ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/04 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 10/04 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 25, 2004. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ September 6 sí October 25, 2004. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Báwo la ṣe lè mú kí ọ̀rọ̀ wa gbéni ró nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀ka kan lára ìgbòkègbodò Kristẹni? [be-YR ojú ìwé 203 ìpínrọ̀ 3 àti 4]

2. Kí ni sísọ̀rọ̀ lásọtúnsọ túmọ̀ sí, kí nìdí tó sì fi ṣe pàtàkì? [be-YR ojú ìwé 206 ìpínrọ̀ 1 sí 4]

3. Báwo la ṣe lè máa tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ wa? [be-YR ojú ìwé 210 ìpínrọ̀ 1 sí 5, àpótí]

4. Báwo la ṣe lè mọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó wà nínú ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n yàn fún wa? [be-YR ojú ìwé 212 ìpínrọ̀ 1 sí 4]

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra kí kókó ọ̀rọ̀ wa má pọ̀ jù? [be-YR ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 2 sí 4]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Àwọn ohun wo ló ń ṣẹlẹ̀ ṣáájú Ìkún Omi tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ló mú kó ṣòro fún àwọn èèyàn láti gbà gbọ́ pé gbogbo ohun tó wà láyìíká wọn máa dópin? [w02-YR 3/1 ojú ìwé 5 àti 6]

7. Kí nìdí tó fi gbàfiyèsí pé àwọn èèyàn ìgbà ayé Jésù kò pè é ní “Oníwòsàn” bí kò ṣe “Olùkọ́”? (Lúùkù 3:12; 7:40) [w02-YR 5/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 6]

8. Báwo ni Òwe 11:24, 25 ṣe fi hàn pé kíkópa kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe pàtàkì gan-an? [w02-YR 7/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2 sí 4]

9. Ọ̀ràn pàtàkì wo ni ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì dá sílẹ̀, àwọn nǹkan wo sì ni ìṣọ̀tẹ̀ náà ti yọrí sí? (Jẹ́n. 3:1-6) [w02-YR 10/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 1, 3 àti 4]

10. Ẹ̀kọ́ wo làwọn tó ń sún ìgbà tí wọ́n máa ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run síwájú lè rí kọ́ látinú ìtàn Nikodémù? [w02-YR 2/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 4 àti 6]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló sọ fún Báláámù pé kó bá àwọn ọkùnrin Bálákì lọ, kí nìdí tí Jèhófà fi bínú nígbà tí Báláámù bá wọn lọ? (Núm. 22:20-22)

12. Ǹjẹ́ ọkọ obìnrin Kristẹni kan lè fagi lé ẹ̀jẹ́ aya rẹ̀? (Núm. 30:6-8)

13. Kí ni ‘àwọn ìlú ńlá ìsádi’ dúró fún lónìí? (Núm. 35:6) [w95-YR 11/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 8]

14. Ṣé bí àṣẹ tó wà nínú Diutarónómì 6:6-9, tó sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ‘so òfin Ọlọ́run mọ́ ọwọ́ àti mọ́ orí gẹ́gẹ́ bí ọ̀já ìgbàjú,’ ṣe wà gẹ́lẹ́ ló ṣe yẹ ká lóye rẹ̀ ni àbí ńṣe la lo ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ?

15. Ǹjẹ́ ohun tí gbólóhùn náà “aṣọ àlàbora rẹ kò gbó” túmọ̀ sí ni pé ńṣe là ń pààrọ̀ aṣọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí tuntun? (Diu. 8:4)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́