Yíyọ Ayọ̀ Ìbísí tí Ọlọ́run Ń Fi Fúnni
1 Àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ onítara oníwàásù Ìjọba. Wọ́n yọ̀ nígbà tí ‘àwọn ìjọ pọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.’ (Ìṣe 16:5) Ìwàásù aláìṣojo wọ́n gbòòrò dé Éṣíà, Europe, àti Áfíríkà, tí ó sì yọrí sí ọ̀pọ̀ ìkórè àwọn onígbàgbọ́.
2 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, iṣẹ́ ìwàásù yóò dé ‘gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè’! (Mat. 24:14) Nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 1996, a ń bá a lọ láti gba ìròyìn nípa ìbísí kíkọyọyọ àti góńgó tuntun nínú akéde láti àwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé. A ti dá ọ̀pọ̀ ìjọ tuntun sílẹ̀. Ìbísí yíyára kánkán yìí tí mú kí ó pọn dandan láti kọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àti àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti láti mú àwọn ilé ẹ̀ka mélòó kan gbòòrò sí i.
3 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 1996 ròyìn iṣẹ́ ilé kíkọ́ gbìgbòòrò rẹpẹtẹ tí ń lọ lọ́wọ́ ní Áfíríkà. Ìgbòkègbodò kan náà ń lọ lọ́wọ́ jákèjádò Latin America. Fún ọdún iṣẹ́ ìsìn 1996, Mexico ròyìn góńgó kíkàmàmà ti 470,098 nínú akéde, àti ìpíndọ́gba 600,751 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí ó béèrè fún dídá 466 ìjọ tuntun sílẹ̀! A ṣètò pé kí ìmúgbòòrò àwọn ilé ẹ̀ka wọ́n parí ní òpin 1999. Ìbísí kan náà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè míràn kò fàyè gba dídẹwọ́ nínú onírúurú ìdáwọ́lé iṣẹ́ ìkọ́lé ìṣàkóso Ọlọ́run.
4 Àwọn ohun èlò ìkọ́lé wọ́n gógó níbi gbogbo, ìwọ̀nba sì ni àwọn ará wa ní ọ̀pọ̀ jù lọ ilẹ̀ ní láti fi tọrẹ nípa ti ara. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ìtara ńlá tí wọ́n ní fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, wọ́n ń gbèrú sí i nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní ti gidi. Òwe 28:27 fi dá wa lójú pé, “ẹni tí ó bá ń fi fún olùpọ́njú kì yóò ṣe aláìní.” Ìmúratán wa láti ṣèrànwọ́ ní bíbójú tó àwọn ìnáwó ìkọ́lé wọ̀nyí, ń yọrí sí “ìmúdọ́gba” àwọn ohun ti ara, ní mímú kí ó ṣeé ṣe fún gbogbo wa láti jèrè ayọ̀ tí ń wá láti inú fífúnni àti ìdùnnú tí ń wá láti inú rírí ìbísí tí Jèhófà ń fi fúnni!—2 Kọr. 8:14, 15; Ìṣe 20:35.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ẹ̀ka Paraguay
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ẹ̀ka Ecuador
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Ìmúgbòòrò Tí A Ń Kọ́ Lọ́wọ́ ní Mexico
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Ẹ̀ka Dominican Republic
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ẹ̀ka Brazil Pẹ̀lú Ìmúgbòòrò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Ẹ̀ka Uruguay Tí A Ń Kọ́ Lọ́wọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àpẹẹrẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí kò náni lówó púpọ̀ ní Latin America
1. Brazil
2. Nicaragua
3. Chile
4. Colombia
5. Mexico
6. Brazil
7. Peru
8. Venezuela
9. Mexico