Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 27
Orin 5 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 15 ìpínrọ̀ 1 sí 10 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 11-13 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: “Bí A Ṣe Lè Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú.” Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn bí àkéde kan ṣe ń fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú lọni.
15 min: Múra Sílẹ̀ Dáadáa Kó O Lè Wàásù Lọ́nà Tó Fi Hàn Pé Ó Jẹ́ Kánjúkánjú. Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ August 15, 2014, ojú ìwé 14 àti 15, ìpínrọ̀ 14 sí 20. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìṣòro táwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín ń kojú tàbí àwọn ìbéèrè tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Báwo la ṣe lè sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó bẹ́ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Ní kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì tàbí tọkọtaya kan ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn àbá yìí sílò tá a bá ń múra àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó lè fa àwọn èèyàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Àwọn tó fẹ́ ṣe àṣefihàn náà lè pinnu ìwé tí wọ́n máa fi lọ onílé.
Orin 95 àti Àdúrà