Máa Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
1. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àgbègbè ti ọdún yìí, kí sì nìdí tó fi bọ́ sí àkókò?
1 Aísáyà kọ̀wé pé: “Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.” (Aís. 30:18b) Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ ló wà nínú Bíbélì nípa bí Ọlọ́run ṣe mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó sì dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nídè. Kí lẹ̀kọ́ tí irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa olùjọsìn Jèhófà lóde òní? Kí la lè ṣe lásìkò yìí láti múra de “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà”? (Jóẹ́lì 2:31, 32) Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” tó ń bọ̀ lọ́nà yìí á mú ká ronú lórí àwọn ìbéèrè yẹn ká sì yẹ ara wa wò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Á ràn wá lọ́wọ́ láti máa fojú sọ́nà fún Jèhófà.
2. Ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a mọyì àpéjọ àgbègbè wa?
2 Ṣó o ti ń ṣètò táá jẹ́ kó o lè gbádùn gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta? Bí àpẹẹrẹ, ṣó o ti tọrọ ààyè lọ́wọ́ ọ̀gá ẹ níbi iṣẹ́? Má ṣe rò pé ààyè á ṣàdédé ṣí sílẹ̀ o. Kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà nípa ẹ̀. Lẹ́yìn náà, lọ tọrọ ààyè. (Neh. 2:4, 5) Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ fòní dónìí fọ̀la dọ́la lórí ọ̀rọ̀ ọkọ̀ tó máa gbé wa dé Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà, ibi tá a máa dé sí àtàwọn ọ̀ràn pàtàkì mìíràn. Bá a bá ṣètò tó ṣe gúnmọ́ báyìí, ó máa fi hàn pé a mọyì àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ti pèsè sílẹ̀ fún wa gan-an. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó bá kù díẹ̀ káàtó fún láti múra sílẹ̀ fún àpéjọ náà, pàápàá àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ.—Gál. 6:10.
3. Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ kó máa hàn nínú ìwà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tá a bá wà ní ìlú tá a ti ń ṣe àpéjọ?
3 Ìwà Rere Ń Buyì Kún Ọlọ́run: Láwọn àpéjọ wa térò máa ń pọ̀ sí, ìwà wa máa ń jẹ́rìí fáwọn tó wà ládùúgbò. Kí lèyí wá ń béèrè lọ́wọ́ gbogbo wa? Nígbà tá a bá wà nílé èrò, ilé àrójẹ tàbí àwọn ibi ìṣòwò mìíràn tó sún mọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà, ànímọ́ Kristẹni tá a fi ń ṣèwà hù bí ìpamọ́ra, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìfòyebánilò gbọ́dọ̀ lè mára tu àwọn tá a jọ wà níbẹ̀. (Gál. 5:22, 23; Fílí. 4:5) Gbogbo wa ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ tí ‘kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, tí kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, tí a kì í sì í tán ní sùúrù.’ Kódà tí ìṣòro bá dé tàbí tí nǹkan ò bá fara rọ pàápàá, ṣe ló yẹ kó máa wù wá láti “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 10:31; 13:5.
4. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti máa hùwà táá mú ìyìn bá Jèhófà?
4 Lẹ́yìn tí àpéjọ kan parí, inú máníjà òtẹ́ẹ̀lì kan dùn gan-an nígbà tó rí ìwà táwọn ọ̀dọ́ wa hù àti bí wọ́n ṣe múra débi tó fi sọ pé ó wu òun láti máa “gba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ilé èrò rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” Oríyìn gidi nìyẹn! Lára èrè tó wà nínú kẹ́yin òbí máa kọ́ àwọn ọmọ yín kẹ́ ẹ sì máa bójú tó wọn nìyẹn. Kò ní bójú mu káwọn òbí máa fi àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ láìsí àbójútó. Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa rí àbójútó tó péye nígbà gbogbo. (Òwe 29:15) Ǹjẹ́ kí ìwà àwọn ọmọ wa máa mú ìyìn bá Jèhófà kó sì máa mú ọkàn rẹ̀ yọ̀!—Òwe 27:11.
5. Báwo laṣọ àti ìmúra wa ṣe lè máa fìyìn fún Jèhófà?
5 Aṣọ Tó Bójú Mu àti Ìmúra Tó Yẹ Ọmọlúwàbí: Kálukú wa lè ṣe ohun táwọn èèyàn á fi máa lérò tó dáa nípa àpéjọ wa. A ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ tí kò bójú mu táráyé ń wọ̀ báyìí tàbí èyí tí kò buyì kúnni, àṣejù ò sì gbọ́dọ̀ wọ ìmúra wa. A gbọ́dọ̀ fi kókó yìí sọ́kàn nígbà tá a bá ń wọkọ̀ lọ́ wọkọ̀ bọ̀ láti Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, orúkọ Jèhófà àti ohun táwọn èèyàn á máa sọ nípa rẹ̀ ló gbọ́dọ̀ máa jẹ wá lógún jù kì í ṣe ohun tó wù wá tàbí èyí tó rọ̀ wá lọ́rùn. Ojúṣe àwọn olórí ìdílé ni láti rí i pé ìdílé wọn múra lọ́nà tó bójú mu tó sì ń fi ìyèkooro èrò inú hàn nígbà gbogbo.—1 Tím. 2:9.
6. Nígbà tá a bá ń najú, kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìrísí wa bójú mu bíi tìgbà tí àpéjọ ń lọ lọ́wọ́?
6 Bákan náà ló ṣe yẹ kí ìrísí wa bójú mu lákòókò tá a bá ń sinmi nínú ilé tá a dé sí tàbí ní òtẹ́ẹ̀lì, àti nígbà tá a bá wà nílé ìtajà àti nílé àrójẹ. Tá a bá fẹ́ jáde lọ jẹun lẹ́yìn ìpàdé òwúrọ̀ tàbí lẹ́yìn ìpàdé ọ̀sán, ó dára ká wọṣọ tó bójú mu. Bá a bá sì lo báàjì àyà, á jẹ́ ká láǹfààní láti wàásù fẹ́ni tá a bá bá pàdé.—2 Kọ́r. 6:3, 4.
7. Ọ̀nà wo la lè gbà fi kún ìwàlétòlétò àti ayọ̀ àpéjọ? (Wo “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè.”)
7 Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín, nítorí náà, yóò dìde láti fi àánú hàn sí yín.” (Aís. 30:18a) Pé a mọyì àánú àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wa gbọ́dọ̀ sún wa láti máa fìyìn fún un nípa ìwà àti ìrísí wa nígbà tá a bá péjọ ní àpéjọ àgbègbè. Ǹjẹ́ kí Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” ṣàlékún ògo Ọlọ́run wa kó sì ràn wá lọ́wọ́ láti máa wà ní ìfojúsọ́nà fún Un!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè
◼ Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ: Àpéjọ á bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú àárọ̀ [9:20 a.m.] lọ́jọ́ Friday. Yóò sì bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án géérégé ní àárọ̀ Sátidé àti Sunday. Tó bá ku ìṣẹ́jú díẹ̀ kí àpéjọ bẹ̀rẹ̀, alága á jókòó sórí pèpéle, ohùn orin Ìjọba Ọlọ́run á sì máa dún láti fi hàn pé àpéjọ máa tó bẹ̀rẹ̀. Oníkálukú ti gbọ́dọ̀ wà lórí ìjókòó lákòókò yẹn kí àpéjọ náà bàa lè bẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ á parí ní agogo márùn-ún kọjá ìṣẹ́jú márùn-ún [5:05 p.m.] nírọ̀lẹ́ Friday, á parí ní agogo márùn-ún kú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [4:35 p.m.] nírọ̀lẹ́ Sátidé, á sì parí ní agogo mẹ́rin ku ogún ìṣẹ́jú [3:40 p.m.] nírọ̀lẹ́ Sunday.
◼ Gbígba Ààyè Ìjókòó: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ kan náà, tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbé nínú ilé kan náà nìkan lo lè gba ààyè sílẹ̀ fún.
◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Jọ̀wọ́ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tí wàá fi fi Gbọ̀ngàn Àpéjọ sílẹ̀ láti lọ wá oúnjẹ rà lákòókò ìsinmi ọ̀sán. O lè jẹ oúnjẹ rẹ nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Jọ̀wọ́ má ṣe ṣe ilẹ̀ yánmọyànmọ, má sì ṣe já bébà tàbí ọ̀rá sílẹ̀. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó máa ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A ò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà oúnjẹ gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má gbà gbé pé kò tọ́ láti mu ọtí líle nígbà téèyàn bá ń lọ sí àpéjọ tàbí téèyàn bá fẹ́ bójú tó ojúṣe rẹ̀ nínú ìjọsìn Ọlọ́run.
◼ Fífowó Ṣètìlẹ́yìn: Owó kékeré kọ́ là ń ná láti ṣètò àpéjọ àgbègbè. A lè fi ìmọrírì wa hàn nípa fífínnúfíndọ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. A sì lè sọ irú owó tá a bá fẹ́ fi ṣètìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ sínú àpótí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tàbí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Kí ẹni tó bá fẹ́ ṣètìlẹ́yìn nípasẹ̀ ìwé sọ̀wédowó ní àpéjọ àgbègbè kọ “Watch Tower” sórí ìwé sọ̀wédowó náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n máa sanwó náà fún.
◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ fún olùtọ́jú èrò tó bá wà nítòsí, ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti mọ bí aláìlera náà ṣe máa dé Ẹ̀ka Ìtọ́jú Pàjáwìrì káwọn òṣìṣẹ́ àpéjọ wa tí wọ́n ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó kí wọ́n sì ṣèrànlọ́wọ́ tó bá yẹ kí wọ́n ṣe.
◼ Gbígba Ohùn Sílẹ̀: A kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni so ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ èyíkéyìí mọ́ wáyà iná tàbí ti ẹ̀rọ tá à ń lò ní àpéjọ. Kí ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ lo ẹ̀rọ tó ń gbohùn sílẹ̀ rí i pé òun ò fi dí ẹlòmíì lọ́wọ́.
◼ Fọ́tò Yíyà: Bó o bá máa ya fọ́tò nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́, má ṣe lo iná tó ń bù yẹ̀rì.
◼ Ẹ̀rọ Atanilólobó àti Fóònù Alágbèéká: Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ yìí dí àwọn ará lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀.
◼ Fọ́ọ̀mù Pàdà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò: Ẹ jẹ́ ká kọ ìsọfúnni sínú fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43), ìyẹn fọ́ọ̀mù tó ń rán wa létí láti padà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tá a bá wàásù fún láìjẹ́-bí-àṣà nígbà àpéjọ àgbègbè. Kí àwọn akéde mú ẹ̀dà fọ́ọ̀mù yẹn kan tàbí méjì dání. A lè rí fọ́ọ̀mù yìí gba ní Ilé Ìgbàwé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà. Ẹ lè mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ bá ti kọ ọ̀rọ̀ sí fún wọn ní Ilé Ìgbàwé tàbí kẹ́ ẹ fún akọ̀wé ìjọ yín nígbà tẹ́ ẹ bá padà délé.
◼ Àwòkẹ́kọ̀ọ́: Ó máa fi hàn pé àwọn arábìnrin nífẹ̀ẹ́ àwọn ará bí won ò bá jẹ́ kí gèlè wọn ṣe gẹngẹ débi tó fi máa dí àwọn tó bá jókòó sẹ́yìn wọn lójú láàárọ̀ Sunday nígbà tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ oníkẹ́jẹ́bú tá à ń lò báyìí tó fi mọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ṣeé lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ.
◼ Àwọn Ilé Elérò Púpọ̀: Fi èso tẹ̀mí sílò bó o bá ti dé sí ibi tí a ó ti ṣe àpéjọ, tí wọ́n sì ń fi ibi tó o máa dé sí hàn ọ́. Má ṣe dé sínú ilé elérò púpọ̀ tí wọ́n kọ́ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí kì í bá ṣe ibẹ̀ ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní kó o dé sí. Ibi tí wọ́n bá sọ pé o ti lè dáná nìkan ni kó o ti máa dáná o. A ti rí i gbọ́ pé àwọn kan máa ń dáná nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí ò fi hàn pé wọ́n mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí.—Lúùkù 10:38-42.