ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/96 ojú ìwé 3-6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 12/96 ojú ìwé 3-6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ September 2 sí December 23, 1996. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.

[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]

Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

1. “Ẹranko ẹhànnà” tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, tí a ṣàpèjúwe nínú Ìṣípayá 13:1, kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Sátánì Èṣù. [1, uw-YR ojú ìwé 63 ìpínrọ̀ 4]

2. Kò sí “ẹja ńlá” tí ó lè gbé odidi ènìyàn mì ní ti gidi. (Jónà 1:17) [11, w89-YR 4/15 ojú ìwé 31, àpótí]

3. Àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì 9:24, 25 tọ́ka sí ìbí Jésù. [6, kl-YR ojú ìwé 36 ìpínrọ̀ 8]

4. Àsọtẹ́lẹ̀ inú Míkà 3:12 tọ́ka sí ìparun àti ìsọdahoro Jerúsálẹ́mù, tí ó wáyé ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. [12, w89-YR 5/1 ojú ìwé 15]

5. A gbọ́dọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run ní ẹ̀mí, ní jíjẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ń sún ṣiṣẹ́; gbogbo ohun tí a béèrè lọ́wọ́ wa kò ju ìyẹn lọ. [12, kl-YR ojú ìwé 45 ìpínrọ̀ 4]

6. Àwọn ohun mẹ́ta tí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà ni (1) ìlà ìran Jésù, (2) àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní ìmúṣẹ, àti (3) gbólóhùn ẹ̀rí ti Jèhófà Ọlọ́run. [5 sí 8, kl-YR ojú ìwé 33 sí 38 ìpínrọ̀ 6 sí 10]

7. A darí àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà ní tààràtà sí ìjọba ẹ̀yà méjì Júdà. [5, w89-YR 3/1 ojú ìwé 14]

8. Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan yẹ kí a yẹ ìjọsìn wa wò láti rí i dájú pé àwọn àṣà aláìwà-bí-Ọlọ́run kò kó èérí bá a, kí a sì lóye ojú ìwòye Ọlọ́run tí a là sílẹ̀ nínú Jákọ́bù 1:27. [17, kl-YR ojú ìwé 51 ìpínrọ̀ 20]

9. Ní ìbámu pẹ̀lú Sefanáyà 3:9, a óò so àwọn ènìyàn Ọlọ́run pọ̀ ṣọ̀kan nínú ayé tuntun, nítorí gbogbo wọn yóò sọ èdè kan náà—Hébérù. [16, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; w89-YR 6/1 ojú ìwé 30, àpótí.]

10. Ní ìmúṣẹ Dáníẹ́lì 12:1, Máíkẹ́lì ti “ń dúró” láti ọdún 1914, nígbà tí ó di Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run; láìpẹ́ òun yóò “dìde” ní orúkọ Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí Ọba Ajagun, tí kò ṣeé ṣẹ́gun, ní mímú ìparun wá sórí ètò búburú ìsinsìnyí. [4, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w93-YR 11/1 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 23.]

Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:

11. Àwọn wo ni “àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè” tí a tọ́ka sí nínú Hágáì 2:7 (NW), ọ̀nà wo sì ni wọ́n gbà “ń wọlé wá”? [17, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 6/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 4.]

12. Ọ̀rọ̀ wo nínú Ìwé Mímọ́ tí àwọn ọmọ Hébérù mẹ́ta náà sọ ni ó fi hàn pé wọn kò gbé ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run lórí rírí ààbò àti ìdáǹdè àtọ̀runwá gbà? (Dan. 3:16-18) [4, w88-YR 12/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 14]

13. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ibi tí a óò bí Mèsáyà náà sí? [12, w89-YR 5/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 5, àpótí]

14. Èé ṣe tí àwọn iṣẹ́ agbára tí a ṣe ní orúkọ Jésù kì í fi í ṣe ẹ̀rí tí ó dájú pé a rí ojú rere tàbí ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run? [13, kl-YR ojú ìwé 46 ìpínrọ̀ 6, 7]

15. Kí ni Orin Dáfídì 2:2 fi hàn nípa bí gbogbo ènìyàn yóò ṣe tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tí a ṣèlérí náà? [7, kl-YR ojú ìwé 36 ìpínrọ̀ 9]

16. Níwọ̀n bí àwọn ọ̀nà ìjọsìn kan ti wà tí Jèhófà kò tẹ́wọ́ gbà, kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe, bí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa? [12, kl-YR ojú ìwé 45 ìpínrọ̀ 5]

17. Níwọ̀n bí gbígba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa tí ṣe kókó nínú ìjọsìn tòótọ́, èé ṣe tí Jésù kì yóò fi tẹ́wọ́ gba àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? [13, kl-YR ojú ìwé 46 ìpínrọ̀ 6, 7]

18. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù ọjọ́ Jésù lérò pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn, ojú wo ni Jésù fi wò ó, báwo ni a sì ṣe lè ṣe bí wọ́n ti ṣe? [14, kl-YR ojú ìwé 48 ìpínrọ̀ 12, 13]

19. Ní Hágáì 2:9, tẹ́ḿpìlì wo ni “ilé ìkẹyìn,” èwo sì ni ti “ìṣáájú,” èé sì ti ṣe tí ògo “ilé ìkẹyìn” fi pọ̀ ju ti “ìṣáájú” lọ? [17, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 6/1 ojú ìwé 30, àpótí.]

20. Kí ni Hóséà 14:2 ń rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣe, báwo sì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ lónìí? (Heb. 13:15) [7, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 9/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1, 2.]

Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

21. Wòlíì _________________________ pe ìlú _________________________ ní ìlú ìtàjẹ̀sílẹ̀, ní nǹkan bí 200 ọdún lẹ́yìn tí _________________________ ti parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fún un níbẹ̀. [11, 14, w89-YR 4/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1, w89-YR 5/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 5]

22. Sátánì máa ń fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ré àwọn ènìyàn lọ sínú títẹ́ ìfẹ́ ọkàn _________________________ lọ́rùn, ní ọ̀nà _________________________ [2, uw-YR ojú ìwé 65 ìpínrọ̀ 9]

23. Láti di ẹni tí a dáàbò bò nípa tẹ̀mí, a kò gbọ́dọ̀ ṣàìnáání gbígbé èyíkéyìí nínú ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ Ọlọ́run wọ̀, tí ó ní _________________________ “àwo ìgbàyà ti _________________________ “ohun ìṣiṣẹ́ _________________________ àlàáfíà,” “apata ńlá ti _________________________ “àṣíborí _________________________ àti _________________________ ẹ̀mí” nínú. [3, uw-YR ojú ìwé 68 ìpínrọ̀ 14]

24. Àwọn tí ń tẹ̀ lé ìsìn àtọwọ́dọ́wọ́, nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù àti ní òde rẹ̀, rò pé àwọ́n ní _________________________ ọkàn, tí yóò sọ _________________________ di ohun tí kò ṣe pàtàkì. [6, uw-YR ojú ìwé 71 ìpínrọ̀ 3]

25. Tẹ̀ lé ìparun Jerúsálẹ́mù láti ọwọ́ àwọn ará Róòmù ní ọdún _________________________ _________________________ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan pòórá nínú ìtàn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọbadáyà ti sọ tẹ́lẹ̀. [11, w89-YR 4/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2, àpótí]

Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

26. Àwọn obìnrin onífẹ̀ẹ́ fàájì tí ń gbé ní Samáríà, ni a pè ní “màlúù Báṣánì” nítorí pé wọ́n (sanra, wọ́n sì lọ́rọ̀ gan-an; jẹ́ olùgbé Báṣánì; ti àwọn ọkọ wọn láti lọ́ owó gbà lọ́wọ́ àwọn òtòṣì) (Ámósì 4:1) [10, w89-YR 4/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 2, àpótí]

27. Ìwé Ámósì, tí a kọ láàárín (ọdún 855 ṣáájú Sànmánì Tiwa; ọdún 829 ṣáájú Sànmánì Tiwa; ọdún 830 ṣááju Sànmánì Tiwa;) sí ọdún 804 ṣááju Sànmánì Tiwa, pèsè òye sínú (ìmúratán; ìríran jìnnà; agbára) Ọlọ́run láti rí àwọn ìjábá tí ń bọ̀ lọ́nà. [9, w89-YR 4/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 2]

28. Lẹ́yìn tí ó ti dàgbà, tí ó sì dáwọ́ lé iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ẹni ọdún (33; 29; 30), Jésù tún fi (ọ̀wọ̀; ìfẹ́ ọkàn; ìfẹ́) jíjinlẹ̀ tí ó ní fún ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ hàn. [10, kl-YR ojú ìwé 40 ìpínrọ̀ 16]

29. (Pétérù; Jòhánù; Pọ́ọ̀lù) ṣàyọlò Jóẹ́lì 2:32 nínú (Ìṣe 2:40; Róòmù 10:13; Tímótì Kìíní 2:4), níbi tí ó ti tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàki kíké pe orúkọ Jèhófà. [8, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 4/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 16.]

30. Ọba kan àti gómìnà kan lọ́wọ́ nínú ikú (Jákọ́bù; Sítéfánù; Jésù). Láti ìgbà náà lọ, àwọn ọ̀tá tẹ́lẹ̀ rí náà, (Pọ́ọ̀lù; Bánábà; Hẹ́rọ́dù) àti (Káyáfà; Pílátù; Bánábà) di ọ̀rẹ́ ojú ẹsẹ̀. [7, kl-YR ojú ìwé 36 ìpínrọ̀ 9]

So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí: 1 Tim. 2:3, 4; Hos. 10:12; Sef. 2:1-3; Jak. 1:26, 27; 1 Joh. 2:15-17

31. Kí Ọlọ́run baà lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, kì í ṣe pé àwọn àṣà ayé kò gbọdọ̀ kó èérí bá a nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún gbọ́dọ̀ ní gbogbo ohun tí Ọlọ́run kà sí pàtàkì nínú pẹ̀lú. [17, kl-YR ojú ìwé 51 ìpínrọ̀ 20]

32. Nípa ṣíṣe ohun tí ó tọ́ nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, a óò kórè ìṣeun ìfẹ́ Jèhófà. [6, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 3/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 2, 3.]

33. A gbọ́dọ̀ tiraka láti gba ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, kí a sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ní títòrò pinpin mọ́ àwọn ohun tí ó béèrè fún ìjọsìn tí ó ṣètẹ́wọ́gbà. [16, kl-YR ojú ìwé 52 ìpínrọ̀ 22]

34. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, a gbọ́dọ̀ yẹra fún àṣà èyíkéyìí tí ó yí wa ká, tí ń gbé ẹ̀mí ayé aláìwà-bí-Ọlọ́run yọ. [15, kl-YR ojú ìwé 50 ìpínrọ̀ 17]

35. Láti jẹ́ ẹni tí a pa mọ́ ní ọjọ́ Jèhófà, a nílò ju ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ lóréfèé lọ. [16, w89-YR 6/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 4]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́