ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/06 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 9/06 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù September: Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la ó lò. Ká sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé nígbà tá a bá kọ́kọ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Bá a bá sì ń padà lọ sọ́dọ̀ gbogbo ẹni tó bá gbàwé lọ́wọ́ wa, ẹ jẹ́ ká ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Níbi tí wọ́n bá ti fìfẹ́ hàn, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn onílé kan bá sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ká fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú mìíràn. December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Àwọn ìwé tá a lè lò bí àfirọ́pò ni Iwe Itan Bibeli Mi àti ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.

◼ À ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ojú ìwé 21 sí 23, tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ ká gba àwọn padà.

◼ Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kíyè sí i pé àwọn àyípadà yìí pọn dandan nígbà tí ìjọ bá ń lọ sí àpéjọ àyíká, àpéjọ àkànṣe tàbí àpéjọ àgbègbè. Ìjọ tó bá ní àpéjọ àkànṣe gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ìpàdé tó wà fún ọ̀sẹ̀ náà, Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ni wọn ò ní ṣe. Bí wọ́n bá máa lọ sí àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè, wọ́n ní láti fagi lé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn; Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nìkan ni kí wọ́n ṣe lọ́sẹ̀ yẹn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́