ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/04 ojú ìwé 1
  • Má Ṣe Fi Iṣẹ́ Ìwàásù Falẹ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Fi Iṣẹ́ Ìwàásù Falẹ̀!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Pa Òye Ìjẹ́kánjúkánjú Rẹ Mọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Bí A Ṣe Lè Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Jíjáramọ́ Iṣẹ́ Ìjẹ́rìí bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 11/04 ojú ìwé 1

Má Ṣe Fi Iṣẹ́ Ìwàásù Falẹ̀!

1 Jésù mọ̀ pé àkókò tó ṣẹ́ kù fún òun lórí ilẹ̀ ayé láti fi ṣe iṣẹ́ Baba òun kéré gan-an. (Jòh. 9:4) Nípa bẹ́ẹ̀, kò fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ falẹ̀ rárá, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí àwọn náà má ṣe fi iṣẹ́ ìwàásù falẹ̀. (Lúùkù 4:42-44; 8:1; 10:2-4) Àwọn ohun amáyédẹrùn kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lójú rẹ̀. (Mát. 8:20) Ìdí nìyẹn tó fi lè parí iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún un.—Jòh. 17:4.

2 Àkókò Tó Ṣẹ́ Kù Kéré Gan-an: Àkókò tó ṣẹ́ kù fún àwa náà láti fi wàásù ìhìn rere ní “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” kò pọ̀ mọ́. (Mát. 24:14) Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé gan-an. Láìpẹ́, “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa . . . yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.” (2 Tẹs. 1:6-9) Òjijì ni ìdájọ́ yẹn yóò dé. (Lúùkù 21:34, 35; 1 Tẹs. 5:2, 3) Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ pé inú ewu làwọn wà. Nítorí náà, ojúṣe wa ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá ojú rere Jèhófà nígbà tí àkókò ṣì wà.—Sef. 2:2, 3.

3 Ẹ Jẹ́ Ká Sa Gbogbo Ipá Wa: Níwọ̀n bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti mọ̀ pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù,” iṣẹ́ ìwàásù ni wọ́n fi ṣáájú nígbèésí ayé wọn. (1 Kọ́r. 7:29-31; Mát. 6:33) Àwọn kan kọ àǹfààní tí wọ́n ní láti di ọlọ́rọ̀ tàbí láti lépa àwọn ohun ti ara mìíràn kí wọ́n lè ráyè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn dáadáa. (Máàkù 10:29, 30) Àwọn mìíràn ṣì ń ní ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò nǹkan kò rọrùn fún wọn. (1 Kọ́r. 15:58) Púpọ̀ nínú wa ti ń polongo ìhìn rere bọ̀ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn láìkáàárẹ̀. (Héb. 10:23) Jèhófà mọyì gbogbo bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń fi nǹkan du ara wọn yìí nítorí kí wọ́n lè ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn.—Héb. 6:10.

4 Bá a bá fi ìjọsìn Jèhófà, èyí tó kan iṣẹ́ ìwàásù, ṣáájú nígbèésí ayé wa, a ó lè máa fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn. Ṣíṣe èyí ò ní jẹ́ kí ayé tí Sátánì ń ṣàkóso pín ọkàn wa níyà, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti máa hùwà mímọ́. (2 Pét. 3:11-14) Dájúdájú, tá ò bá fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa falẹ̀, àwa àtàwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ wa á lè rí ìgbàlà.—1 Tím. 4:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́