Ní Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Tí Wàá Máa Lépa Láti Fi Yin Ẹlẹ́dàá Rẹ Lógo
1. (a) Báwo ni ìgbésí ayé ẹni ṣe lè nítumọ̀? (b) Kí lohun tí Nóà àti Mósè ń lépa?
1 Kí ìgbésí ayé ẹni tó lè nítumọ̀, èèyàn gbọ́dọ̀ ní ohun kan tó ń lépa. Bíbélì fún wa ní àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó ní ohun tí wọ́n ń lé. Nóà fi nǹkan bí àádọ́ta ọdún ṣiṣẹ́ láti kan ọkọ̀ áàkì. Kí lohun tí Nóà ń lépa? Ó ń wá “ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.” Wòlíì Mósè “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.”—Héb. 11:7, 26.
2. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
2 Bẹ́ẹ̀ ni o, kò sígbà kan nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò ní ohun rere kan tí wọ́n ń lé, ọwọ́ wọn sì máa ń tẹ àwọn nǹkan ọ̀hún, tí èyí sì ń gbé Ọlọ́run ga. Báwo la ṣe lè ní àwọn nǹkan tẹ̀mí tí a óò máa lépa láti fi yin Ẹlẹ́dàá wa lógo lónìí? Àwọn nǹkan wo la lè gbé ka iwájú ara wa, kí sì làwọn ohun tá a lè ṣe kí ọwọ́ wa lè tẹ̀ wọ́n?
3. Báwo ni àwọn nǹkan tẹ̀mí tí à ń lépa ṣe yàtọ̀ sáwọn nǹkan táráyé ń lé?
3 Ẹ̀mí Tó Tọ́ Ṣe Pàtàkì: Àwọn nǹkan tẹ̀mí tí à ń lépa yàtọ̀ sáwọn nǹkan táráyé ń lé. Ohun tó ń mú káwọn èèyàn ayé máa lé ọ̀pọ̀ lára ohun tí wọ́n ń lé ni pé wọ́n fẹ́ di ọlọ́rọ̀ lọ́nàkọnà, wọ́n sì tún ń wá ipò àti agbára lójú méjèèjì. Àmọ́, àwọn ohun téèyàn ń lépa tó máa gbé Jèhófà Ọlọ́run ga ni àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa sí Ọlọ́run àti ìgbòkègbodò Ìjọba rẹ̀. (Mát. 6:33) Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti ọmọnìkejì ẹni ló ń jẹ́ ká máa lé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, èyí á sì jẹ́ ká ní ìfọkànsìn Ọlọ́run.—Mát. 22:37-39; 1 Tím. 4:7.
4, 5. Àwọn nǹkan tẹ̀mí wo la lè máa lépa?
4 Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Tá A Lè Máa Lépa: O lè pinnu pé wàá mú kí ìmọ̀ rẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i. Òwe 2:1-5 gbà wá nímọ̀ràn pé ká wá “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” Bó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà á máa wà lọ́kàn rẹ nígbà gbogbo. Wàá sì lè túbọ̀ máa ṣe ìpinnu tó tọ́ nígbà tí ọ̀ràn pàtàkì bá jẹ yọ.
5 Àwọn akéde kan pinnu pé àwọn á máa lo iye wákàtí kan pàtó nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ṣé ìwọ náà lè pinnu pé wàá túbọ̀ di ọ̀jáfáfá olùkọ́ nígbà tó o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Àwọn akéde kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ pinnu pé lọ́dọọdún, àwọn á máa ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní àkókò ìsinmi. Ǹjẹ́ o máa ń ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí!? Àwọn kan pinnu pé bí ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan bá ṣe ń dé gbàrà làwọn á máa kà á.
6. Kí làwọn ohun tá a lè ṣe tó lè jẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ àwọn ohun tí à ń lépa?
6 Ṣíṣe Àkọsílẹ̀ Àwọn Ohun Tí A Fẹ́ Máa Lépa Lè Jẹ́ Kí Ọwọ́ Wa Tẹ̀ Wọ́n: Sólómọ́nì sọ pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù, àwọn ọ̀rọ̀ yíyẹ ní agbára láti fúnni ní ìtọ́sọ́nà nígbèésí ayé ẹni. (Oníw. 12:11) Tá a bá kọ àwọn ọ̀rọ̀ yíyẹ náà sínú ìwé, a óò máa rántí wọn nígbà gbogbo. (Diu. 17:18) Nítorí náà, a lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tá a fẹ́ máa lé àti ọ̀nà tá a fẹ́ gbé e gbà tí ọwọ́ wa yóò fi tẹ̀ wọ́n, ká sì tún kọ àwọn ìṣòro tá a rò pé ó lè yọjú àtàwọn nǹkan tá a lè ṣe láti yanjú wọn.
7. Báwo ni ọwọ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan ṣe tẹ ohun tó ń lépa?
7 Wo àpẹẹrẹ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan ní ìpínlẹ̀ àdádó kan. Òjijì ni ìyàwó arákùnrin tó ti ń sìn tipẹ́ yìí kú. Àmọ́, lẹ́yìn tí ọkàn rẹ̀ ti fúyẹ́ díẹ̀, ó pinnu pé òun á túbọ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà òun, ó wá ṣètò àwọn ohun kan tó fẹ́ máa lé. Ó kọ àwọn ohun tó fẹ́ ṣe sínú ìwé, lẹ́yìn náà ó fi ọ̀ràn yìí sínú àdúrà, ó sì pinnu láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun mẹ́ta níparí oṣù yẹn. Ojoojúmọ́ ló máa ń yẹ ìgbòkègbodò rẹ̀ wò, ó sì máa ń wo bí òun ṣe tẹ̀ síwájú sí ní ọjọ́ mẹ́wàá-mẹ́wàá. Ǹjẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tẹ nǹkan tó ní lọ́kàn láti ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun mẹ́rin ló ròyìn, ayọ̀ ńlá lèyí sì jẹ́ fún un!
8. Kí ló yẹ ká pinnu pé a óò ṣe?
8 Àmọ́ ṣá o, láwọn ìgbà mìíràn, ipò nǹkan lè máà jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti lépa àwọn nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, àìsàn tàbí ojúṣe wa nínú ìdílé lè máà jẹ́ kí agbára wa gbé àwọn nǹkan kan. Síbẹ̀, ó ṣì ṣeé ṣe fún wa láti máa ‘bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.’ (Oníw. 12:13) Tá a bá láwọn nǹkan tẹ̀mí tá à ń lé, á ràn wá lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ní àwọn nǹkan tẹ̀mí tá à ń lépa láti fi yin Ẹlẹ́dàá wa lógo.