Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tí a ó fi lọni ní October: Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó fi lọni jálẹ̀ gbogbo oṣù yìí. Níbi tí wọ́n bá ti fìfẹ́ hàn, kí a fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí a sì sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la ó fi lọni. Bí ẹni tó ò ń wàásù fún bá sọ pé òun ò lọ́mọ, fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Gbìyànjú láti fi ìwé pẹlẹbẹ yìí bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì, Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?
◼ “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2005” ló wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Ẹ tọ́jú rẹ̀ kí ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún 2005.
◼ Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí kì í fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò kí a máa ṣèfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi fọ́ọ̀mù tí a fi ń béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ nílò fún oṣù kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti gba ìwé tó nílò lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tá a máa ń béèrè fún lọ́nà àkànṣe o.
◼ Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
Ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ ọdún 2003—Gẹ̀ẹ́sì
Ìwé Watchtower Publications Index 1992-2002 —Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà