Àpéjọ Àgbègbè Jẹ́ Àkókò Ìjọsìn Aláyọ̀
1. Ọ̀nà wo ni àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe ní Ísírẹ́lì gbà jọra pẹ̀lú àwọn àpéjọ àgbègbè tá à ń ṣe lóde òní?
1 Ọdọọdún ni Jósẹ́fù, Màríà, àwọn ọmọ wọn àtàwọn míì máa ń lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àjọyọ̀. Láwọn àkókò yìí, àwọn àtàwọn míì tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn máa ń gbé àwọn àníyàn wọn ojoojúmọ́ kúrò lọ́kàn, wọ́n sì máa ń pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí tó jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wọn. Àwọn àjọyọ̀ yìí máa ń fún wọn láǹfààní láti ronú nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún wọn, kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, kí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò Òfin Ọlọ́run. Àpéjọ àgbègbè wa tó ń bọ̀ lọ́nà máa fún àwa pẹ̀lú nírú àǹfààní yìí láti fi ayọ̀ jọ́sìn Jèhófà.
2. Kí ló yẹ ká ṣe láti múra sílẹ̀ fún àpéjọ àgbègbè tó ń bọ̀ lọ́nà?
2 Ó Yẹ Ká Múra Sílẹ̀: Jésù àti ìdílé rẹ̀ máa ń rin ìrìn àjò nǹkan bí igba [200] kìlómítà ní àlọ àti àbọ̀ láti ìlù Násárétì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ iye àbúrò tí Jésù ní, a lè fojú inú wo ìsapá àti ìmúrasílẹ̀ tí Jósẹ́fù àti Màríà ní láti ṣe. Ǹjẹ́ o ti ṣe àwọn ìmúrasílẹ̀ tó pọn dandan kó o lè wà ní àpéjọ náà lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta? Èyí lè gba pé kó o gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tàbí kó o gbàyè lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ tàbí lọ́dọ̀ olùkọ́ ọmọ rẹ. Tó o bá fẹ́ dé sí òtẹ́ẹ̀lì, ṣé o ti ṣètò tó yẹ? Ǹjẹ́ o lè lo ìdánúṣe láti ṣèrànwọ́ fún ẹni tó bá nílò àkànṣe àbójútó nínú ìjọ rẹ láti lọ sí àpéjọ náà?—1 Jòh. 3:17, 18.
3. Báwo ni àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe ní Ísírẹ́lì ṣe ń fún wọn láǹfààní láti gbé ara wọn ró?
3 Ìbákẹ́gbẹ́ Tó Ń Gbéni Ró: Àwọn àjọyọ̀ tí àwọn Júù máa ń ṣe máa ń fún wọn láǹfààní láti gbé ara wọn ró. Ó dájú pé inú Jésù àti ìdílé rẹ̀ máa ń dùn láti tún rí àwọn ọ̀rẹ́ wọn àtijọ́ nígbà àjọyọ̀ náà. Inú wọn tún máa ń dùn láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun láàárín ọ̀pọ̀ àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n máa wà níbi àjọyọ̀ náà tàbí àwọn tí wọ́n jọ máa rìnrìn àjò lójú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.
4. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa?
4 Ọ̀kan lára ìdí tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye fi ṣètò pé ká máa pé jọ láti gbọ́ àwọn àsọyé ní àpéjọ àgbègbè dípò kí wọ́n kàn máa tẹ àwọn ìsọfúnni náà jáde sínú ìwé ni pé ká lè máa fún ara wa ní ìṣírí. (Héb. 10:24, 25) Torí náà, ṣètò bó o ṣe máa tètè dé sí àpéjọ náà lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, kó o lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì kí alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó nasẹ̀ ohùn orin tó máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò ti tó láti lọ jókòó. Dípò ká kúrò nínú gbọ̀ngàn náà láti lọ jẹun ní ọ̀sán, á dáa ká gbé oúnjẹ ọ̀sán wa dání, ká lè wà ní àpéjọ náà láti ní ìfararora, ká sì jọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn tá a jọ wà ní àpéjọ náà. Ó yẹ ká mọyì ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa tó wà níṣọ̀kan, tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà.—Míkà 2:12.
5. Kí ló máa jẹ́ ká lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú àpéjọ náà?
5 Àkókò Láti Kẹ́kọ̀ọ́: Láti kékeré ni Jésù ti máa ń lo àǹfààní àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Baba rẹ̀ ọ̀run. (Lúùkù 2:41-49) Kí ló máa ran àwa àtàwọn ìdílé wa lọ́wọ́ ká lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà? Jókòó sáyè rẹ nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, má sì ṣe máa tàkúrọ̀sọ. Má ṣe jẹ́ kí fóònú alágbèéká rẹ, ohun èlò atanilólobó tàbí irú àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀ dí ìwọ tàbí àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Alásọyé ni kó o máa wò, kó o sì máa ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí. Kí àwọn ìdílé jókòó pa pọ̀, kí ẹ̀yin òbí lè rí i dájú pé àwọn ọmọ yín ń fetí sílẹ̀. Tó bá di ìrọ̀lẹ́, ẹ fi àkókò díẹ̀ jíròrò àwọn ohun tí ẹ gbádùn ní àpéjọ náà.
6. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa aṣọ àti ìmúra wa?
6 Aṣọ àti Ìmúra: Ó rọrùn fún àwọn oníṣòwò láti ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n ń rìnrìn àjò láti dá Jésù àti ìdílé rẹ̀ mọ̀ títí kan àwọn Júù yòókù tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn nígbà tí wọ́n bá ń lọ tàbí tí wọ́n ń bọ̀ láti ibi àjọyọ̀. Ìdí sì ni pé ìṣẹ́tí máa ń wà létí aṣọ wọn, okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sì máa ń wà lókè ìṣẹ́tí náà. (Núm. 15:37-41) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Kristẹni kì í wọ aṣọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, àwọn èèyàn mọ̀ wá sí ẹni tó máa ń múra ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì tó sì máa ń mọ́ tónítóní. Ó yẹ ká fún ìrísí wa láfiyèsí dáadáa nígbà tá a bá ń rìnrìn àjò lọ sí àpéjọ náà, nígbà tá a bá wà nílùú tí àpéjọ náà ti wáyé àti nígbà tá a bá ń pa dà lọ sílé. Kódà, bá a bá tiẹ̀ pààrọ̀ aṣọ wa lẹ́yìn ìpàdé, ó yẹ kí ìrísí wa bójú mu, ká sì de báàjì àpéjọ náà mọ́ àyà wa. Èyí á jẹ́ ká yàtọ̀ sí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn èèyàn á sì lè fi ojú tó dáa wò wá.
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú nípa yíyọ̀ǹda ara wa ní àpéjọ náà?
7 A Nílò Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni: A nílò àwọn òṣìṣẹ́ tó pọ̀ dáadáa kí nǹkan bàa lè lọ bó ṣe yẹ ní àpéjọ náà. Ṣé wàá yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣèrànwọ́? (Sm. 110:3) Àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe ní àpéjọ àgbègbè wa jẹ́ ara iṣẹ́ ìsìn mímọ́, ó sì máa ń jẹ́rìí lọ́nà rere. Inú ẹni tó ń bójú tó ibì kan tá a lò fún àpéjọ wa dùn gan-an nígbà tó rí iṣẹ́ tí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún ìmọ́tótó ṣe, èyí sì mú kó kọ̀wé pé: “Mò dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gidigidi fún ohun tó yani lẹ́nu jù lọ tí mo tíì fojú ara mi rí. Mo ti máa ń gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ní orúkọ rere lọ́dọ̀ wa pé wọ́n máa ń fi ibi tí wọ́n bá lò sílẹ̀ ní mímọ́ tónítóní ju bí wọ́n ṣe bá a lọ. Ẹ ti jẹ́ kí ibí yìí dùn ún wò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ fún àwọn ará ìlú yìí, àwọn èèyàn tí wọ́n sì gbayì jù lọ tó máa ń wù wá pé kí wọ́n rí mọ́ wa lẹ sì lò láti ṣe iṣẹ́ náà.”
8. Àwọn àǹfààní wo la máa ní láti jẹ́rìí ní ibi tí àpéjọ náà ti máa wáyé?
8 Àǹfààní Láti Jẹ́rìí: Ọ̀pọ̀ èèyàn tó bá wà ní ìlú tí àwọn àpéjọ náà ti máa wáyé máa kíyè sí àwọn èèyàn tí wọ́n wọṣọ tí wọ́n sì múra dáadáa, tí wọ́n fi báàjì àpéjọ náà sáyà, èyí lè mú kí wọ́n fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i, a ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣàlàyé fún wọn nípa àpéjọ náà. Ọmọ ọdún mẹ́rin kan mú ẹ̀dà ìwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde ní àpéjọ kan lọ sí ilé oúnjẹ lẹ́yìn tí ìpàdé parí, ó sì fi han ẹni tó ń tajà níbẹ̀. Èyí jẹ́ ko ṣeé ṣe fún àwọn òbí ọmọdékùnrin náà láti pe obìnrin tó ń ta oúnjẹ náà wá sí àpéjọ.
9. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù àti ìdílé rẹ̀ ní ti bí wọ́n ṣe mọyì àwọn àǹfààní tí wọ́n ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?
9 Àwọn Júù tí wọ́n fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa Jèhófà máa ń fojú sọ́nà fún àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe nígbà àtijọ́. (Diu. 16:15) Inú Jésù àti ìdílé rẹ̀ máa ń dùn láti yááfì ohunkóhun tó bá gbà kí wọ́n lè lọ, kí wọ́n sì jàǹfààní àjọyọ̀ náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Àwa pẹ̀lú mọyì àwọn àpéjọ àgbègbè wa, a gbà pé ó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa. (Ják. 1:17) Àkókò ti tó báyìí láti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún àǹfààní tá a máa ń ní lọ́dọọdún láti fi ayọ̀ jọ́sìn Jèhófà!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè
◼ Àkókò Ìpàdé: Aago mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú [9:20] ni ìpàdé máa bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà tí wọ́n bá ti ṣèfilọ̀ ohùn orin tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ àpéjọ, ó yẹ kí olúkúlùkù wa lọ jókòó ká lè bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ náà máa parí ní aago márùn-ún ku ìṣẹ́jú márùn-ún [4:55] ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday àti ọjọ́ Sátidé, ó sì máa parí ní aago mẹ́rin ku ogún ìṣẹ́jú [3:40] ní ọ̀sán Sunday.
◼ Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Ní gbogbo ibi tí àpéjọ ti máa wáyé, àwọn olùtọ́jú èrò máa darí wa síbi tá a máa gbé ọkọ̀ wa sí. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 14:40.
◼ Gbígba Àyè Ìjókòó Sílẹ̀: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọ ọkọ̀ kan náà tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbé nínú ilé kan náà àtàwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan lo lè gbàyè sílẹ̀ fún.—1 Kọ́r. 13:5.
◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tẹ́ ẹ fi máa kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti lọ wá oúnjẹ rà lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó máa ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. A kò sì gba ọtí líle láyè.
◼ Ọrẹ: A lè fi hàn pé a mọrírì ètò tá a ṣe láti mú kí àpéjọ yìí wáyé bá a bá fínnú fíndọ̀ fowó sínú àpótí ọrẹ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tàbí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Kí ẹni tó bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn ní àpéjọ àgbègbè fi hàn pé ètò Ọlọ́run ni òun fẹ́ kí wọ́n sanwó náà fún nípa kíkọ “Watch Tower” sórí sọ̀wédowó náà. Kẹ́ni náà kọ “Watch” àti “Tower” lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o, kó má ṣe kọ ọ́ pa pọ̀.
◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún olùtọ́jú èrò tó bá wà nítòsí, ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti gbé aláìlera náà lọ sí Ẹ̀ka Ìtọ́jú Pàjáwìrì káwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ ní àpéjọ wa lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó, kí wọ́n sì lè ṣèrànwọ́ tó bá yẹ.
◼ Gbígba Ohùn Sílẹ̀: A kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni so ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ èyíkéyìí mọ́ wáyà iná tàbí ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tá à ń lò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, kí ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ lo ẹ̀rọ tó ń gbohùn sílẹ̀ rí i dájú pé òun kò fi dí ẹlòmíì lọ́wọ́.
◼ Kẹ̀kẹ́ Tí Wọ́n Fi Ń Ti Àwọn Ọmọ Ọwọ́ Kiri: A kò fàyè gba kẹ̀kẹ́ tí wọ́n fi ń ti àwọn ọmọ ọwọ́ kiri ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Àmọ́, ẹ lè lo bẹ́líìtì ààbò, èyí tí òbí lè dè mọ́ ara ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí á sì wá gbé ọmọ sínú rẹ̀.
◼ Àwòkẹ́kọ̀ọ́: Kò ní bójú mu kí àwọn arábìnrin jẹ́ kí gèlè wọn ga débi tó fi máa dí àwọn tó bá jókòó sẹ́yìn wọn lójú lọ́sàn-án Sunday nígbà tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó mọ níwọ̀n tá à ń lò báyìí, títí kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a tún lè lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ.—1 Kọ́r. 10:24.
◼ Lọ́fíńdà: A máa fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò, tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ lo àwọn lọ́fíńdà olóòórùn líle, torí èyí lè ṣàkóbá fún àwọn tó níṣòro èémí.—Fílí. 2:4.
◼ Àwọn Búkà Oúnjẹ Àtàwọn Tó Ń Tajà Níwájú Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ẹ jẹ́ kí ìwà rere wa bọlá fún orúkọ Jèhófà tá a bá wà láwọn búkà oúnjẹ. Kò bọ́gbọ́n mu láti lọ ra oúnjẹ ní búkà tàbí lọ́wọ́ àwọn tó ń kiri ọjà nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́. Bí a bá rí ẹni tó fẹ́ ra ohunkóhun, ohun tó máa dáa jù lọ ni pé kí onítọ̀hún ṣe bẹ́ẹ̀ kí àpéjọ tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn tí àpéjọ bá parí.
◼ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Ayọ̀ tá a máa ní pé a wá sí àpéjọ náà á túbọ̀ pọ̀ sí i, tá a bá yọ̀ǹda ara wa láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó pọn dandan ní àpéjọ náà. (Ìṣe 20:35) Kí ẹni tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọ àgbègbè náà. Àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] pẹ̀lú lè yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n lè ṣíṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí tàbí alágbàtọ́ wọn tàbí àgbàlagbà míì tá a bá fà wọ́n lé lọ́wọ́.
◼ Ilé Gbígbé: (1) Fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù tó o bá ti dé síbi tí a ó ti ṣe àpéjọ, tí wọ́n sì ń fi ibi tó o máa dé sí hàn ẹ́. (2) Má ṣe dé sínú ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kò bá ní kó o dé síbẹ̀. Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn nípa dídé sí kìkì ibi tí wọ́n bá ní kó o dé sí. (3) Kí àwọn arákùnrin má ṣe jẹ́ kí ilẹ̀ ṣú wọn sínú yàrá tó wà fún àwọn arábìnrin, wọn kò sì gbọ́dọ̀ sùn síbẹ̀. Àwọn arábìnrin pẹ̀lú kò sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (4) Bí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú nípa ibi tí wọ́n fi ẹ́ sí, rí i dájú pé o tètè fi tó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé létí kó o tó kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. (5) Bó bá jẹ́ pé òtẹ́ẹ̀lì lo dé sí, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń bójú tó òtẹ́ẹ̀lì náà. (6) Ibi tí wọ́n bá sọ pé o ti lè dáná nìkan ni kó o ti máa dáná. (7) Má ṣe dáná nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́, torí ìyẹn kò ní fi hàn pé o mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí.—Lúùkù 10:38-42.
◼ Ètò Ìrìnnà: Torí pé ẹ̀mí ṣeyebíye, ó yẹ kí gbogbo wa fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò nígbà tá a bá ń ṣètò bá a ṣe fẹ́ wọkọ̀ lọ sí àpéjọ àgbègbè ti ọdún yìí. Kí àwọn alàgbà rí i dájú pé ọkọ̀ tó bójú mu ni wọ́n háyà. Kí àwọn táyà, bíréèkì àti iná ọkọ̀ náà jẹ́ èyí tó ń ṣiṣẹ́ dáradára. Bó bá tiẹ̀ máa gba pé kẹ́ ẹ fi kún owó ọkọ̀, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ gúnlẹ̀ láyọ̀. Àwọn awakọ̀ tó máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú yín lórí àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí ni kí ẹ gbà: kó má ṣe dẹ́rù pa ọkọ̀, kó má ṣe sá eré àsápajúdé, kó sùn dáadáa ní alẹ́ ọjọ́ tó máa ṣáájú ọjọ́ tó fẹ́ wà yín lọ sí àpéjọ, kó má sì ṣe mu ọtí líle kẹ́ ẹ tó gbéra tàbí nígbà tó bá ń wakọ̀. Ẹ jẹ́ kí ọ̀ràn ààbò jẹ yín lógún; bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ẹ máa yẹra fún ewu.—Òwe 22:3.