Àpótí Ìbéèrè
◼ Ǹjẹ́ ó tọ́ kẹ́nì kan ṣàkójọ ọ̀rọ̀ táwọn tó níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa sọ, kó wá fún àwọn ẹlòmíì?
Kò burú tẹ́nì kan bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìlò àwọn ará ilé rẹ̀ àti díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àmọ́ o, ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ kó irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ jọ láti máa pín in fún gbogbo àwọn ará tàbí kó máa tà á fún wọn, nítorí pé ìyẹn jẹ́ rírú òfin ẹ̀tọ́ oní-ǹkan.—Róòmù13:1.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ nìkan la kọ sí àwọn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan, a ò kọ ibi táwọn tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ náà fún ti máa mú ọ̀rọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ó máa ṣàǹfààní tẹ́nì kan bá wá àwọn ibi téèyàn ti lè mú àwọn iṣẹ́ náà, tó sì wá tẹ̀ ẹ́ káwọn tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ náà fún lè lò ó? Rárá, kò ní ṣàǹfààní. Bákan náà, kò bójú mu pé kẹ́nì kan ṣàkójọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó wà fún Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, kó wá fún àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n lò ó. Èyí kò dára nítorí pé kò ní jẹ́ káwọn tẹ́ni náà fún fi àwọn kókó pàtàkì sọ́kàn. Fúnra akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ni kó ṣe ìwádìí. Àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí Jèhófà gbà ń lo Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè máa fi ‘ahọ́n tí Jèhófà ti kọ́’ sọ̀rọ̀.—Aísá. 50:4.