Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn August
Av. Av. Av. Av.
Iye: Hrs. Mags. R.V. Bi.St.
Aṣá. Àkàn. 537 135.5 9.5 60.2 10.3
Aṣá. Dééd. 19,025 71.0 5.5 26.0 5.8
Aṣá. Olù. 6,188 57.7 3.5 16.7 3.6
Akéde 174,736 10.8 0.7 3.5 1.0
ÀRÒPỌ̀ 200,486 Àwọn Tí A Batisí: 1,184
Inú wa dùn láti ròyìn góńgó kíkàmàmà tí a kò tí ì ní irú rẹ̀ rí nínú akéde. Fún ìgbà àkọ́kọ́, a kọjá góńgó 200,000, pẹ̀lú 200,486 tí ó ròyìn ní August. Èyí fi 2,832 ju góńgó tí a ní gbẹ̀yìn ní June. Ìpíndọ́gba ọdọọdún ti lọ sókè sí 191,558, ìbísí 3.6 nínú ọgọ́rùn-ún ju ìpíndọ́gba ọdún tí ó kọjá ti 184,940 akéde. A tún dórí góńgó tuntun ti 19,025 aṣáájú ọ̀nà déédéé. Iye tí a batisí, 13,184, jẹ́ iye tí ó ga jù lọ fún ọdún èyíkéyìí láti 1975, nígbà tí a ri 16,291 bọmi. Ìjọ 3,741 ni ó wà ní Nàìjíríà nísinsìnyí.
ÌRÒYÌN ÀTÀTÀ NÍPA ÌṢE ÌRÁNTÍ
Iye àwọn tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí ní April 2 jẹ́ 520,413, ìbísí àtàtà tí ó fi 12,644 ju ti ọdún tí ó kọjá lọ. Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí ìbísí títayọ lọ́lá wáyé ní ìpínlẹ̀ wa tí a sábà máa ń ṣiṣẹ́ nínú rẹ̀ dáradára. Àwọn 498 ni ó ṣàjọpín nígbà Ìṣe Ìrántí.