Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Oct. 15
“Kí la máa ṣe láti sọ ayé di ibi kan tó sàn jù, tí ayọ̀ kún inú rẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ẹ̀dá èèyàn ti gbìyànjú ìjọba kan tẹ̀ lé òmíràn láti mú nǹkan sunwọ̀n sí i. Ṣùgbọ́n kíyè sí èrò Ọlọ́run nípa èyí. [Ka Jeremáyà 10:23.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ‘Ohun Náà Gan-an Tó Máa Mú Ayé Aláyọ̀ Wá,’ ó sì fi bí èyí ṣe máa tó wáyé hàn.”
Jí! Nov. 8
“Ǹjẹ́ o gbà pé pákáǹleke túbọ̀ ń bá aráyé lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ èyí. [Ka 2 Tímótì 3:1.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìgbésí ayé máa ń ṣòro fún débi pé wọ́n máa ń sọ̀rètí nù. Ìwé ìròyìn yìí fúnni ní ìṣírí gan-an ni. Ó ṣàlàyé béèyàn ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ àìnírètí kí ó sì jẹ́ kí ìgbésí ayé gbádùn mọ́ òun.”
Ilé Ìṣọ́ Nov. 1
Lẹ́yìn tí o bá ti sọ ìròyìn kan tó ń dani láàmù, béèrè pé: “Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe irú ohun búburú bẹ́ẹ̀? Gbogbo wa ló yẹ ká mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn ṣì ń ṣe àwọn nǹkan búburú síbẹ̀. Kí ló fà á? [Lẹ́yìn tí ó bá fèsì, ka Ìṣípayá 12:9.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí a ṣe lè dáàbò bo ara wa nípa fífi ìṣọ́ ṣọ́ ẹ̀rí ọkàn wa.”
Jí! Nov. 8
“Ìwọ náà á gbà pé àkókò oníwà ipá la ń gbé yìí. [Lẹ́yìn tí ó bá fèsì, ka 2 Tímótì 3:3.] Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwà ‘òǹrorò’ máa ń wáyé kódà nínú agbo ìdílé pàápàá. Àpilẹ̀kọ yìí tí a pè ní, ‘Ìrànwọ́ fún Àwọn Obìnrin Tí Ọkọ Wọn Ń Lù,’ sọ ọ̀rọ̀ tó kún fún ìrètí. Ó ṣeé ṣe kí o mọ ẹni tó lè jàǹfààní látinú rẹ̀.”