Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 27, 2014.
Bó ṣe wà nínú Númérì 21:5, kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ráhùn sí Ọlọ́run àti Mósè, ìkìlọ̀ wo nìyẹn sì jẹ́ fún wa? [Sept. 1, w99 8/15 ojú ìwé 26 sí 27]
Kí nìdí tí ìbínú Jèhófà fi ru sí Báláámù? (Núm. 22:20-22) [Sept. 8, w04 8/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3]
Kí ni Númérì 25:11 sọ nípa ìwà tí Fíníhásì hù, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? [Sept. 8, w04 8/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5]
Àwọn ọ̀nà wo ni Mósè gbà fi àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ta yọ lélẹ̀ fún wa lónìí? (Núm. 27:5, 15-18) [Sept. 15, w13 2/1 ojú ìwé 5]
Báwo ni Jóṣúà àti Kálébù ṣe fi ẹ̀rí tó lágbára hàn pé àwọn èèyàn aláìpé lè rìn ní ọ̀nà Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí láìka inúnibíni sí? (Núm. 32:12) [Sept. 22, w93 11/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 13]
Tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ẹ̀kọ́ wo làwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó lè rí kọ́ látinú ìgbọràn àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì? (Núm. 36:10-12) [Sept. 29, w08 2/15 ojú ìwé 4 sí 5 ìpínrọ̀ 10]
Kí ni ìyọrísí ìráhùn àti ọ̀rọ̀ tí kò dára táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ, kí la sì rí kọ́ nínú ìtàn yìí? (Diu. 1:26-28, 34, 35) [Oct. 6, w13 8/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 7]
Ohun méjì pàtàkì wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ìbùkún Jèhófà gbà, kí nǹkan sì lè dára fún wọn ní Ilẹ̀ Ìlérí? (Diu. 4:9) [Oct. 13, w06 6/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 15]
Lọ́nà wo ni aṣọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi gbó tí ẹsẹ̀ wọn kò sì wú nígbà tí wọ́n ń rìn láginjù? (Diu. 8:3, 4) [Oct. 20, w04 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1]
Báwo la ṣe lè fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Mósè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n “rọ̀ mọ́” Jèhófà sílò? (Diu. 13:4, 6-9) [Oct. 27, w02 10/15 ojú ìwé 16 sí 17 ìpínrọ̀ 14]