Jàǹfààní Láti Inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996—Apá 2
1 Kété lẹ́yìn ìdásílẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun ní 1943, ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀ka Society ròyìn pé: “Ètò àtàtà yìí ti ṣàṣeyọrí láàárín sáà kúkúrú ní ṣíṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn ará, tí wọ́n ti ronú tẹ́lẹ̀ pé wọn kò lè jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ ní gbangba láé, láti dáńgájíá dáradára lórí pèpéle, kí wọ́n sì gbéṣẹ́ sí i nínú pápá.” Ilé ẹ̀kọ́ náà ń bá a nìṣó láti pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ títayọ lọ́lá, tí gbogbo wa nílò.
2 Bibeli Kíkà: Kì í ṣe kìkì àwọn tí a fún ní apá ọ̀rọ̀ sísọ ní ń jàǹfààní láti inú ilé ẹ̀kọ́ náà. Ní tòótọ́, gbogbo wá ní iṣẹ́ àyànfúnni kan—Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ fi àwọn orí Bibeli tí a óò kà ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan hàn. Ọ̀pọ̀ ìránnilétí inú Ìwé Mímọ́ wà, tí ó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì kíka Bibeli lójoojúmọ́. (Joṣ. 1:8; Orin Da. 1:2; Ìṣe 17:11) Bibeli kíkà ṣe kókó fún ìlera pípé nípa tẹ̀mí; ó ń bọ́ èrò inú àti ọkàn-àyà. Bí a bá ń ka Bibeli, ó kéré tán fún ìṣẹ́jú márùn-ún lójoojúmọ́, a óò lè máa bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣe déédéé. Ní òpin ọdún, a óò ti kà ju 150 orí lọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bí a bá fi Bibeli kan sárọ̀ọ́wọ́tó, ó yẹ̀ kí a lè ka díẹ̀ nínú rẹ̀ lójoojúmọ́.
3 Ọ̀rọ̀ Ìtọ́ni: Láti ru àwọn ará sókè sí iṣẹ́ ìsìn onídùúróṣinṣin àti onítara, ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ ìtọ́ni ní láti lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára, kí ó fúnni lóye, kí ó sì mú ìmọrírì dàgbà fún Jehofa, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀. Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ṣàṣeparí èyí nípa mímúra sílẹ̀ dáradára, ní gbígbé ọ̀rọ̀ wọn ka orí ẹṣin ọ̀rọ̀, sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú, àti mímú kí ọ̀rọ̀ náà lárinrin. (Heb. 4:12) Ó ṣe pàtàkì pé kí olùbánisọ̀rọ̀ má ṣe lò kọjá àkókò tí a yàn fún un. Ìwé Isopọṣọkan àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà kún fún àwọn ẹsẹ Bibeli, wọ́n sì pèsè ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ lílárinrin tí ó lè ṣe wá láǹfààní nípa tẹ̀mí.
4 Àwọn Kókó Pàtàkì Láti Inú Bibeli: Àwọn arákùnrin tí a bá fún ní iṣẹ́ àyànfúnni yìí ní láti yan àwọn ẹsẹ kan pàtó tí a lè lò ní ọ̀nà gbígbéṣẹ́ fún àǹfààní ìjọ. Èyí ń béèrè fún kíka àwọn orí tí a yàn fúnni, ṣíṣe àṣàrò lórí wọn, àti ṣíṣe ìwádìí lórí àwọn ẹsẹ tí a yàn, láti rí àwọn kókó tí yóò mú ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ náà yéni. “Scripture Index,” tí ó lè ṣèrànwọ́ nínú wíwá ìsọfúnni nípa àwọn ẹsẹ Bibeli kan pàtó, wà lẹ́yìn ìwé Watch Tower Publications Index. Àwọn arákùnrin tí ń bójú tó apá yìí ní láti lo ìwòyemọ̀, kí wọ́n sì yẹra fún fifi àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí kò bá a mu kún un. Wọn kò ní láti múra àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ju èyí tí wọ́n lè kárí láàárín ìṣẹ́jú mẹ́fà lọ.
5 Gbogbo wa lè jàǹfààní láti inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti sunwọ̀n sí i nínú agbára ìsọ̀rọ̀ àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa. Dájúdájú, lílo àǹfààní ìpèsè yìí ní kíkún yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú ‘kí ìlọsíwájú wá fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.’—1 Tim. 4:15.