Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Oct. 15
“Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé fún àwọn ọmọdé tàbí àwọn ẹlòmíràn nípa ìdí tí ọ̀pọ̀ ohun búburú fi ń ṣẹlẹ̀ lónìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì dáhùn ìbéèrè náà, ‘Ta Ní Ń Bẹ Lẹ́yìn Gbogbo Láabi Tí Ń Ṣẹlẹ̀?’ [Ka 1 Jòhánù 5:19.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ olubi ọ̀hún àti bí a ṣe lè kọjúùjà sí i.”
Ilé Ìṣọ́ Nov. 1
“Ọ̀pọ̀ lára wa máa ń gbìyànjú láti wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́, wàá gbà pé èyí kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti ṣe. [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀. [Ka Jákọ́bù 3:2.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ bí títọrọ àforíjì ṣe lè jẹ́ kókó pàtàkì kan láti fi mú kí àlàáfíà wà láàárín tọ̀túntòsì.”
Jí! Nov. 8
“Ǹjẹ́ o rò pé àdúrà tí àwọn aṣáájú ìsìn tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn ń gbà lè mú àlàáfíà ayé wá? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí àlàáfíà yóò wà kárí ayé. [Ka Aísáyà 9:6, 7.] Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé alákòóso pàtàkì kan ni yóò mú àlàáfíà ayé wá? Ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ ẹni tí alákòóso yẹn jẹ́ àti bí yóò ṣe mú ojúlówó àlàáfíà wá.”
“Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí ẹnì kankan kì yóò sọ pé, ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ [Ka Aísáyà 33:24.] Ǹjẹ́ o ò gbà pé ìyẹn á dára gan-an? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bó ti wù kó rí, lóde òní, aráyé ń dojú kọ oríṣiríṣi àìsàn, títí kan àjàkálẹ̀ àrùn éèdì. Ìtẹ̀jáde Jí! yìí dáhùn ìbéèrè náà, Ǹjẹ́ àrùn Éèdì máa dópin láé?”