Wàásù Ìjọba Náà
1 Ní Hébérù 10:23, a rọ̀ wá láti “di ìpolongo ìrètí wa ní gbangba mú ṣinṣin.” A sì gbé ìrètí wa karí Ìjọba Ọlọ́run. Jésù pàṣẹ ní ti gidi pé kí a wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè. (Mak. 13:10) A ní láti ní èyí lọ́kàn nígbà tí a bá ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
2 Nígbà tí a bá kàn sí àwọn ènìyàn, a máa ń gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa ohun kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí tàbí tí ó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń mẹ́nu kan ohun tí wọ́n mọ̀ dáradára, irú bí ìwà ọ̀daràn ní àdúgbò, ìṣòro àwọn ọ̀dọ́, àníyàn ìgbọ́bùkátà, tàbí yánpọnyánrin àlámọ̀rí ayé. Níwọ̀n bí ọkàn ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ti wà lórí àwọn “àníyàn ìgbésí ayé” wọ̀nyí, nígbà tí a bá fi hàn pé a bìkítà, a sì lóye ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn, àwọn ènìyàn lọ́pọ̀ ìgbà yóò sọ ohun tí ó wà lọ́kàn wọn jáde. (Luk. 21:34) Èyí lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti ṣàjọpín ìrètí wa pẹ̀lú wọn.
3 Ṣùgbọ́n, bí a kò bá ṣọ́ra, ìjíròrò náà lè dá lórí àwọn ohun tí kò gbéni ró, débi pé, a óò kùnà láti ṣàṣeparí ète tí a fi ṣèbẹ̀wò—láti wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Bí a tilẹ̀ ń pe àfiyèsí sórí àwọn ipò burúkú tí ń mú ọ̀pọ̀ ìrora ọkàn wá, ète wa jẹ́ láti darí àfiyèsí sórí Ìjọba náà, tí yóò yanjú gbogbo ìṣòro aráyé nígbẹ̀yìngbẹ́yín. A ní ìrètí àgbàyanu ní tòótọ́ tí ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ènìyàn gbọ́. Nítorí náà, bí a tilẹ̀ lè jíròrò àwọn apá díẹ̀ lára “àwọn àkókò líle koko tí ó nira lati bálò” wọ̀nyí, ní ìbẹ̀rẹ̀, a gbọ́dọ̀ tètè darí àfiyèsí sórí apá pàtàkì ìhìn iṣẹ́ wa, “ìhìn rere àìnípẹ̀kun.” Ní ọ̀nà yìí, a óò ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.—2 Tim. 3:1; 4:5; Iṣi. 14:6.