Jíjáramọ́ Iṣẹ́ Ìjẹ́rìí bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
1 Ìgbà ìkórè máa ń lárinrin. Ó tún jẹ́ àkókò iṣẹ́ àṣekára. Ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló wà láti fi kó irè oko jọ. Àwọn òṣìṣẹ́ kò sì jẹ́ fiṣẹ́ wọn ṣeré rárá.
2 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ lọ́nà àpèjúwe, ó fi “ìparí ètò àwọn nǹkan” wé ìgbà ìkórè. (Mát. 13:39) Ìparí ètò àwọn nǹkan là ń gbé, àkókò tó ṣẹ́ kù fún jíjẹ́rìí “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” sì kúrú jọjọ. (Mát. 24:14) Bí òpin náà ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, ó pọndandan pé ká jára mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Èé ṣe? Jésù ṣàlàyé pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.”—Mát. 9:37, 38; Róòmù 12:11.
3 Wà Lẹ́nu Rẹ̀ Ní Kánjúkánjú: Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ kíkọyọyọ, ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ péré ló ní láti parí iṣẹ́ táa yàn fún un. Ó fi ìjẹ́kánjúkánjú wàásù ọ̀hún, ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.”—Lúùkù 4:43.
4 Jésù gbin irú ìjẹ́kánjúkánjú kan náà sínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Máàkù 13:32-37) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé “ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n . . . ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:42) Wọn kò jẹ́ kí àwọn ìgbòkègbodò tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gba ipò iwájú nínú ìgbésí ayé wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kéré níye, wọ́n ṣàṣeyọrí nínú ìwàásù ìhìn rere náà “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kól. 1:23.
5 Ìdí tó túbọ̀ ṣe pàtàkì tilẹ̀ tún wà tó fi yẹ ká ní irú ìjẹ́kánjúkánjú bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, bí “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” (1 Pét. 4:7) Jèhófà ti yan ọjọ́ àti wákàtí tí ètò àwọn nǹkan yìí yóò wá sópin. (Mát. 24:36) Àkókò tó ṣẹ́ kù yìí sì ni a óò fi parí iṣẹ́ ìwàásù náà. Ìdí nìyẹn táa fi gbọ́dọ̀ fi kún ìsapá wa láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn sí i.
6 Báa bá jára mọ́ iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà bí òpin ti ń sún mọ́lé, ọkàn wa yóò balẹ̀ láti sọ fún Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fún un pé: ‘A ti parí iṣẹ́ tí ó fún wa láti ṣe.’—Jòh. 17:4.