Fíforúkọ Sílẹ̀ Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
1 Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti ṣe gudugudu méje nínú dídá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere. Ọ̀pọ̀ nínú wá ṣì rántí bí a ṣe kún fún ìbẹ̀rùbojo tó àti bí a ṣe nímọ̀lára àìtóótun tó, nígbà tí a kọ́kọ́ forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, nísinsìnyí, a dúpẹ́ gidigidi fún ipa tí ó kó nínú ìdàgbàsókè wa tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ àti olùkọ́ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Fi wé Ìṣe 4:13.) Ìwọ ha ti forúkọ sílẹ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́ ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ yìí bí?
2 Àwọn wo ni ó lè forúkọ sílẹ̀? Ojú ìwé 73, ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa dáhùn pé: “Gbogbo awọn wọnni tí wọn nfi taapọn-taapọn darapọ pẹlu ijọ naa lè fi orukọ silẹ, tí ó ní ninu awọn ẹni titun tí wọn ṣẹṣẹ nwá si awọn ipade, niwọn bi igbesi-aye wọn bá ti wà ní ibamu pẹlu awọn ilana-ipilẹ Kristian.” A ké sí gbogbo àwọn tí ó tóótun—ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé—láti tọ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ, kí wọ́n sì forúkọ sílẹ̀.
3 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ fún 1997: Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún 1997 kárí onírúurú ẹ̀kọ́ àti àwọn ènìyàn inú Bíbélì. Ní àfikún sí mímú ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa dàgbà, a ń kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ọ̀pọ̀ ìṣura tẹ̀mí, tí ó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Òwe 9:9) Bí a bá múra ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, títí kan Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, tí a sì ń pésẹ̀ déédéé, a lè jẹ àǹfààní ńlá nípa tẹ̀mí láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.
4 Fún 1997, ọ̀pọ̀ jù lọ lára Bíbélì kíkà fún Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 2 ni kò gùn tó ti àwọn ọdún tí ó ti kọjá. Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ bá ń múra iṣẹ́ yìí sílẹ̀, kí ó ṣọ́ iye àkókò tí ó lò fún kíkàwé dáradára, kí ó sì pinnu mélòó lára ìṣẹ́jú márùn-ún tí a yàn fún un ni ó lè lò fún ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èyí yóò fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láyè láti lo àkókò rẹ̀ ní kíkún, kí ó sì mú ọ̀nà ìmọ̀wéékà rẹ̀ àti ọnà sísọ̀rọ̀ láìwòwé dàgbà.—1 Tim. 4:13.
5 A ti fi ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà kún ìgbékalẹ̀ Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 3, tí a gbé karí ìwé Ìmọ̀. Nítorí náà, arábìnrin kan lè yan yálà ìpadàbẹ̀wò, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, tàbí ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà, gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ fún iṣẹ́ àyànfúnni yìí. Àmọ́ ṣáá o, kí a máa bá a lọ láti fi ìtẹnumọ́ pàtàkì sórí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́, kì í ṣe sórí ìgbékalẹ̀.
6 Yálà o ní àǹfààní fífúnni ní ọ̀rọ̀ ìtọ́ni, àwọn kókó pàtàkì inú Bíbélì, tàbí iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, o lè fi ìmọrírì rẹ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run hàn nípa mímúra apá tìrẹ sílẹ̀ dáradára àti ṣíṣe ìdánrawò rẹ̀ dáradára, nípa gbígbé e kalẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú àti ìtara ọkàn, nípa ṣíṣàìré kọjá àkókò, nípa fífetí sí ìmọ̀ràn alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ àti fífi í sílò, àti nípa sísakun nígbà gbogbo láti fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ìforúkọsílẹ̀ rẹ yóò já sí ìbùkún fún ìwọ àti fún gbogbo àwọn tí ó wà níjokòó.