Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Ọdún 2001
1 Ìdí púpọ̀ tó bá Ìwé Mímọ́ mu ló wà tó fi yẹ kí gbogbo wa kópa ní kíkún bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.—Òwe 15:23; Mát. 28:19, 20; Ìṣe 15:32; 1 Tím. 4:12, 13; 2 Tím. 2:2; 1 Pét. 3:15.
2 Ó pẹ́ ti ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún kíka Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí máa ń wáyé nínú ilé ẹ̀kọ́ náà. Kíka nǹkan bí ojú ewé kan nínú Bíbélì lójoojúmọ́ ló túmọ̀ sí. Bẹ̀rẹ̀ látọdún yìí, a ṣètò Bíbélì kíkà fún ọ̀sẹ̀ àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú. Àfikún ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà, tí a ti fi kún un látọdún mẹ́ta sẹ́yìn ni a ti parí. Ṣùgbọ́n, bí o bá fẹ́ láti ka Bíbélì sí i ju èyí tí a ṣètò, o lè ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tìrẹ.
3 Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì ń kọ́ àwọn arákùnrin ní “ìwé kíkà ní gbangba” nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Tím. 4:13) Bí wọ́n bá yan Bíbélì kíkà fún ọ, fi í dánra wò kí o máa kà á sókè ketekete léraléra. O lè lo Bíbélì kíkà tí Society ṣe sínú kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́ kí o lè túbọ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń pe ọ̀rọ̀, bí a ṣe ń gbé ohun sókè sódò, àti bí a ṣe lè mú àwọn apá mìíràn nínú ìwé kíkà sunwọ̀n sí i.
4 Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta àti Ìkẹrin la gbé karí “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ní àfikún sí èyí, a tún gbé Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin karí ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Bí ibi tí a yàn fún ọ bá ju ohun tí o lè kárí láàárín àkókò tí a fún ọ, yan kìkì ohun tí á wúlò jù lọ ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín. O lè lo ìgbékalẹ̀ èyíkéyìí tó bá bá ìpínlẹ̀ yín mu jù lọ.
5 Sa gbogbo ipá tó bá yẹ láti ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún ọ ní ilé ẹ̀kọ́. Wá àyè múra sílẹ̀ dáadáa, kí o sì sọ̀rọ̀ látọkàn wá. O máa jẹ́ orísun ìṣírí fún ìjọ, ìwọ fúnra rẹ yóò sì jàǹfààní nípa fífi tọkàntọkàn kópa nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ní ọdún 2001.