Pípolongo Òtítọ́ Lójoojúmọ́ ní Fífara Wé Jesu
1 Jesu ní iṣẹ́ pàtó kan láti parí nígbà tí ó fi wá sí orí ilẹ̀ ayé. Ní ṣókí: ‘Láti jẹ́rìí sí òtítọ́.’ (Joh. 18:37) Ó polongo òtítọ́ nípa àwọn àgbàyanu ànímọ́ àti ète Bàbá rẹ̀. Iṣẹ́ yìí dà bí oúnjẹ fún un; gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ dá lé e lórí. (Joh. 4:34) Luku ròyìn pé Jesu “ń kọ́ni lójoojúmọ́ ninu tẹmpili.” (Luku 19:47) Jesu lo àkókò tí ó ṣẹ́ kù ní kíkún. (Joh. 9:4) Kété ṣáájú ikú rẹ̀, òún lè polongo fún Bàbá rẹ̀ pé: “Mo ti yìn ọ́ lógo ní ilẹ̀-ayé, ní píparí iṣẹ́ tí iwọ ti fún mi lati ṣe.”—Joh. 17:4.
2 Nígbà tí ọkàn-àyà wa bá kún fún ìmọrírì fún gbogbo ohun tí Jehofa ti ṣe, a óò sún àwa pẹ̀lú láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lójoojúmọ́. A óò dà bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu tí wọ́n polongo láìbẹ̀rù pé: “Awa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nipa awọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:20) Wọ́n ń bá sísọ̀rọ̀ nípa Jehofa nìṣó, nítorí àkọsílẹ̀ náà sọ pé, “Ní ojoojúmọ́ . . . wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀.” (Ìṣe 5:42) Ó yẹ kí á bi ara wa léèrè pé, ‘Mo ha jẹ́ aláfarawé Olùkọ́ mi, Jesu bí?’
3 Wíwàásù Pẹ̀lú Ìjẹ́kánjúkánjú: Jesu sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà tí a bá ti polongo ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé tán, “nígbà naa ni òpin yoo sì dé.” (Matt. 24:14) Èyí yẹ kí ó mú wa nímọ̀lára ìjẹ́pàtàkì àti ìjẹ́kánjúkánjú iṣẹ́ wa. Bí ìwàláàyè àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti wà nínú ewu, kò sí ohun tí ó tún ṣe pàtàkì tàbí ṣàǹfààní ju èyí lọ láti ṣe. Níwọ̀n bí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti ń sún mọ́ òpin rẹ̀, àkókò tí ó ṣẹ́ kù láti parí iṣẹ́ yìí ti dín kù!
4 Ìròyìn fi hàn pé Jehofa ń mú ìkójọ àwọn ẹni bí àgùntàn yára kánkán. (Isa. 60:22) Ní ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn ń rọ́ wá ní ti gidi sínú òtítọ́, tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ polongo tìdùnnútìdùnnú pé: “A óò bá ọ lọ, nítorí àwá ti gbọ́ pé, Ọlọrun wà pẹ̀lú rẹ”! (Sek. 8:23) Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Ìkórè pọ̀, ṣugbọn ìwọ̀nba díẹ̀ ni awọn òṣìṣẹ́. . . . Ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè lati rán awọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀,” jẹ́ òtítọ́ nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Matt. 9:37, 38) Ìyẹn kò ha sún wa láti jẹ́ onítara bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu tí wọ́n “wà ní tẹmpili nígbà gbogbo” tí “wọ́n ń fi ìbùkún fún Ọlọrun”?—Luku 24:53.
5 Sọ Òtítọ́ Di Mímọ̀ Lójoojúmọ́: Lójoojúmọ́, ó yẹ kí á máa wá ọ̀nà láti sọ òtítọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Àǹfààní sábà máa ń ṣí sílẹ̀. O ha lè jẹ́rìí fún ẹni tí ó jókòó tì ọ́ nínú ọkọ̀ èrò bí? Tàbí, o ha lè kọ lẹ́tà sí ẹnì kan tí o kò bá nílé? O ha ti ronú nípa fífi ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé ìròyìn lọ òǹtàjà tàbí àwọn ènìyàn tí o ń bá pàdé lọ́jà nígbà tí o bá ń lọ rajà? Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ronú nípa ọ̀pọ̀ àǹfààní mìíràn tí ń ṣí sílẹ̀ fún ọ lójoojúmọ́ láti ṣàjọpín ìrètí rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Bí o bá sapá, tí o sì fi ìgbóyà hàn, Jehofa yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.—1 Tessa. 2:2.
6 Nítorí náà, bí a ti ń bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ó yẹ kí á bi ara wa léèrè pé, ‘Èmi yóò ha lo ìdánúṣe láti ṣàjọpín ìrètí mi pẹ̀lú ẹnì kan, bí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀ lónìí bí?’ Ṣàfarawé ẹ̀mí ìrònú Jesu, tí ó ṣàlàyé ìdí tí a fi rán òun wá sí orí ilẹ̀ ayé pé: “Emi gbọ́dọ̀ polongo ìhìnrere ìjọba Ọlọrun.” (Luku 4:43) Bí a bá fẹ́ẹ́ dà bí olùkọ́ wa, àwa yóò ṣe ohun kan náà.—Luku 6:40.