Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Oct. 15
“Torí pé ọ̀run ni Ọlọ́run wà, èrò àwọn kan ni pé kò lè ṣeé ṣe láti mọ Ọlọ́run. Ṣé ìwọ náà ti rò bẹ́ẹ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Jòhánù 17:3.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè ní ìmọ̀ Ọlọ́run.”
Ile Iṣọ Nov. 1
“Lónìí, àlàyé tó ta kora nípa béèyàn ṣe lè tọ́mọ pọ̀ lọ jàra. Ṣó o rò pé ó ṣeé ṣe fáwọn òbí láti rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbọ́kàn lé? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Sáàmù 32:8.] Ìwé ìròyìn yìí fún wa ní ìtọ́ni tó wúlò látinú Bíbélì nípa ọmọ títọ́.”
Jí! Oct.-Dec.
“Ṣó o rò pé ó ṣeé ṣe láti tún fojú kan àwọn èèyàn wa tó ti kú? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí Jésù sọ pé òun máa ṣe nípa àwọn tó ti kú. [Ka Jòhánù 5:28, 29.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá kú.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 26 hàn án.
“Bóyá la fi máa rẹ́ni tí wíwo tẹlifíṣọ̀n kì í dùn mọ́. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o rò pó pọn dandan láti máa ṣàṣàyàn ohun tó yẹ ká máa wò? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ka Òwe 13:20.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ipa tí tẹlifíṣọ̀n ń ní lórí wa, ó sì dábàá àwọn ọ̀nà tá a lè gbà pinnu bá a ó ṣe máa wo tẹlifíṣọ̀n tó.”