Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní December: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation fún ₦320, pẹ̀lú ìwé True Peace and Security—How Can You Find It? fún ₦80. Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun fún ₦120. Bí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, fi Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí fún ₦240, tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí lọni. Àwọn èdè yòó kù—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi fún ₦240. Bí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, fi ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí lọni. January àti February: Ẹ́fíìkì àti Haúsá—Yálà Alafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo? tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Gẹ̀ẹ́sì—Yálà Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun tàbí The Bible—God’s Word or Man’s? Ìgbò—Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, True Peace and Security—How Can You Find It?, tàbí Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ. Ísókó—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Yorùbá—Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. (A óò fi gbogbo ìwé olójú ewé 192 tí ó wà lókè yìí lọni ní ẹ̀dínwó ₦50 [iye tí aṣáájú ọ̀nà yóò gbà á, ₦40]; ìwé Walaaye Titilae ní Ẹ́fíìkì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, àti Yorùbá jẹ́ ₦80 [iye tí aṣáájú ọ̀nà yóò gbà á, ₦50]. A ti fi lẹ́tà tí ó sọ̀rọ̀ nípa èyí ránṣẹ́ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ní May.) ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Kí àwọn ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé béèrè fún àwọn ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ti 1996 pẹ̀lú ìwé ìbéèrè ẹrù wọn ti December.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.
◼ Ìṣe Ìrántí fún 1998 yóò jẹ́ ní Saturday, April 11, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. A pèsè Ìsọfúnni ṣáájú nípa déètì ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí 1998 yìí, kí àwọn ará lè ṣètò tàbí ṣe àdéhùn tí ó pọn dandan fún àwọn gbọ̀ngàn tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, bí ìjọ tí ó pọ̀ bá ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí wọ́n sì ní láti wá àwọn ilé mìíràn.
◼ Nítorí ìjẹ́pàtàkì ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ní yíyan ẹni tí yóò sọ̀rọ̀ Ìṣe Ìrántí, kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yan ọ̀kan lára àwọn alàgbà tí wọ́n tóótun dáradára, dípò lílo gbogbo alàgbà ní ìtòtẹ̀léra tàbí lílo arákùnrin kan náà lọ́dọọdún.
◼ Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí Tuntun Tí Ó Wà:
Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun (Kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí márùn-ún ni ó wà nínú álúbọ́ọ̀mù kan) —Gẹ̀ẹ́sì
◼ Kásẹ́ẹ̀tì Fídíò Tuntun Tí Ó Wà:
To the Ends of the Earth —Gẹ̀ẹ́sì