ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “WÀÁSÙ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ, WÀ LẸ́NU RẸ̀ NÍ KÁNJÚKÁNJÚ.”—2 TÍM. 4:2.
Bí A Ṣe Lè Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú
Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú, ó sì ṣe pàtàkì pé ká ní ẹ̀mí yìí ká bàa lè la òpin ètò àwọn nǹkan yìí já. Tá a bá ń fi àwọn ìránnilétí tó wà nísàlẹ̀ yìí sílò, èyí á jẹ́ ká lè máa fi sọ́kàn pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú.
Máa gbàdúrà déédéé nípa Ìjọba náà.—Mát. 6:10.
Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ kó o lè dáàbò bo ọkàn rẹ.—Héb. 3:12.
Máa fi ọgbọ́n lo àkókò rẹ.—Éfé. 5:15, 16; Éfé. 1:10.
Jẹ́ kí ojú rẹ mú “ọ̀nà kan.” Má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tó wà nínú ayé yìí pín ọkàn rẹ níyà.—Mát. 6:22, 25; 2 Tím. 4:10.
Máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà kó o sì wà lójúfò bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ní ìmúṣẹ.—Máàkù 13:35-37.
Tá a bá ń fi sọ́kàn pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú, a ó lè máa kópa ní kíkún lẹ́nu iṣẹ́ tí kò ní pẹ́ parí yìí!—Jòh. 4:34, 35.