẹ́nu bà yìí, a lè wọ aṣọ tó yàtọ̀ sí èyí tá a wọ̀ lọ sí àpéjọ, síbẹ̀ ó yẹ kí ìmúra wa bójú mu, kó buyì kúnni, kó sì jẹ́ ti ọmọlúwàbí. Ó yẹ ká jẹ́ kí àwọn tó ń kíyè sí wa rí ìyàtọ̀ láàárín wa àtàwọn aláìgbàgbọ́. (Róòmù 12:2) Ó tún yẹ ká fi báàjì àpéjọ sáyà láwọn ibi tá a mẹ́nu bà yìí, ká lè fi jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa àpéjọ náà, ká lè fi wàásù, káwọn ará tá a jọ wá sí àpéjọ náà sì lè fi dá wa mọ̀.

3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní sùúrù àti ìwà ọmọlúwàbí?

3 Jẹ́ Onísùúrù àti Ọmọlúwàbí: Nínú ayé táwọn èèyàn ò ti moore, tí wọn ò sì mọ̀ ju tara wọn lọ yìí, ìwà ọmọlúwàbí àti sùúrù tá a bá ní máa ń jẹ́ kára tu àwọn èèyàn gan-an, irú bí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì àti ilé oúnjẹ. (2 Tím. 3:1-5) Tá a bá fẹ́ gba àyè ìjókòó tàbí tá a fẹ́ gba ìtẹ̀jáde tuntun, ẹ má ṣe jẹ́ ká ro ti ara wa nìkan, àmọ́ ká máa ro ti àwọn ẹlòmíì. (1 Kọ́r. 10:23, 24) Nígbà tí olùfìfẹ́hàn kan wá sí àpéjọ àgbègbè wa fúngbà àkọ́kọ́, ó sọ pé, “Mi ò rántí ìkankan nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn wú mi lórí gan-an ni.”

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká yọ̀ǹda ara wa ní àpéjọ náà, tó bá ṣeé ṣe?

4 Yọ̀ǹda Ara Rẹ Tọkàntọkàn: Àwa Kristẹni tòótọ́ máa ń yọ̀ǹda ara wa tọkàntọkàn. (Sm. 110:3) Ṣé ìwọ náà á yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣiṣẹ́ ní àpéjọ àgbègbè? Ní ìlú ibì kan tá a ti ṣe àpéjọ àgbègbè, nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló yọ̀ǹda ara wọn láti wá tún ibi tá a fẹ́ lò ṣe ṣáájú àpéjọ náà. Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ sọ pé: “A ò tíì rí irú eléyìí rí níbí yìí o! Ẹ wo bí àwọn èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣe iṣẹ́ ti pọ̀ tó!” À ń fojú sọ́nà fún àpéjọ àgbègbè ọdún 2013, ká lè fetí sílẹ̀ ká sì kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ká sì tún gbé orúkọ rẹ̀ ga.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2013

◼ Àkókò Ìpàdé: Aago mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú [9:20] ni ohùn orin máa bẹ̀rẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Tí ohùn orin bá ti bẹ̀rẹ̀, ó yẹ kí olúkúlùkù wa lọ jókòó ká lè bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ náà máa parí ní aago márùn-ún ku ìṣẹ́jú mẹ́wàá [4:50] ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday àti Sátidé, ó sì máa parí ní aago mẹ́rin ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [3:35] ní ọ̀sán Sunday.

◼ Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Ní gbogbo ibi tí àpéjọ ti máa wáyé, àyè ìgbọ́kọ̀sí máa wà lọ́fẹ̀ẹ́. Àwọn olùtọ́jú èrò máa darí yín síbẹ̀ bẹ́ ẹ bá ṣe ń dé. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 13:4, 5.

◼ Àwọn Tó O Lè Gbàyè Sílẹ̀ Fún: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ kan náà tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbénú ilé kan náà àtàwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan lo lè gbàyè sílẹ̀ fún.—1 Kọ́r. 13:5.

◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tẹ́ ẹ fi máa kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti lọ ra oúnjẹ lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

◼ Ọrẹ: A lè fi hàn pé a mọyì ètò tá a ṣe láti mú kí àpéjọ yìí wáyé bá a bá fínnú fíndọ̀ fi owó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Kí ẹni tó bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn kọ ọ́ síbẹ̀ pé “Watch Tower” ni kí wọ́n sanwó náà fún. Kí ẹni náà kọ Watch àti Tower lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o. Ẹ tún lè lo káàdì owó, ìyẹn debit card tàbí credit card láti fi ọrẹ ránṣẹ́.

◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá wáyé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún olùtọ́jú èrò tó bá wà nítòsí, ó máa fi ọ̀ràn náà tó Ẹ̀ka Ìtọ́jú Pàjáwìrì létí lẹ́sèkẹsẹ̀, káwọn òṣìṣẹ́ àpéjọ wa tí wọ́n ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó, kí wọ́n sì lè ṣèrànwọ́.

◼ Lílo Oògùn: Tó o bá ní oògùn tí ò ń lò, jọ̀wọ́ mú èyí tó máa tó ẹ lò dání wá sí àpéjọ, torí pé a lè máà ní irú oògùn bẹ́ẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Kí àwọn tó bá ń lo abẹ́rẹ́ fún ìtọ̀ ṣúgà rí i dájú pé àwọn tọ́jú abẹ́rẹ́ náà dáadáa, kí wọ́n má ṣe jù ú sínú àwọn ike ìkólẹ̀sí tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti ti ibi tí wọ́n bá dé sí.

◼ Bàtà: Lọ́dọọdún àwọn èèyàn sábà máa ń fara pa nítorí irú bàtà tí wọ́n ń wọ̀, pàápàá àwọn tó bá wọ bàtà gogoro. Torí náà, ó máa dáa kó o wọ bàtà tí kò ga, tó bójú mu tó máa jẹ́ kó o lè rìn láì fara pa.

◼ Àga Ọmọdé Tó Ní Táyà Lẹ́sẹ̀ àti Àga Ìnàyìn: Ẹ má ṣe gbé àga ọmọdé tó ní táyà lẹ́sẹ̀ àti àga ìnàyìn wá sí àpéjọ àgbègbè. Àmọ́ ẹ lè gbé ìjókòó ọmọdé tó ṣeé dè sórí àga ní ẹ̀gbẹ́ òbí ọmọ náà wá.

◼ Lọ́fíńdà: A máa fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò tí a bá ṣọ́ra fún lílo àwọn lọ́fíńdà tó ní òórùn líle, kí a má bàa ṣàkóbá fún àwọn tó níṣòro èémí.—1 Kọ́r. 10:24.

◼ Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò (S-43): Bẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan nígbà àpéjọ àgbègbè, tí ẹni náà sì fìfẹ́ hàn, ẹ kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù padà-lọ-ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43). Ẹ lè mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sí fún wọn ní Ilé Ìgbàwé tàbí kẹ́ ẹ fún akọ̀wé ìjọ yín ní gbàrà tẹ́ ẹ bá pa dà délé.

◼ Búkà Oúnjẹ Àtàwọn Tó Ń Tajà Níwájú Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ẹ jẹ́ ká fi ìwà rere bọlá fún orúkọ Jèhófà tá a bá wà nílé oúnjẹ. Ká múra lọ́nà tó yẹ Kristẹni. Kò bọ́gbọ́n mu láti lọ ra ọjà nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.

◼ Ilé Gbígbé:

(1) Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe gbà ju iye yàrá tẹ́ ẹ nílò lọ, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí iye èèyàn tó máa wà pẹ̀lú yín nínú yàrá pọ̀ ju iye tí wọ́n gbà láyè lọ.

(1) Má ṣe wọ́gi lé ètò tó o ṣe láti dé sí òtẹ́ẹ̀lì, àyàfi tí ọ̀ràn pàjáwìrì bá wáyé, kó o sì sọ fún àwọn tó ń bójú tó òtẹ́ẹ̀lì náà lésẹ̀kẹsẹ̀, kí àwọn ẹlòmíì lè gba yàra náà. (Mát. 5:37) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n dá owó rẹ pa dà fún ẹ tó o bá tètè sọ fún wọn kó tó ku ọjọ́ méjì ṣáájú ìgbà tó yẹ kó o dé síbẹ̀.

(2) Tó o bá gba ohun èlò tí wọ́n fi ń kó ẹrù, rí i pé o lò ó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kó o sì tètè dá a pa dà káwọn ẹlòmíì lè rí i lò.

(2) O lè fún àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì tó bá ẹ gbé ẹrù lówó, o sì lè fi owó tàbí ẹ̀bùn sílẹ̀ fún ẹni tó ń bá ẹ tún yàrá ṣe ní òtẹ́ẹ̀lì tó o bá dé sí.

(3) Ibi tí wọ́n bá sọ pé kó o ti dáná nìkan ni kó o ti máa dáná. Má ṣe dáná nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́, torí ìyẹn kò ní fi hàn pé o mọyì nǹkan tẹ̀mí.

(4) Láwọn òtẹ́ẹ̀lì kan, wọ́n máa ń fi ìpápánu, kọfí, ọtí ẹlẹ́rìndòdò àtàwọn nǹkan míì sínú yàrá tẹ́ ẹ máa dé sí, jọ̀wọ́ má ṣe mú ju iye tó yẹ lọ.

(5) Rí i pé o fi èsò tẹ̀mí ṣèwà hù ní gbogbo ìgbà tó o bá ń bá àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé sọ̀rọ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ yìí ń bójú tó èrò tó pọ̀. Wọ́n máa mọyì sùúrù, inú rere àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò tá a bá fi hàn sí wọn.

(6) Kí àwọn òbí bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa ní òtẹ́ẹ̀lì, níbi odò ìlúwẹ̀ẹ́, láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wà, ní ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ibòmíì.

(7) Má ṣe dé sínú ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kò bá sọ pé kó o dé síbẹ̀. Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, kó o dé sí kìkì ibi tí wọ́n bá ní kó o dé sí. Kí àwọn arákùnrin má ṣe di alẹ́ sínú yàrá tó wà fún àwọn arábìnrin, wọn kò sì gbọ́dọ̀ sùn síbẹ̀. Àwọn arábìnrin pẹ̀lú kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yàrá tó wà fún àwọn arákùnrin.

(8) Bí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú nípa ibi tí wọ́n fi ọ́ sí, rí i dájú pé o fi tó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé létí kó o tó kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

◼ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Kí ẹni tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọ àgbègbè. Àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] pẹ̀lú lè yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n lè ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí tàbí alágbàtọ́ wọn tàbí àgbàlagbà míì tá a bá fà wọ́n lé lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́