A Máa Gbádùn Ìtura Nípa Tẹ̀mí fún Ọjọ́ Mẹ́ta
1. Kí la lè máa retí láti gbádùn ní àpéjọ àgbègbè wa ti ọdún yìí?
1 Ní ilẹ̀ tó gbẹ́ táútáú nípa tẹ̀mí, ìyẹn ayé Sátánì yìí, Jèhófà ń bá a lọ láti máa pèsè ìtura fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Aísá. 58:11) Àpéjọ àgbègbè tá à ń ṣe lọ́dọọdún jẹ́ ọ̀kan lára ìpèsè tí Jèhófà ń lò láti fún wa lókun. Bí àpéjọ àgbègbè ti ọdún yìí ṣe ń sún mọ́lé, báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ láti gba ìtura nípa tẹ̀mí ká sì tu àwọn ẹlòmíì náà lára?—Òwe 21:5.
2. Àwọn nǹkan wo la ní láti múra sílẹ̀ fún?
2 Bí o kò bá tíì ṣètò àwọn nǹkan rẹ àti iṣẹ́ rẹ, àkókò nìyí fún ẹ láti ṣètò wọn kó o lè wà ní àpéjọ àgbègbè náà lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ǹjẹ́ o ti mọ́ iye àkókò tó o máa lò kó o tó dé Gbọ̀ngàn Àpéjọ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kàn, kó o lè máa tètè dé kó o sì lè wá ibi tó o máa jókòó sí kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀? Ó dájú pé o kò ní fẹ́ pàdánù èyíkéyìí lára oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ti pèsè sílẹ̀ fún wa láti fún wa lókun! (Aísá. 65:13, 14) Ǹjẹ́ o ti ṣètò ibi tó o máa dé sí àti ọkọ̀ tó o máa wọ̀?
3. Àwọn àbá wo ló máa ran àwa àti ìdílé wa lọ́wọ́ ká lè jàǹfààní tó kún rẹ́rẹ́ látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà?
3 Kí ló máa jẹ́ kó o lè pọkàn pọ̀ nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́? Tó bá ṣeé ṣe, máa sun dáadáa ní gbogbo òru ọjọ́ àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Máa wo olùbánisọ̀rọ̀. Máa ṣí Bíbélì rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti pe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí. Ó máa dáa kí àwọn òbí àtàwọn ọmọ jókòó pọ̀, kí wọ́n lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀. (Òwe 29:15) Ẹ sì tún lè jíròrò àwọn kókó pàtàkì inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní ìrọ̀lẹ́. Kí àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ lè máa gbádùn ìtura tẹ̀mí yìí lọ lẹ́yìn àpéjọ náà, ẹ lè ya àkókò kan sọ́tọ̀ nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín láti jíròrò àwọn kókó pàtàkì tí ìdílé yín lè ṣiṣẹ́ lé lórí.
4. Báwo la ṣe lè ran àwọn tó wà nínú ìjọ wa lọ́wọ́ láti rí ìtura nípa tẹ̀mí gbà?
4 Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́ Láti Rí Ìtura: A fẹ́ kí àwọn ẹlòmíì náà rí ìtura nípa tẹ̀mí. Ǹjẹ́ àwọn akéde tó ti dàgbà tàbí àwọn míì tó nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ sí àpéjọ náà wà nínú ìjọ yín? Ǹjẹ́ o lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? (1 Jòh. 3:17, 18) Àwọn alàgbà, ní pàtàkì jù lọ àwọn alábòójútó àwùjọ, gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn akéde rí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò gbà.
5. Ètò wo la ti ṣe fún pínpín ìwé ìkésíni sí àpéjọ náà? (Tún wo àpótí tó wà lókè.)
5 Bá a ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, tó bá ti ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ká lọ sí àpéjọ àgbègbè tí wọ́n yan ìjọ wa sí, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni tá a máa fi pe àwọn èèyàn sí àpéjọ náà. Gbogbo ìjọ gbọ́dọ̀ fi ṣe àfojúsùn wọn láti pín gbogbo ìwé ìkésíni tá a fi ránṣẹ́ sí wọn, kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Kẹ́ ẹ kó ìwé ìkésíni tó bá ṣẹ́ kù sí ìdílé yín lọ́wọ́ wá sí ibi tẹ́ ẹ ti máa ṣe àpéjọ, kẹ́ ẹ lè lò ó nígbà tẹ́ ẹ bá ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. A máa fún yín ní ìtọ́ni síwájú sí i nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday. Kẹ́ ẹ kó ìwé ìkésíni tí ẹ ò ní lọ́kàn láti lò ní àpéjọ náà fún ọ̀kan lára àwọn alábòójútó èrò ní gbàrà tẹ́ ẹ bá ti dé Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Ẹ jọ̀wọ́, kẹ́ ẹ ṣẹ́ ọ̀kan kù sọ́wọ́ torí pé a máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àsọyé tó gbẹ̀yìn lọ́jọ́ Sunday.
6. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà hùwà tó bójú mu ní àpéjọ náà?
6 Ìwà Tó Bójú Mu Ń Tuni Lára: Ní àkókò yìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn,” tí wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ẹlòmíì, ó máa ń tuni lára gan-an láti wà láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ń sapá láti máa hùwà tó bójú mu! (2 Tím. 3:2) Ìwà tó bójú mu ló jẹ́ tá a bá rọra wọ inú Gbọ̀ngàn àpéjọ wọ́ọ́rọ́wọ́ tá a sì tún jáde wọ́ọ́rọ́wọ́ lọ́nà tó wà létòlétò; tó sì tún jẹ́ pé kìkì àwọn tá a jọ ń gbé nínú ilé kan náà tàbí tá a jọ wọ ọkọ̀ kan náà àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan la gba àyè sílẹ̀ fún. Ó tún yẹ ká lọ jókòó nígbà tí alága bá sọ pé ká lọ jókòó sí àyè wa, ká lè gbọ́ ohùn orin tó máa bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Ìwà tó bójú mu ló tún jẹ́ láti yí fóònù wa tàbí ẹ̀rọ atanilólobó lọ sílẹ̀, kó máa bàa pín ọkàn àwọn ẹlòmíì níyà nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. A tún ń hu ìwà tó bójú mu tí a kì í bá sọ̀rọ̀, fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, jẹun tàbí ká máa rìn kiri láìnídìí nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.
7. Báwo la ṣe lè rí ìtura gbà ká sì mú kí ara tu àwọn ẹlòmíì bá a ṣe ń ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa?
7 Ìbákẹ́gbẹ́ Tó Ń Tuni Lára: Àpéjọ àgbègbè máa ń fún wa ní àǹfààní tó pọ̀ sí i láti gbádùn ìṣọ̀kan Kristẹni pẹ̀lú àwọn ará wa. (Sm. 133:1-3) O ò ṣe lo ìdánúṣe láti “gbòòrò síwájú,” kó o mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wá láti àwọn ìjọ míì? (2 Kọ́r. 6:13) O lè fi ṣe àfojúsùn rẹ láti mọ ẹnì kan tàbí ìdílé kan lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọ náà. Àkókò ìsinmi ọ̀sán máa fún ẹ láǹfààní láti ṣe èyí. Torí náà, ńṣe ni kó o gbé oúnjẹ tìrẹ wá, kó o jẹun, kó o sì ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ dípò tí wàá fi jáde lọ ra oúnjẹ tàbí kó o lọ jẹun ní búkà tó wà nítòsí. Èyí lè jẹ́ kó o rí àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tó sì máa wà pẹ́ títí.
8. Kí nìdí tó fi yẹ ká yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ ní àpéjọ náà, báwo la sì ṣe lè ṣe é?
8 Ó máa ń tuni lára gan-an láti ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mímọ́! Ǹjẹ́ o lè yọ̀ǹda ara rẹ láti ran ẹ̀ka tó ń bójú tó iṣẹ́ kan lọ́wọ́ tàbí kó o ran ìjọ rẹ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìmọ́tótó tí wọ́n bá yàn fún yín? (Sm. 110:3) Tí o kò bá tíì ní iṣẹ́ kankan tó máa bójú tó, jọ̀wọ́ lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni, kí wọ́n lè fún ẹ ní iṣẹ́ tí wàá bá wọn ṣe ní àpéjọ náà. Tí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn bá pọ̀, ó máa jẹ́ kí iṣẹ́ náà gbádùn mọ́ni kó sì rọrùn.
9. Kí nìdí tó fi yẹ ká fún ìwà wa àti ìrísí wa ní àfiyèsí pàtàkì nígbà àpéjọ náà?
9 Ìwà Wa Ń Tu Àwọn Tó Ń Wò Wá Lára: Aṣojú la jẹ́ ní ibi àpéjọ àgbègbè náà fún ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, kì í ṣe nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́ nìkan. Àwọn tó ń wò wá nígbà tá a wà ní ìlú tá a ti lọ ṣe àpéjọ gbọ́dọ̀ rí ìyàtọ̀ tó ń tuni lára láàárín àwa àti àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. (1 Pét. 2:12) Ìmúra wa àti ìrísí wa nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ní ibi tá a dé sí àti ní ilé oúnjẹ gbọ́dọ̀ fi ìyìn fún Jèhófà. (1 Tím. 2:9, 10) Tá a ba wọ báàjì àyà wa, àwọn tó ń wò wá yóò dá wa mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Èyí sì lè fún wa láǹfààní láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àpéjọ náà, ká sì tún wàásù fún wọn síwájú sí i.
10. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì àti nílé oúnjẹ ní èrò tó dáa nípa àpéjọ wa?
10 Báwo la ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì àti nílé oúnjẹ? A kò gbọ́dọ̀ fẹnu gba yara tó pọ̀ ju ohun tá a nílò sílẹ̀, torí èyí kò ní jẹ́ kí àwọn míì tó wá sí àpéjọ náà rí ibi tí wọ́n máa dé sí, ó sì máa jẹ́ kí àwọn tó ni òtẹ́ẹ̀lì náà pàdánù owó tó yẹ kó wọlé fún wọn. Bí èrò bá ń lọ̀ tó ń bọ̀ ní òtẹ́ẹ̀lì náà nígbà tá a débẹ̀ àti nígbà tá a fẹ́ jáde, a gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù ká sì hùwà pẹ̀lẹ́. (Kól. 4:6) Ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó gbé oúnjẹ fún wa ní ilé oúnjẹ tàbí òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì tó bá wa gbé ẹrù wa, tó tún yàrá wa ṣe tàbí tó ṣe nǹkan míì fún wa.
11. Ìrírí wo ló jẹ́ ká mọ bí híhu ìwà rere Kristẹni ṣe wàásù fún àwọn èèyàn?
11 Ipa wo ni ìwà rere wa ní àpéjọ àgbègbè máa ń ní lórí àwọn ẹlòmíì? Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn kan sọ ohun tí alábòójútó gbọ̀ngàn kan tá a ti ṣe àpéjọ sọ, ó ní: “Àwọn èèyàn náà máa ń bọ̀wọ̀ fúnni. Inú wa máa ń dùn láti gbà wọ́n lọ́dọọdún.” Lọ́dún tó kọjá, ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ pọ́ọ̀sì rẹ̀ nù ní òtẹ́ẹ̀lì kan tí àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè dé sí. Nígbà tí wọ́n dá pọ́ọ̀sì náà pa dà sọ́dọ̀ máníjà òtẹ́ẹ̀lì náà, tí kò sì sí ohun tó sọnù nínú rẹ̀, máníjà náà sọ fún ẹni tó ni pọ́ọ̀sì náà pé: “Ohun tó jẹ́ kó o rí pọ́ọ̀sì yìí ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe àpéjọ wọn ládùúgbò yìí, àwọn ni wọ́n sì pọ̀ jù ní òtẹ́ẹ̀lì yìí. Ká ní kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni, o ò bá máà rí pọ́ọ̀sì yìí mọ́.”
12. Bí ọjọ́ àpéjọ àgbègbè wa ṣe ń sún mọ́lé, kí ló yẹ kó jẹ́ àfojúsùn wa, kí sì nìdí?
12 Àpéjọ àgbègbè wa tọdún yìí ń yára sún mọ́lé gan-an. A ti lo ọ̀pọ̀ àkókò, a sì ti sapá gan-an láti múra ìpàdé yìí sílẹ̀, kí ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ náà sì tuni lára. Torí náà, fi ṣe àfojúsùn rẹ láti wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, kó o sì múra sílẹ̀ fún ohun tí Jèhófà àti ètò rẹ̀ ti pèsè sílẹ̀ fún ẹ. Pinnu láti mú kí ara tu àwọn míì nípa híhùwà tó bójú mu, bó o ṣe ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú wọn tayọ̀tayọ̀ àti nípasẹ̀ ìwà rere rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ àti àwọn míì á lè ní irú ìmọ̀lára tí ọ̀kan lára àwọn tó lọ sí àpéjọ àgbègbè kan lọ́dún tó kọjá ní, ó sọ pé: “Mi ò rántí ìgbà tí mo ní irú ìrírí tó tẹ́ni lọ́rùn bẹ́ẹ̀ gbẹ̀yìn!”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 1]
Bá a ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, tó bá ti ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ká lọ sí àpéjọ àgbègbè tí wọ́n yan ìjọ wa sí, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni tá a máa fi pe àwọn èèyàn sí àpéjọ náà
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Ìmúra wa àti ìrísí wa nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ní ibi tá a dé sí àti ní ilé oúnjẹ gbọ́dọ̀ fi ìyìn fún Jèhófà
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Pinnu láti mú kí ara tu àwọn míì nípa híhùwà tó bójú mu, bó o ṣe ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú wọn tayọ̀tayọ̀ àti nípasẹ̀ ìwà rere rẹ
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 2-4]
Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2011
◼ Àkókò Ìpàdé: Aago mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú [9:20] ni ìpàdé máa bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà tí wọ́n bá ti ṣèfilọ̀ ohùn orin tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ àpéjọ, ó yẹ kí olúkúlùkù wa lọ jókòó ká lè bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ náà máa parí ní aago márùn-ún ku ìṣẹ́jú márùn-ún [4:55] ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday àti ọjọ́ Sátidé, ó sì máa parí ní aago mẹ́rin ku ogún ìṣẹ́jú [3:40] ní ọ̀sán Sunday.
◼ Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Ní gbogbo ibi tí àpéjọ ti máa wáyé, àwọn olùtọ́jú èrò máa darí wa síbi tá a máa gbé ọkọ̀ wa sí. Torí náà, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 14:40.
◼ Àwọn Tó O Lè Gbàyè Sílẹ̀ Fún: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ kan náà, tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbé nínú ilé kan náà àtàwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan lo lè gbàyè sílẹ̀ fún.—1 Kọ́r. 13:5.
◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Ẹ jọ̀wọ́ ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tẹ́ ẹ fi máa kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti lọ wá oúnjẹ rà lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó máa ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. A kò sì gba ọtí líle láyè.
◼ Ọrẹ: A lè fi hàn pé a mọrírì ètò tá a ṣe láti mú kí àpéjọ yìí wáyé bá a bá fínnú fíndọ̀ fowó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Kí ẹni tó bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn ní àpéjọ àgbègbè fi hàn pé “Watch Tower” ni òun fẹ́ kí wọ́n sanwó náà fún. Kẹ́ni náà kọ Watch àti Tower lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o.
◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ fún olùtọ́jú èrò tó bá wà nítòsí, ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti gbé aláìlera náà lọ sí Ẹ̀ka Ìtọ́jú Pàjáwìrì káwọn òṣìṣẹ́ àpéjọ wa tí wọ́n ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó, kí wọ́n bàa lè ṣèrànlọ́wọ́ tó bá yẹ kí wọ́n ṣe.
◼ Lílo Oògùn: Tó o bá ní oògùn tí ò ń lò, jọ̀wọ́ mú èyí tó máa tó ẹ lò dání wá sí àpéjọ, torí pé a lè máà ní irú oògùn bẹ́ẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ.
◼ Bàtà: Kó o má bàa fara pa, ó dára kó o wọ bàtà tí kò fi bẹ́ẹ̀ ga, tó máa jẹ́ kó o lè rìn dáadáa.
◼ Àwòkẹ́kọ̀ọ́: Kò ní bójú mu kí àwọn arábìnrin jẹ́ kí gèlè wọn ga débi tó fi máa dí àwọn tó bá jókòó sẹ́yìn wọn lójú lọ́sàn-án Sunday nígbà tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó mọ níwọ̀n tá à ń lò báyìí, títí kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a tún lè lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ.—Fílí. 2:4.
◼ Lọ́fíńdà: Ó máa fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò tí a kò bá lo àwọn lọ́fíńdà olóòórùn líle níwọ̀n, torí èyí lè ṣàkóbá fún àwọn tó níṣòro èémí.—1 Kọ́r. 10:24.
◼ Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò (S-43): Bẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan nígbà àpéjọ àgbègbè tí ẹni náà sì fìfẹ́ hàn, ẹ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tá a fi ń kọ ìsọfúnni nípa èyí, ìyẹn fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43). Kí àwọn akéde mú fọ́ọ̀mù kan tàbí méjì wá sí àpéjọ. Ẹ lè mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ bá ti kọ ọ̀rọ̀ sí fún wọn ní Ilé Ìgbàwé tàbí kẹ́ ẹ fún akọ̀wé ìjọ yín nígbà tẹ́ ẹ bá pa dà délé.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2009, ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 5 sí 6.
◼ Àwọn Búkà Oúnjẹ Àtàwọn Tó Ń Tajà Níwájú Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ẹ jẹ́ kí ìwà rere wa bọlá fún orúkọ Jèhófà tá a bá wà láwọn búkà oúnjẹ. Kò bọ́gbọ́n mu láti lọ ra oúnjẹ ní búkà tàbí lọ́wọ́ àwọn tó ń kiri ọjà nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Bí a bá rí ẹni tó fẹ́ ra ohunkóhun, ohun tó máa dáa jù lọ ni pé kí onítọ̀hún ṣe bẹ́ẹ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí.
◼ Ilé Gbígbé: (1) Fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù tó o bá fẹ́ gba ibi tó o máa dé sí níbi tẹ́ ẹ ti máa ṣe àpéjọ. (2) Má ṣe dé sínú ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kò bá ní kó o dé síbẹ̀. Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn nípa dídé sí kìkì ibi tí wọ́n bá ní kó o dé sí. (3) Kí àwọn arákùnrin má ṣe jẹ́ kí ilẹ̀ ṣú wọn sínú yàrá tó wà fún àwọn arábìnrin, wọn kò sì gbọ́dọ̀ sùn síbẹ̀. Àwọn arábìnrin pẹ̀lú kò sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (4) Bí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú nípa ibi tí wọ́n fi ẹ́ sí, rí i dájú pé o tètè fi tó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé létí kó o tó kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. (5) Bó bá jẹ́ pé òtẹ́ẹ̀lì lo dé sí, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń bójú tó òtẹ́ẹ̀lì náà. (6) Ibi tí wọ́n bá sọ pé o ti lè dáná nìkan ni kó o ti máa dáná. (7) Má ṣe dáná nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́, torí ìyẹn kò ní fi hàn pé o mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí.—Lúùkù 10:38-42.
◼ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Ayọ̀ tá a máa ní pé a wá sí àpéjọ náà á túbọ̀ pọ̀ sí i, tá a bá yọ̀ǹda ara wa láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó pọn dandan ní àpéjọ náà. (Ìṣe 20:35) Kí ẹni tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọ àgbègbè náà. Àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] pẹ̀lú lè yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n lè ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí tàbí alágbàtọ́ wọn tàbí àgbàlagbà míì tá a bá fà wọ́n lé lọ́wọ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 2]
Báwo La Ṣe Máa Pín Ìwé Ìkésíni Náà?
Kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ọ̀rọ̀ wa gbọ́dọ̀ ṣe ṣókí. Lẹ́yìn tó o bá ti kí ẹni náà, o lè sọ pé: “À ń pín ìwé ìkésíni yìí kárí ayé. Tìẹ rèé. Wàá rí ìsọfúnni síwájú sí i nínú ìwé náà.” A ṣe iwájú ìwé ìkésíni náà lọ́nà tó fani mọ́ra, torí náà jẹ́ kí ẹni tí ò ń bá sọ̀rọ̀ rí i dáadáa nígbà tó o bá fẹ́ mú un lé e lọ́wọ́. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀yàyà. Tó bá jẹ́ òpin ọ̀sẹ̀ lò ń pín ìwé ìkésíni náà, fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé ìròyìn wa pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.