Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Oct. 15
“Ọ̀pọ̀ ìpinnu tí a ní láti ṣe máa ń nípa gan-an lórí ìgbésí ayé wa. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àwọn ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 3:6.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí jíròrò àwọn ìlànà márùn-ún tí a gbé karí Bíbélì, èyí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.”
Ilé Ìṣọ́ Nov. 1
“Gbogbo wa ni ẹnì kan ti já kulẹ̀ rí nígbà kan tàbí òmíràn. Ǹjẹ́ o ti rò ó wò rí pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà tí mo lè gbẹ́kẹ̀ lé?’ [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 3:5.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọlọ́run. Ó tún jíròrò nípa bí a ṣe lè mọ irú àwọn ẹni tó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé.”
Jí! Nov. 8
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí ohun èlò kankan tá à ń lò nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ tí kì í ṣe pé àtinú epo rọ̀bì ni wọ́n ti mú un jáde. Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa bí ìgbésí ayé á ṣe rí láìsí àwọn ohun wọ̀nyí tí wọ́n mú jáde látinú epo rọ̀bì? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò nípa bí epo rọ̀bì ṣe wá di ohun tó ń kó ipa pàtàkì nínú àwùjọ wa òde òní. Ó tún ṣàlàyé ìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù pé lọ́jọ́ kan, kò ní sí epo rọ̀bì mọ́ lórí ilẹ̀ ayé.”