Máa Rìn bí Ọlọ́gbọ́n
1 Nígbà tí Jésù pe àwọn apẹja mẹ́rin pé kí wọ́n wá di ọmọlẹ́yìn òun, wọn ò fi ìpinnu wọn falẹ̀ rárá, “kíá, . . . wọ́n tẹ̀ lé e.” (Mát. 4:18-22) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ará Tásù di Kristẹni tójú rẹ̀ tó ti fọ́ sì tún ríran, òun náà ò fàkókò ṣòfò, “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Jésù nínú àwọn sínágọ́gù.” (Ìṣe 9:20) Àkókò ò dúró dẹnì kan, tọ́jọ́ bá ti lọ, kò ṣe mú so lókùn. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa “rìn gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n” tó bá dọ̀rọ̀ lílo àkókò wa.—Éfé. 5:15, 16.
2 Ìṣẹ̀lẹ̀ Tá Ò Rí Tẹ́lẹ̀: Àwọn àǹfààní tá a ní láti lo ara wa fún Jèhófà lónìí lè máà sí mọ́ lọ́la. (Ják. 4:14) Kò sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ àwọn “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníw. 9: 11) Bá a ṣe ń dàgbà sí i nínú ayé búburú yìí, ṣe làwọn “ọjọ́ oníyọnu àjálù” tí ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tó ń dé bá wa lọ́jọ́ ogbó ń dín ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kù. (Oníw. 12:1) Nítorí náà, kò yẹ ká máa fòní dónìí, fọ̀la dọ́la tó bá dọ̀rọ̀ ká ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run tàbí ká máa retí ìgbà tí nǹkan máa rọ̀ wá lọ́rùn ká tó mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i. (Lúùkù 9:59-62) Ábúráhámù ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn lọ́jọ́ ogbó rẹ̀, kó tó kú “ó darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn,” nítorí ó fara ẹ̀ fún Jèhófà pátápátá, èyí sì fi hàn pé ó fọgbọ́n lo ìgbésí ayé rẹ̀.—Jẹ́n. 25:8.
3 Àsìkò Ti Lọ!: Ó tún yẹ ká máa fọgbọ́n lo àkókò wa nítorí pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́r. 7:29-31) Láìpẹ́, ayé búburú yìí á dópin. Àǹfààní tá a sì ní láti kópa nínú kíkó àwọn ẹni-bí-àgùntàn jọ nígbà “ìkórè ilẹ̀ ayé” náà á dópin. (Ìṣí. 14:15) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí àníyàn ìgbésí ayé àtàwọn nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà má gba àkókò tó yẹ ká lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́wọ́ wa. (Lúùkù 21:34, 35) Ẹ wo bí ayọ̀ wa yóò ti pọ̀ tó nígbà tá a bá wẹ̀yìn wò tá a sì rí i pé a ti ṣe ipa tiwa nínú iṣẹ́ ìkórè náà!
4 A gbọ́dọ̀ wà lójúfò ní gbogbo ìgbà, ká má ba pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ń fúnni láyọ̀ tá a lè ní. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti lo ara wa fún Jèhófà, “níwọ̀n ìgbà tí a bá ti lè pè é ní ‘Òní.’” (Héb. 3:13) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n, nítorí “ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòh. 2:17.