ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/04 ojú ìwé 3-6
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2005

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2005
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ìtọ́ni
  • ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 10/04 ojú ìwé 3-6

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2005

Ìtọ́ni

Bí a ó ṣe máa darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 2005 la ṣètò sísàlẹ̀ yìí.

ÀWỌN ÌWÉ TÁ A TI YANṢẸ́ FÚNNI: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run [be-YR], Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé [fy-YR] àti “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò,” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lápá ẹ̀yìn Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

Kí a bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ yìí LÁKÒÓKÒ. A ó fi orin, àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀ bẹ̀rẹ̀, a ó sì lo ìlànà tó tẹ̀ lé e yìí láti fi darí rẹ̀:

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn tàbí alàgbà mìíràn tó tóótun yóò sọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan tí a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Láwọn ìjọ tí alàgbà ò bá ti pọ̀ tó, wọ́n lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun.) Kí olùbánisọ̀rọ̀ fi ọ̀rọ̀ inú àpótí tó wà lójú ìwé tá a ti yanṣẹ́ fún un kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àyàfi bá a bá sọ pé kó má ṣe sọ̀rọ̀ lórí àpótí náà. Àmọ́, kò ní sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdánrawò tó wà níbẹ̀. Àwọn ìdánrawò náà wà fún ìlò ẹnì kọ̀ọ̀kan àti fún ìlò alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, kó lè máa fi gba àwọn ará nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun ni yóò bójú tó iṣẹ́ yìí, a ó sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́ tàbí ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí ó ṣe iṣẹ́ yìí bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá láìsí pé ó ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwùjọ. Kì í ṣe pé kí olùbánisọ̀rọ̀ kàn sọ̀rọ̀ lórí ibi tí a yàn fún un nìkan, ṣùgbọ́n ní pàtàkì, ó yẹ kó sọ ìwúlò ohun tó ń sọ̀rọ̀ lé lórí, kó sì tẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ni kó lò. A retí pé káwọn arákùnrin tá a bá yan iṣẹ́ yìí fún rí i dájú pé àwọn kò kọjá àkókò tí a ní kí wọ́n lò. A lè fún wọn nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́ bó bá yẹ.

ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTINÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Fún ìṣẹ́jú mẹ́fà àkọ́kọ́, kí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun sọ bí a ṣe lè fi ohun tó wà nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ náà sílò. Ó lè sọ̀rọ̀ lórí apá èyíkéyìí lára Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ náà. Kì í wulẹ̀ ṣe pé kó kàn ṣe àkópọ̀ ibi tá a ní kó kà o. Ète iṣẹ́ yìí ni láti jẹ́ kí àwùjọ lóye ìdí tí ọ̀rọ̀ tó ń sọ fi wúlò fún wọn àti ọ̀nà tó gbà wúlò fún wọn. Kí olùbánisọ̀rọ̀ rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tí òun ń sọ kò kọjá ìṣẹ́jú mẹ́fà. Kí ó wá lo ìṣẹ́jú mẹ́rin tó kù láti fi gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwùjọ pẹ̀lú. Kí ó sọ pé kí àwùjọ sọ ọ̀rọ̀ ṣókí (ní ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀) lórí ohun tí wọ́n gbádùn nínú Bíbélì kíkà náà àtàwọn àǹfààní inú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a yàn sí kíláàsì mìíràn máa lọ síbẹ̀.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KEJÌ: Ìṣẹ́jú mẹ́rin. Arákùnrin ni yóò bójú tó ìwé kíkà yìí. Bíbélì ni a óò máa kà lọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́, lẹ́ẹ̀kan lóṣù, a óò fa iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí yọ látinú Ilé Ìṣọ́. Kí akẹ́kọ̀ọ́ ka ibi tá a yàn fún un láìsí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ àsọparí. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ibi tí a óò ṣètò fún kíkà lè gùn tàbí kó kúrú, àmọ́ ìwé kíkà náà kò ní gbà ju ìṣẹ́jú mẹ́rin lọ tàbí kó dín díẹ̀. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ tó máa yàn fún akẹ́kọ̀ọ́ kan kó tó yàn án fún un, kó sì rí i pé ọjọ́ orí àti òye akẹ́kọ̀ọ́ náà kò kéré sí iṣẹ́ náà. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ ni bó ṣe máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kàwé dáadáa nípa ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí: kíkàwé lọ́nà tó yéni yékéyéké, jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ni lẹ́nu, títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dídánudúró bó ṣe yẹ àti sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dáni.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸTA: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Arábìnrin ni a ó yan iṣẹ́ yìí fún. A ó yan ìgbékalẹ̀ kan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a fún ní iṣẹ́ yìí tàbí kí wọ́n fúnra wọn yan ọ̀kan lára ìgbékalẹ̀ tá a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 82 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a yàn fún un, kó sì mú un bá ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣiṣẹ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ ìjọ mu, èyí tí àwọn ará á lè lò. Bí a kò bá tọ́ka sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kankan tá a gbé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí kà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ olóòótọ́ àti olóye pèsè láti fi kó iṣẹ́ rẹ̀ jọ. Àwọn iṣẹ́ tá a tọ́ka ìwé tá a gbé wọn kà ni kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ ni ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, bó ṣe mú kí onílé ronú lórí Ìwé Mímọ́ àti bó ṣe mú kó lóye àwọn kókó pàtàkì inú iṣẹ́ rẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá mọ̀wéé kà ni ká yan iṣẹ́ yìí fún. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yan olùrànlọ́wọ́ kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸRIN: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Kí akẹ́kọ̀ọ́ tá a yan iṣẹ́ yìí fún kó iṣẹ́ rẹ̀ jọ láti ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a yàn fún un. Bí a kò bá tọ́ka sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kankan tí a gbé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí kà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ olóòótọ́ àti olóye pèsè láti fi kó iṣẹ́ rẹ̀ jọ. Bí a bá yàn án fún arákùnrin, kí ó sọ ọ́ bí àsọyé nípa dídarí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó bá jẹ́ arábìnrin ni yóò bójú tó o, kí ó tẹ̀ lé ìtọ́ni tí a pèsè fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè gbé Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin fún arákùnrin nígbàkigbà tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé, bí a bá sàmì ìràwọ̀ (*) síwájú ẹṣin ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, àwọn arákùnrin ni ká yàn án fún kí wọ́n lè sọ ọ́ bí àsọyé.

ÀKÓKÒ: Kí akẹ́kọ̀ọ́ kankan má ṣe kọjá àkókò, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà má sì ṣe sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Kí a fi ọgbọ́n dá Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì, Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta àti Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin dúró bí àkókò bá ti pé. Bí àwọn arákùnrin tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ níbẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́, ìyẹn ọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní tàbí àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà bá kọjá àkókò, kí a fún wọn nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́. Kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ rí i dájú pé àwọn kò kọjá àkókò tá a fún wọn. Ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta la ó fi bójú tó ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ yìí látòkèdélẹ̀, láìsí orin àti àdúrà.

ÌMỌ̀RÀN: Ìṣẹ́jú kan. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ kò ní lò ju ìṣẹ́jú kan lọ lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan láti fi sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró lórí ohun kan nínú iṣẹ́ náà tó kíyè sí pé ó dára gan-an. Kì í ṣe pé kó kàn sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ pé “o ṣe dáadáa,” kàkà bẹ́ẹ̀, kó ṣàlàyé àwọn ìdí pàtó tí ohun tó kíyè sí nínú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà fi gbéṣẹ́. Bó bá kíyè sí i pé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan kù síbì kan, ó tún lè fún un nímọ̀ràn tí ń gbéni ró lẹ́yìn ìpàdé tàbí nígbà mìíràn.

OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN: Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà lè yan alàgbà kan tó tóótun, bó bá wà, láfikún sí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Bí àwọn alàgbà bá pọ̀ nínú ìjọ, a lè máa lo alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó tóótun lọ́dọọdún láti ṣe iṣẹ́ yìí. Ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn ni láti máa fún àwọn arákùnrin tó ń bójú tó Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní àti kókó pàtàkì látinú Bíbélì nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kó máa fúnni nímọ̀ràn ní gbogbo ìgbà táwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá bójú tó àwọn iṣẹ́ yìí. Ètò yìí la ó tẹ̀ lé lọ́dún 2005, ó sì lè yí padà bó bá yá.

ÌWÉ ÌMỌ̀RÀN Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Èyí wà nínú ìwé tá à ń lò fún Ilé Ẹ̀kọ́.

ÀTÚNYẸ̀WÒ ALÁFẸNUSỌ: Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Ní oṣù méjì-méjì, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò máa darí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ṣáájú èyí, a óò bójú tó ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà, bá a ṣe ṣàlàyé lókè. A óò gbé àtúnyẹ̀wò yìí ka àwọn ohun tá a jíròrò nínú ilé ẹ̀kọ́ láàárín oṣù méjì tó ṣáájú, títí kan ti ọ̀sẹ̀ àtúnyẹ̀wò náà. Bí ìjọ yín bá ń lọ sí àpéjọ àyíká tàbí tẹ́ ẹ ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká ní ọ̀sẹ̀ àtúnyẹ̀wò, ẹ tẹ̀ lé ìtọ́ni tá a ṣe nípa ọ̀nà tí a ó gbà darí ilé ẹ̀kọ́ lọ́sẹ̀ yẹn. Ẹ óò rí ìtọ́ni yìí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2003, ojú ìwé 6.

ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ

Jan. 3 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 16 sí 20 Orin 6

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Àlàyé Ọ̀rọ̀ Rẹ Yéni (be-YR ojú ìwé 226 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 227 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Bẹ̀rù Ọlọ́run Tòótọ́ (be-YR ojú ìwé 272 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 2: Jóṣúà 16:1-17:4

No. 3: Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ìbálòpọ̀ (fy-YR ojú ìwé 92 sí 94 ìpínrọ̀ 8 sí 13)

No. 4: Ṣé Jíjẹ́ Ọlọ́rọ̀ Tàbí Òtòṣì Ló Ń Fi Hàn Pé Èèyàn Ń Ṣèfẹ́ Ọlọ́run Lónìí?

Jan. 10 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 21 sí 24 Orin 100

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣàlàyé Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Kò Bá Yé Àwùjọ (be-YR ojú ìwé 227 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 228 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀ (be-YR ojú ìwé 273 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 274 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: Jóṣúà 23:1-13

No. 3: Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Yan Ọ̀rẹ́ Gidi (fy-YR ojú ìwé 95 àti 96 ìpínrọ̀ 14 sí 18)

No. 4: Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Ká Máa Jọ́sìn Jésù?

Jan. 17 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 1 sí 4 Orin 97

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣe Àlàyé Tó Bá Yẹ (be-YR ojú ìwé 228 ìpínrọ̀ 2 àti 3)

No. 1: Ẹni Tó Ń Jẹ́ Orúkọ Yẹn (be-YR ojú ìwé 274 ìpínrọ̀ 2 sí 5)

No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 2:1-10

No. 3: Yíyan Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé fún Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 97 sí 102 ìpínrọ̀ 19 sí 27)

No. 4: Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àwọn Fídíò Orin Tó Lè Pani Lára?

Jan. 24 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 5 sí 7 Orin 47

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ipò Ọkàn Onítọ̀hún Ṣe Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 228 ìpínrọ̀ 4 sí 6)

No. 1: Orúkọ Ọlọ́run,“Ilé Gogoro Tí Ó Lágbára” (be-YR ojú ìwé 274 ìpínrọ̀ 6 títí dé àkọlé tó wà ní ojú ìwé 275)

No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 6:25-35

No. 3: Báwo Ló Ṣe Yẹ Kí Bíbélì Nípa Lórí Òmìnira Tá A Ní Láti Ṣèpinnu?

No. 4: aÌmọ̀ràn Látinú Ìwé Mímọ́ fún Ìdílé Àwọn Òbí Anìkàntọ́mọ (fy-YR ojú ìwé 103 sí 105 ìpínrọ̀ 1 sí 8)

Jan. 31 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 8 sí 10 Orin 174

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ (be-YR ojú ìwé 230 ìpínrọ̀ 1 sí 6)

No. 1: Jíjẹ́rìí Jésù (be-YR àkọlé tó wà ní ojú ìwé 275 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 2: w03-YR 1/15 ojú ìwé 19 àti 20 ìpínrọ̀ 16 sí 18

No. 3: Ìṣòro Gbígbọ́ Bùkátà Gẹ́gẹ́ Bí Òbí Anìkàntọ́mọ (fy-YR ojú ìwé 105 sí 107 ìpínrọ̀ 9 sí 12)

No. 4: Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì Kò Mọ sí Kíkó Ohun Ìní Jọ Nìkan

Feb. 7 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 11 sí 14 Orin 209

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣe Ìwádìí Kí Àwùjọ Lè Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ (be-YR ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Títẹnu Mọ́ Ipa Tí Jésù Ń Kó Bí Olùràpadà (be-YR ojú ìwé 276 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 12:1-15

No. 3: Ohun Tó Mú Káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Wà Níṣọ̀kan

No. 4: bPípèsè Ìbáwí Nínú Ìdílé Òbí Anìkàntọ́mọ (fy-YR ojú ìwé 107 sí 109 ìpínrọ̀ 13 sí 17)

Feb. 14 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 15 sí 18 Orin 105

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣàlàyé Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 4 àti 5)

No. 1: Títẹnu Mọ́ Ipa Tí Jésù Ń Kó Bí Àlùfáà Àgbà àti Orí Ìjọ (be-YR ojú ìwé 277 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 15:9-20

No. 3: Bíborí Ìṣòro Ìdánìkanwà (fy-YR ojú ìwé 110 sí 113 ìpínrọ̀ 18 sí 22)

No. 4: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Yàgò fún Gbogbo Ìbẹ́mìí lò? (td–YR 13D)

Feb. 21 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 19 sí 21 Orin 53

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣàlàyé Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 232 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Títẹnu Mọ́ Ipa Tí Jésù Ń Kó Bí Ọba Tí Ń Ṣàkóso (be-YR ojú ìwé 277 ìpínrọ̀ 3 àti 4)

No. 2: w03-YR 2/1 ojú ìwé 17 àti 18 ìpínrọ̀ 18 sí 21

No. 3: Bí A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Ìdílé Àwọn Òbí Anìkàntọ́mọ (fy-YR ojú ìwé 113 sí 115 ìpínrọ̀ 23 sí 27)

No. 4: Kí Ni Díẹ̀ Lára “Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”? (1 Kọ́r. 2:10)

Feb. 28 Bíbélì kíkà: Rúùtù 1 sí 4 Orin 120

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣe Àlàyé Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 232 ìpínrọ̀ 2 sí 4)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Mar. 7 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 1 sí 4 Orin 221

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ Ohun Tó Máa Ṣe Àwùjọ Láǹfààní (be-YR ojú ìwé 232 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 233 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Fífi Kristi Ṣe Ìpìlẹ̀ (be-YR ojú ìwé 278 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 2: 1 Sámúẹ́lì 2:1-11

No. 3: Ìdí Tó Fi Dára Láti Máa Fi Ìlànà Ọlọ́run Sílò Nígbà Téèyàn Bá Ń Ṣàìsàn (fy-YR ojú ìwé 116 sí 119 ìpínrọ̀ 1 sí 9)

No. 4: Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì í Fi Í Wo Ìràwọ̀

Mar. 14 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 5 sí 9 Orin 151

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ Jáde Láti Ibi Tí A Ti Yanṣẹ́ fún Ọ (be-YR ojú ìwé 234 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 235 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Ìhìn Rere Ìjọba Yìí (be-YR ojú ìwé 279 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 2: 1 Sámúẹ́lì 5:1-12

No. 3: Àǹfààní Tó Wà Nínú Níní Ẹ̀mí Tó Dára Nígbà Téèyàn Bá Ń Ṣàìsàn (fy-YR ojú ìwé 120 àti 121 ìpínrọ̀ 10 sí 13)

No. 4: Bí A Ṣe Lè Mú Kí Àjọṣe Àwa àti Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I

Mar. 21 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 10 sí 13 Orin 166

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 236 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 1: Ṣíṣàlàyé Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Jẹ́ (be-YR ojú ìwé 280 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 2: 1 Sámúẹ́lì 10:1-12

No. 3: Báwo Ló Ṣe Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Hùwà sí Àwọn Èèyàn Wọn Tí Kì í Ṣe Ẹlẹ́rìí?

No. 4: cMọ Ohun Tó Jẹ́ Àkọ́múṣe, Kó O sì Jẹ́ Káwọn Ọmọ Mọ Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Tí Ẹnì Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Ṣàìsàn (fy-YR ojú ìwé 122 àti 123 ìpínrọ̀ 14 sí 18)

Mar. 28 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 14 àti 15 Orin 172

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìbéèrè Láti Fi Nasẹ̀ Àwọn Kókó Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 237 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

No. 1: Ṣíṣàlàyé Bí Ìjọba Ọlọ́run Ṣe Kan Ìgbésí Ayé Wa (be-YR ojú ìwé 281 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 2: w03-YR 3/15 ojú ìwé 19 àti 20 ìpínrọ̀ 17 sí 21

No. 3: Ìdí Táwọn Kristẹni Fi Ń Sanwó Orí

No. 4: dOjú Tó Yẹ Ká Fi Wo Ìtọ́jú Ìṣègùn (fy-YR ojú ìwé 124 sí 127 ìpínrọ̀ 19 sí 23)

Apr. 4 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 16 sí 18 Orin 27

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìbéèrè Láti Ṣàlàyé Kókó Kan (be-YR ojú ìwé 237 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Ìdí Tí Ẹ̀kọ́ Ìwé Fi Ṣe Pàtàkì Fáwọn Kristẹni (w03-YR 3/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5)

No. 2: 1 Sámúẹ́lì 17:41-51

No. 3: Báwo Ni Aya Tó Jẹ́ Onígbàgbọ́ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Jọba Láàárín Òun àti Ọkọ Rẹ̀ Tó Ń Ṣe Ìsìn Tó Yàtọ̀? (fy-YR ojú ìwé 128 sí 132 ìpínrọ̀ 1 sí 9)

No. 4: Ríronú Jinlẹ̀ Lórí Àbájáde Ìwà Wa Lè Jẹ́ Ká Nífẹ̀ẹ́ Ohun Rere Ká sì Kórìíra Ohun Búburú

Apr. 11 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 19 sí 22 Orin 73

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìbéèrè Láti Fi Ohun Tó Wà Lọ́kàn Olùgbọ́ Hàn (be-YR ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 3 sí 5)

No. 1: Bí Àwọn Ọ̀dọ́ Ṣe Lè Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí (w03-YR 4/1 ojú ìwé 8 sí 10)

No. 2: 1 Sámúẹ́lì 20:24-34

No. 3: Ìdí Tí Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Fi Máa Ń Wuni

No. 4: eBáwo Ni Ọkọ Tó Jẹ́ Onígbàgbọ́ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Jọba Láàárín Òun àti Aya Rẹ̀ Tó Ń Ṣe Ìsìn Tó Yàtọ̀? (fy-YR ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 10 àti 11)

Apr. 18 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 23 sí 25 Orin 61

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìbéèrè Láti Fi Tẹ Ọ̀rọ̀ Rẹ Mọ́ni Lọ́kàn (be-YR ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 239 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà (w03-YR 11/1 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: w03-YR 5/1 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 11 sí 14

No. 3: Fífi Ìwé Mímọ́ Tọ́ Àwọn Ọmọ Nínú Ìdílé Tí Ìsìn Ọkọ àti Aya Ti Yàtọ̀ (fy-YR ojú ìwé 133 àti 134 ìpínrọ̀ 12 sí 15)

No. 4: Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Bá Ábúráhámù Dá Májẹ̀mú

Apr. 25 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 26 sí 31 Orin 217

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìbéèrè Láti Fi Tú Èrò Búburú Fó (be-YR ojú ìwé 239 ìpínrọ̀ 2 sí 4)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

May 2 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 1 sí 3 Orin 91

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Àfiwé Tààrà àti Àfiwé Ẹlẹ́lọ̀ọ́ (be-YR ojú ìwé 240 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 241 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Kì Í Ṣe Tìtorí Àtiríṣẹ́ Nìkan Lèèyàn Ṣe Ń Kàwé (w03-YR 3/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 5)

No. 2: 2 Sámúẹ́lì 2:1-11

No. 3: Wíwà Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Òbí Tí Ìsìn Wọn Yàtọ̀ (fy-YR ojú ìwé 134 àti 135 ìpínrọ̀ 16 sí 19)

No. 4: Ọ̀pọ̀ Àǹfààní Ló Wà Nínú Jíjẹ́ Olóòótọ́ Èèyàn

May 9 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 4 sí 8 Orin 183

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Àpẹẹrẹ (be-YR ojú ìwé 241 ìpínrọ̀ 2 sí 4)

No. 1: Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èwe Gidi Gan-an (w03-YR 4/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: 2 Sámúẹ́lì 5:1-12

No. 3: Kí Làwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Májẹ̀mú Òfin?

No. 4: fÌṣòro Tó Wà Nínú Kéèyàn Lọ Fẹ́ Ọkọ Tàbí Aya Mìíràn Dípò Ti Tẹ́lẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 136 sí 139 ìpínrọ̀ 20 sí 25)

May 16 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 9 sí 12 Orin 66

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Àpẹẹrẹ Inú Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 242 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

No. 1: Ǹjẹ́ Jèhófà Ń Kíyè sí Ohun Tí Ò Ń Ṣe? (w03-YR 5/1 ojú ìwé 28 sí 31)

No. 2: 2 Sámúẹ́lì 9:1-13

No. 3: Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìlépa Ọrọ̀ Àlùmọ́nì Pín Ìdílé Rẹ sí Méjì (fy-YR ojú ìwé 140 àti 141 ìpínrọ̀ 26 sí 28)

No. 4: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yè—Lọ́nà Wo? (Héb. 4:12)

May 23 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 13 sí 15 Orin 103

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ǹjẹ́ Ó Máa Yé Àwọn Èèyàn? (be-YR ojú ìwé 242 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 243 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Àkọsílẹ̀ Nípa Ọjọ́ Nóà—Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì fún Wa? (w03-YR 5/15 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 2 Sámúẹ́lì 13:10-22

No. 3: Kí Ni Ọ̀rọ̀ Inú Jòhánù 11:25, 26 Túmọ̀ Sí?

No. 4: gỌṣẹ́ Tí Ìmukúmu Ń Ṣe (fy-YR ojú ìwé 142 àti 143 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

May 30 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 16 sí 18 Orin 132

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àpèjúwe Tí A Gbé Ka Ohun Táwọn Èèyàn Mọ̀ (be-YR ojú ìwé 244 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

No. 1: Ronú Lọ́nà Tó Ṣe Tààrà Kó O sì Fi Ọgbọ́n Hùwà (w03-YR 7/15 ojú ìwé 21 sí 23)

No. 2: w03-YR 5/15 ojú ìwé 16 àti 17 ìpínrọ̀ 8 sí 11

No. 3: Ríran Mẹ́ńbà Ìdílé Tó Jẹ́ Onímukúmu Lọ́wọ́ (fy-YR ojú ìwé 143 sí 147 ìpínrọ̀ 5 sí 13)

No. 4: Ìdí Tí Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Kì Í Fi Í Ṣe Ìwà Agọ̀

June 6 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 19 sí 21 Orin 224

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àpèjúwe Tó Bá Ipò Àwùjọ Rẹ Mu (be-YR ojú ìwé 244 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 245 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Mímọrírì Ìdí Tá A Fi Ń Báni Wí (w03-YR 10/1 ojú ìwé 20 àti 21 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 2: 2 Sámúẹ́lì 19:1-10

No. 3: Báwo Làwọn Kristẹni Ṣe Lè Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run?

No. 4: hÌwà Ipá Abẹ́lé àti Bí A Ṣe Lè Yẹra fún Un (fy-YR ojú ìwé 147 sí 149 ìpínrọ̀ 14 sí 22)

June 13 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 22 sí 24 Orin 74

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ohun Tí A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 247 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

No. 1: Máa Gba Ẹ̀kọ́ Kí O sì Máa Ṣọ́ Ahọ́n Rẹ (w03-YR 9/15 ojú ìwé 21 àti 22 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 2: 2 Sámúẹ́lì 24:10-17

No. 3: Ṣé Pípínyà Ló Lè Yanjú Ìṣòro Ọkọ àti Aya? (fy-YR ojú ìwé 150 sí 152 ìpínrọ̀ 23 sí 26)

No. 4: Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Kristẹni Kan Fi Gbọ́dọ̀ Ya Ara Rẹ̀ Sọ́tọ̀ Kúrò Nínú Ayé?

June 20 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 1 àti 2 Orin 2

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí Jésù Ṣe Lo Ohun Tí A Lè Fojú Rí (be-YR ojú ìwé 247 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Kíkọ́ Béèyàn Ṣe Ń Lẹ́mìí Ohun-Moní-Tómi (w03-YR 6/1 ojú ìwé 8 sí 11)

No. 2: w03-YR 6/1 ojú ìwé 12 àti 13 ìpínrọ̀ 1 sí 4

No. 3: Kí Lohun Tó Ṣe Pàtàkì Gan-an Nípa Òfin Kẹwàá?

No. 4: iBí A Ṣe Lè Fi Ìwé Mímọ́ Yanjú Ìṣòro Ìgbéyàwó (fy-YR ojú ìwé 153 sí 156 ìpínrọ̀ 1 sí 9)

June 27 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 3 sí 6 Orin 167

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tí A Lè Fojú Rí (be-YR ojú ìwé 248 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

July 4 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 7 àti 8 Orin 194

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Àwòrán Ilẹ̀, Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ àti Fídíò (be-YR ojú ìwé 248 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 249 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Tẹ́ Ẹ Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́ (w03-YR 9/1 ojú ìwé 30 àti 31)

No. 2: 1 Àwọn Ọba 8:1-13

No. 3: Báwo Ni Jésù Ṣe Ṣẹ́gun Ayé?

No. 4: jFífi Ẹ̀tọ́ Ìgbéyàwó Fúnni (fy-YR ojú ìwé 156 sí 158 ìpínrọ̀ 10 sí 13)

July 11 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 9 sí 11 Orin 191

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ohun Tí A Lè Fojú Rí Níwájú Àwùjọ Ńlá (be-YR ojú ìwé 249 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 250 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Jésù Kristi Wá Sáyé (w03-YR 6/15 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 1 Àwọn Ọba 9:1-9

No. 3: Ohun Tí Bíbélì Sọ Pé Ó Lè Fa Ìkọ̀sílẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 158 àti 159 ìpínrọ̀ 14 sí 16)

No. 4: Fífi Àwọn Ìlànà Bíbélì Sílò Lè Ranni Lọ́wọ́ Láti Borí Ìṣòro Sísọ Oògùn Olóró Di Bárakú

July 18 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 12 sí 14 Orin 162

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìdí Tí Fífèròwérò Fi Ṣe Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 251 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Èrò Ọkàn Ẹni Nìwà Ẹni, Ìwà Ẹni sì Lẹ́san (w03-YR 1/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 2: 1 Àwọn Ọba 12:1-11

No. 3: Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Forí Ti Ìṣòro

No. 4: kOhun Tí Ìwé Mímọ́ Sọ Nípa Ìpínyà (fy-YR ojú ìwé 160 sí 162 ìpínrọ̀ 17 sí 22)

July 25 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 15 sí 17 Orin 158

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ibi Tó Yẹ Kí O Ti Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 251 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 252 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Bí A Ṣe Lè ‘Róye Ohun Tí Ìfẹ́ Jèhófà Jẹ́’ (w03-YR 12/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 2)

No. 2: w03-YR 7/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 15 sí 17

No. 3: Dídàgbà Pọ̀ (fy-YR ojú ìwé 163 sí 165 ìpínrọ̀ 1 sí 9)

No. 4: Báwo Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Ń Tu Àwọn Kristẹni Nínú?

Aug. 1 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 18 sí 20 Orin 207

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìgbà Tó Yẹ Kí O Juwọ́ Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 252 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 253 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Máa Rìn ní Ọ̀nà Tó Wu Jèhófà (w03-YR 10/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: 1 Àwọn Ọba 18:1-15

No. 3: Gbogbo Kristẹni Lè So Èso Púpọ̀

No. 4: lFífún Ìdè Ìgbéyàwó Lókun Lẹ́ẹ̀kan Sí I (fy-YR ojú ìwé 166 àti 167 ìpínrọ̀ 10 sí 13)

Aug. 8 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 21 àti 22 Orin 92

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Máa Béèrè Ìbéèrè Kó O sì Máa Ṣàlàyé Ìdí Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 253 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 254 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Bí Ipò Òṣì Ṣe Máa Dópin Títí Láé (w03-YR 8/1 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 1 Àwọn Ọba 21:15-26

No. 3: Gbádùn Àwọn Ọmọ-Ọmọ Rẹ Kí O sì Máa Mú Ara Rẹ Bá Àwọn Àyípadà Tó Ń Wáyé Bí O Ti Ń Darúgbó Mu (fy-YR ojú ìwé 168 sí 170 ìpínrọ̀ 14 sí 19)

No. 4: Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Ní Ìgboyà, Báwo La sì Ṣe Lè Ní In?

Aug. 15 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 1 sí 4 Orin 16

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ẹ̀rí Tó Yè Kooro Tí A Gbé Karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 255 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 256 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Ọ̀fẹ́ Ni Ẹ̀yin Gbà, Ọ̀fẹ́ Ni Kí Ẹ Fúnni (w03-YR 8/1 ojú ìwé 20 sí 22)

No. 2: 2 Àwọn Ọba 3:1-12

No. 3: Kí Nìdí Táwọn Tó Gbé Ayé Ṣáájú Ìkún Omi Fi Ń Pẹ́ Láyé?

No. 4: aFífarada Ìdààmú Ikú Ọkọ Tàbí Aya Ẹni (fy-YR ojú ìwé 170 sí 172 ìpínrọ̀ 20 sí 25)

Aug. 22 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 5 sí 8 Orin 193

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fi Àfikún Ẹ̀rí Ti Ọ̀rọ̀ Rẹ Lẹ́yìn (be-YR ojú ìwé 256 ìpínrọ̀ 3 sí 5)

No. 1: Kíkọ́ Bá A Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Lò (w03-YR 8/1 ojú ìwé 29 sí 31)

No. 2: w03-YR 8/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 18 sí 22

No. 3: Bí Àwọn Kristẹni Ṣe Ń Bọlá fún Àwọn Òbí Wọn Àgbà (fy-YR ojú ìwé 173 sí 175 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 4: Àwọn Ànímọ́ Dáadáa Wo Ni Jónà Ní Tó Yẹ Ká Fi Ṣe Àwòkọ́ṣe?

Aug. 29 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 9 sí 11 Orin 129

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Mímú Ẹ̀rí Tó Pọ̀ Tó Jáde (be-YR ojú ìwé 257 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Sept. 5 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 12 sí 15 Orin 175

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Rírí I Dájú Pé Ọ̀rọ̀ Wa Wọni Lọ́kàn (be-YR ojú ìwé 258 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 1: Ǹjẹ́ Ò Ń Wá Jèhófà Tọkàntọkàn? (w03-YR 8/15 ojú ìwé 25 sí 28)

No. 2: 2 Àwọn Ọba 12:1-12

No. 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Oníwàtútù?

No. 4: bFi Ìfẹ́ àti Ẹ̀mí Ìfọ̀ràn-Rora-Ẹni-Wò Hàn (fy-YR ojú ìwé 175 sí 178 ìpínrọ̀ 6 sí 14)

Sept. 12 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 16 sí 18 Orin 203

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Lè Mọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Àwọn Èèyàn (be-YR ojú ìwé 259 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Kí Làwọn Èèyàn Fi Ń Rántí Jésù? (w03-YR 8/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 6)

No. 2: 2 Àwọn Ọba 16:10-20

No. 3: Máa Wojú Jèhófà fún Okun Nígbà Gbogbo (fy-YR ojú ìwé 179 sí 182 ìpínrọ̀ 15 sí 21)

No. 4: Báwo La Ṣe Lè Rí I Dájú Pé A Mọ Ohun Tó Ṣètẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

Sept. 19 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 19 sí 22 Orin 89

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Ń Gbin Ẹ̀mí Rere Sọ́kàn Àwọn Olùgbọ́ (be-YR ojú ìwé 259 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 260 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: ‘Máa Di Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rọ̀ Afúnni-Nílera Mú’ (w03-YR 1/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: 2 Àwọn Ọba 19:20-28

No. 3: Sapá Láti Ní Ìfọkànsìn Ọlọ́run àti Ìkóra-Ẹni-Níjàánu (fy-YR ojú ìwé 183 àti 184 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 4: Ẹ̀kọ́ Wo La Lè Rí Kọ́ Lára Àwọn Kristẹni Ará Wa ní Ìlú Símínà Ìgbàanì?

Sept. 26 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 23 sí 25 Orin 84

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ríran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 260 ìpínrọ̀ 2 àti 3)

No. 1: Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Jìyà (w03-YR 1/1 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: w03-YR 8/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 6 sí 10

No. 3: A Gbà Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dára

No. 4: cOjú Ìwòye Tó Tọ́ Nípa Ipò Orí (fy-YR ojú ìwé 185 àti 186 ìpínrọ̀ 6 sí 9)

Oct. 3 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 1 sí 4 Orin 51

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìwà Wa Ṣe Pàtàkì Lójú Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 260 ìpínrọ̀ 4 àti 5)

No. 1: Ṣé Èṣù Ti Borí Ni? (w03-YR 1/15 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 1 Kíróníkà 4:24-43

No. 3: Ipa Pàtàkì Tí Ìfẹ́ Ń Kó Nínú Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 186 àti 187 ìpínrọ̀ 10 sí 12)

No. 4: Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Olúkúlùkù Wa Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan

Oct. 10 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 5 sí 7 Orin 195

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ríran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Yẹ Ara Wọn Wò (be-YR ojú ìwé 261 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Bá A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Yẹ Nípa Iṣẹ́ (w03-YR 2/1 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 1 Kíróníkà 5:18-26

No. 3: Ohun Tí A Mọ̀ Nípa “Ọjọ́ Jèhófà”

No. 4: dÌdílé Tó Ń Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run (fy-YR ojú ìwé 188 àti 189 ìpínrọ̀ 13 sí 15)

Oct. 17 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 8 sí 11 Orin 201

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ríran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Máa Ṣègbọràn Látọkànwá (be-YR ojú ìwé 261 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 262 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: “Ẹ Mọ́kànle! Mo Ti Ṣẹ́gun Ayé” (w03-YR 3/15 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 1 Kíróníkà 10:1-14

No. 3: Ìdílé àti Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ (fy-YR ojú ìwé 190 àti 191 ìpínrọ̀ 16 sí 18)

No. 4: Àwọn Wo Ló Yẹ Ká Máa Fọgbọ́n Bá Lò?

Oct. 24 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 12 sí 15 Orin 80

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Tẹ̀ Lé Àwọn Ìtọ́sọ́nà Jèhófà Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Lè Dénú Ọkàn Àwọn Èèyàn (be-YR ojú ìwé 262 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Ibo Lo Ti Lè Rí Ìlànà Ẹ̀sìn Tòótọ́? (w03-YR 4/15 ojú ìwé 5 sí 7)

No. 2: w03-YR 11/1 ojú ìwé 10 àti 11 ìpínrọ̀ 10 sí 13

No. 3: Ohun Tí Rírìn ní Orúkọ Jèhófà Túmọ̀ sí ní Tòótọ́

No. 4: Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́ (td-YR 1A)

Oct. 31 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 16 sí 20 Orin 129

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Àkókò Bó Ṣe Yẹ (be-YR ojú ìwé 263 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 264 ìpínrọ̀ 4)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Nov. 7 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 21 sí 25 Orin 215

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Gbígbani-níyànjú Lọ́nà Tó Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 265 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 266 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Ẹ Dúró Ṣinṣin Kẹ́ Ẹ sì Gba Ẹ̀bùn Eré Ìje Ìyè (w03-YR 5/15 ojú ìwé 21 sí 24)

No. 2: 1 Kíróníkà 22:1-10

No. 3: Àtúnwí Asán, Àdúrà sí Màríà, Tàbí Àwọn “Ẹni Mímọ́” Kò Lẹ́sẹ̀ Nílẹ̀ (td-YR 1B)

No. 4: eBí A Ṣe Lè Mú Kí Ìgbéyàwó Túbọ̀ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Dáadáa

Nov. 14 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 26 sí 29 Orin 35

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Ìfẹ́ Gbani-níyànjú (be-YR ojú ìwé 266 ìpínrọ̀ 2 sí 5)

No. 1: Ọrẹ Tí Inú Ọlọ́run Ń Dùn Sí (w03-YR 6/1 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 1 Kíróníkà 29:1-9

No. 3: Ìdí Táwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Fi Ń Rí Inúnibíni

No. 4: A Gbé Jésù Kọ́ Sórí Òpó Igi Ìfikúpani Gẹ́gẹ́ Bí Ẹ̀gàn (td-YR 2A)

Nov. 21 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 1 sí 5 Orin 46

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìgbani-níyànjú Tí A Gbé Ka Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 267 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

No. 1: Béèyàn Ṣe Lè ní Ojúlówó Ìfẹ́ (w03-YR 7/1 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 2 Kíróníkà 2:1-10

No. 3: Lílóye Ìdí Tí A Fi Ń Gba Ìbáwí

No. 4: A Kò Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn Rẹ̀ (td-YR 2B)

Nov. 28 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 6 sí 9 Orin 106

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Níní “Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ” (be-YR ojú ìwé 267 ìpínrọ̀ 3 àti 4)

No. 1: Ìdí Tá Ò Fi Lè Dá Wà Láìfi Tàwọn Ẹlòmíràn Ṣe (w03-YR 7/15 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: w03-YR 12/1 ojú ìwé 15 sí 16 ìpínrọ̀ 3 sí 6

No. 3: Bí A Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Ní Ìdùnnú Kíkọyọyọ Nínú Jèhófà

No. 4: Ìrètí fún Àwọn Òkú (td-YR 3A)

Dec. 5 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 10 sí 14 Orin 116

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Fún Àwùjọ Lókun (be-YR ojú ìwé 268 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Ìsìn Kristẹni Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Ló Wà (w03-YR 9/1 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 2 Kíróníkà 12:1-12

No. 3: Ìdí Tí A Fi Nílò Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run

No. 4: Àjíǹde sí Ìyè ní Ọ̀run Tàbí Lórí Ilẹ̀ Ayé (td-YR 3B)

Dec. 12 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 15 sí 19 Orin 182

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Rírán Àwùjọ Létí Ohun Tí Jèhófà Ti Ṣe (be-YR ojú ìwé 268 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 269 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Ń Dá sí Ọ̀ràn Ẹ̀dá Èèyàn? (w03-YR 10/1 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: 2 Kíróníkà 19:1-11

No. 3: Ogun Ọlọ́run Láti Fi Òpin sí Ìwà Burúkú (td-YR 4A)

No. 4: Ẹ̀kọ́ Tí A Lè Rí Kọ́ Lára Ìdílé Jésù

Dec. 19 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 20 sí 24 Orin 186

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Bí Jèhófà Ti Ṣe Ran Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Lọ́wọ́ (be-YR ojú ìwé 269 ìpínrọ̀ 3 sí 5)

No. 1: Báwo Lo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání? (w03-YR 10/15 ojú ìwé 4 sí 7)

No. 2: w03-YR 12/15 ojú ìwé 16 àti 17 ìpínrọ̀ 13 sí 15

No. 3: Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Kíkọ́ Béèyàn Ṣe Ń Lẹ́mìí Ohun-Moní-Tómi

No. 4: Ogun Amágẹ́dọ́nì Kò Lòdì sí Òfin Ìfẹ́ Ọlọ́run (td-YR 4B)

Dec. 26 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 25 sí 28 Orin 137

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Ìdùnnú Sọ̀rọ̀ Nípa Ohun Tí Ọlọ́run Ń Gbé Ṣe Nísinsìnyí (be-YR ojú ìwé 270 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 271 ìpínrọ̀ 1)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

b Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

c Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

d Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

e Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

f Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

g Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

h Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

i Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

j Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

k Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

l Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

a Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

b Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

c Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

d Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

e Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́