Jèhófà Ń Dá Wa Lẹ́kọ̀ọ́ Láti Ṣe Iṣẹ́ Yìí
1. Kí ni Jèhófà máa ń ṣe tó bá gbé iṣẹ́ kan lé àwọn èèyàn lọ́wọ́?
1 Bí Jèhófà bá gbé iṣẹ́ kan lé àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó tún máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà sọ fún Nóà pé kó ṣe iṣẹ́ kan tí kò ṣe rí, ìyẹn iṣẹ́ kíkan ọkọ̀ áàkì, Jèhófà tún sọ bó ṣe máa ṣe é fún un. (Jẹ́n. 6:14-16) Nígbà tí Ọlọ́run yan Mósè olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ ọlọ́kàn tútù láti bá àwọn àgbààgbà ọkùnrin ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Fáráò sọ̀rọ̀, Jèhófà mú kó dá a lójú pé: “Èmi alára yóò sì wà pẹ̀lú ẹnu rẹ, èmi yóò sì kọ́ ọ ní ohun tí ó yẹ kí o sọ.” (Ẹ́kís. 4:12) Tó bá wá kan iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ láti wàásù ìhìn rere, Jèhófà kò fi wá sílẹ̀. Ó ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí nípasẹ̀ ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí?
2. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run?
2 Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run: Gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà yẹ̀ wò kó o tó lọ sí ìpàdé. Bó o sì ṣe ń wo ọ̀nà tí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ń gbà gbé iṣẹ́ wọn kalẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣàlàyé rẹ̀, òye rẹ nípa béèyàn ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ á túbọ̀ jinlẹ̀. (Òwe 27:17) Mú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tìrẹ dání wá sípàdé, o sì lè kọ nǹkan sínú rẹ̀. Nígbà tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ bá tọ́ka sí ìwé náà lẹ́yìn tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan bá parí iṣẹ́ rẹ̀, fa ìlà sábẹ́ kókó pàtàkì tí wàá fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí, kó o sì kọ ọ̀rọ̀ sí àwọn àlàfo tó wà létí ìwé náà. Ọ̀nà tó dára jù lọ tó o lè gbà jàǹfààní nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí ni pé kó o máa kópa nínú rẹ̀. Ǹjẹ́ o ti forúkọ sílẹ̀? Bí wọ́n bá fún ẹ níṣẹ́, múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa, kó o sì ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ. Tó o bá wà lóde ẹ̀rí, lo àwọn ohun tó o ti kọ́.
3. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn?
3 Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn: A máa rántí àwọn àbá tá a máa gbé yẹ̀ wò ní ìpàdé yìí tá a bá ka àwọn ìwé tí wọ́n tọ́ka sí ká tó wá sípàdé, tá a sì múra sílẹ̀ láti dáhùn. Tá a bá jẹ́ kí ìdáhùn wa ṣe ṣókí, ó máa jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní láti dáhùn. Fọkàn sí àwọn àṣefihàn tí wọ́n bá ṣe dáadáa, kó o sì lo àwọn abá tó o bá rí i pé ó máa jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ túbọ̀ gbẹ́ṣẹ́. Tọ́jú ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ní àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣe kókó, kó o lè rí i lò lọ́jọ́ iwájú.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Ọlọ́run ń fún wa?
4 Bíi ti iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé Mósè àti Nóà lọ́wọ́, iṣẹ́ tá a gbé lé àwa náà lọ́wọ́ pé ká wàásù ìhìn rere ni gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn rárá. (Mát. 24:14) A lè kẹ́sẹ járí tá a bá gbára lé Jèhófà, Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá, tá a sì ń fi ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ń pèsè fún wa sílò.—Aísá. 30:20.