Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Oct. 15
“Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé béèyàn bá kàwé, ayé ẹ̀ ti dáa nìyẹn. Ǹjẹ́ o rò pé ẹ̀kọ́ ìwé kan wà tó lè tún ayé èèyàn ṣe tó sì lè mú kéèyàn lè fàyà rán ìṣòro ìgbésí ayé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Róòmù 12:2.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bá a ṣe lè jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ tó dáa jù lọ.”
Ile Iṣọ Nov. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ni inú wọn kò dùn sí bí nǹkan ò ṣe rí bó ṣe yẹ kó rí nínú ayé. Ǹjẹ́ o rò pé ẹnì kan wà tó lè tún ayé yìí ṣe? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò àwọn nǹkan tó ń dènà àyípadà rere. Ó tún sọ ẹni tó máa mú àyípadà wá àti bó ṣe máa jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ayé tí kálukú á sì máa gbé láìséwu.” Ka Sáàmù 72:12-14.
Jí Nov. 8
“Kárí ayé, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló wà láàárín olówó àti òtòṣì. Ǹjẹ́ o rò pé ohun kan wà tó lè mú ìyàtọ̀ náà kúrò? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Mátíù 6:9, 10.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Ìjọba Ọlọ́run á fópin sí àìdọ́gba tó wà láàárín aráyé lóde tòní.”
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń gbádùn kíka ìwé ìròyìn. Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo ohun táwọn ìwé ìròyìn ń gbé jáde ló ṣeé gbà gbọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí dábàá bá a ṣe lè jàǹfààní látinú kíka ìwé ìròyìn. Bákan náà, ó sọ ìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra.” Ka Òwe 14:15.