Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ Oct. 15
“Àwọn èèyàn kan rò pé béèyàn bá ṣe lówó tó ló ṣe máa ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó. Ǹjẹ́ o rò pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí ọkùnrin kan tó ní ọrọ̀ gan-an kọ. [Ka Oníwàásù 5:10.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ lọ.”
Ile Ìṣọ́ Nov. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fọkàn tán àwọn aṣáájú ayé nítorí pé wọn ò lè yanjú àwọn ìṣòro òde òní. Ǹjẹ́ o rò pé ẹnì kankan wà tó lè mú àsọtẹ́lẹ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí ṣẹ? [Ka Sáàmù 72:7, 12, 16. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ẹni tó jẹ́ aṣáájú tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ yìí àti ohun tó máa ṣe fún aráyé.”
Jí! Nov. 8
“Ọ̀pọ̀ èèyàn rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa tọ́mọ láti kékeré. Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 22:6.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí ṣàlàyé àwọn ohun táwọn òbí lè ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè dàgbà di ẹni tó ní láárí àti olùbẹ̀rù Ọlọ́run.”
“Ó yẹ káwọn òbí tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà kí àwọn ọmọ bàa lè borí gbogbo pákáǹleke tí wọ́n ń rí lónìí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Éfésù 6:4.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí ìbáwí túmọ̀ sí gan-an. Ó tún sọ báwọn òbí ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà kí wọ́n sì máa bá wọn wí láìsí pé wọ́n ń ba àwọn ọmọ nínú jẹ́.”