À Ń Wàásù Ìhìn Rere Ìjọba Ọlọ́run Fáwọn Ẹlòmíì
1 Púpọ̀ nínú àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko yìí ni ò gbà gbọ́ pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. (Éfé. 2:12) Àwọn míì ti fàìmọ̀kan gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀, àwọn alákòóso ayé, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àtàwọn nǹkan míì. Ẹ ò ri bí ayọ̀ wa ti pọ̀ tó torí a mọ̀ pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa! Mímọ̀ tá a mọ̀ pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa yìí ni “ìdákọ̀ró fún ọkàn wa, ó dájú, ó [sì] fìdí múlẹ̀ gbọn-in.”—Héb. 6:19.
2 Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso, ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè. Àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú máa jíǹde. (Ìṣe 24:15) Àìríná-àìrílò, ìwà ìrẹ́nijẹ, àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú máa wábi gbà. (Sm. 9:18; Mát. 12:20, 21; Ìṣí. 21:3, 4) Díẹ̀ rèé lára àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣèlérí pé òun yóò ṣe. Ó dáa ná, èwo lo máa fẹ́ kí Ọlọ́run kọ́kọ́ ṣe nínú àwọn ohun tó ṣèlérí wọ̀nyí?
3 Wàásù Ìhìn Rere: A ò gbọ́dọ̀ fi ìgbàgbọ́ tá a ní pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run mọ sọ́dọ̀ ara wa. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa, à ń fara wé Jésù bá a ṣe ń “polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì,” tá à ń “wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú,” tá a sì ń “rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀.” (Lúùkù 4:18) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù ìhìn rere yìí nínú ọjà àti níbikíbi tó bá ti ráwọn èèyàn. Ó jẹ́ kí ọwọ́ òun dí jọjọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣe 18:5) Tá a bá fara wé Pọ́ọ̀lù tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” ò ní jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run wọ̀ọ̀kùn.—Máàkù 4:19.
4 A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ìjọba Ọlọ́run ṣákìí nígbà tá a bá pàdé àwọn tí ò fìfẹ́ hàn, àwọn tí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà ò jinlẹ̀ tó tàbí àwọn tó ń ta kò wá lójú méjèèjì. Ńṣe ni ká yáa “di ìpolongo ìrètí wa ní gbangba mú ṣinṣin láìmikàn.” (Héb. 10:23) Ká sì má ṣe “tijú ìhìn rere.” (Róòmù 1:16) Ó wá lè jẹ́ pé rírí táwọn míì bá rí i pé ìgbàgbọ́ wa dá wa lójú tí wọ́n sì rí i pé à ń fara da àdánwò ló máa mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́tí sí wa.
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń sọ fáwọn èèyàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń nímùúṣẹ ló fà á tí ipò nǹkan fi ń burú si nínú ayé, síbẹ̀ a kì í ṣe oníwàásù ègbé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run là ń wàásù. Ǹjẹ́ ká máa fìtara wàásù ìhìn rere yìí pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó dájú ká lè ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin.”—Héb. 6:11.