ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ojú ìwé 43-ojú ìwé 46
  • Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí A Ṣe Ń Múra Iṣẹ́ Ìwé Kíkà Sílẹ̀
  • Mímúra Iṣẹ́ Tó Ní Ẹṣin Ọ̀rọ̀ àti Ìgbékalẹ̀
  • Nígbà Tí Iṣẹ́ Rẹ Bá Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Tààràtà
  • Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ Jáde Láti Ibi Tí A Ti Yanṣẹ́ fún Ọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìlànà Fún Àwọn Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Mú Wa Gbára Dì fún Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nígbèésí Ayé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ojú ìwé 43-ojú ìwé 46

Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀

BÍ O ṣe ń gba iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan lo ṣe ń láǹfààní láti tẹ̀ síwájú sí i. Máa ṣakitiyan nípa rẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìlọsíwájú rẹ yóò hàn kedere sí ọ àti sí àwọn ẹlòmíràn. (1 Tím. 4:15) Ilé ẹ̀kọ́ yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí òye rẹ túbọ̀ pọ̀ sí i.

Ṣé àyà rẹ máa ń là gààrà nítorí pé o fẹ́ sọ̀rọ̀ níwájú ìjọ? Ó máa ń ṣèèyàn bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, kódà bó bá tiẹ̀ ti pẹ́ tó o ti jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan kan wà tó lè mú kí àyà rẹ má fi bẹ́ẹ̀ já púpọ̀ mọ́. Nílé, jẹ́ kó mọ́ ọ lára láti máa kàwé síta lọ́pọ̀ ìgbà. Nínú ìpàdé ìjọ, máa lóhùn sí ọ̀rọ̀ dáadáa, bó o bá sì ti di akéde, máa jáde òde ẹ̀rí déédéé. Ìyẹn á jẹ́ kó o nírìírí nípa bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ẹlòmíràn. Ẹ̀wẹ̀, máa tètè múra iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tá a bá yàn fún ọ sílẹ̀ ṣáájú àkókò, kí o sì fi bí o ṣe máa sọ ọ́ dánra wò, kí o sọ ọ́ síta ni o. Rántí pé iwájú àwùjọ tó fẹ́ràn rẹ lo ti fẹ́ sọ ọ́. Kí o sì tó sọ ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tí a bá yàn fún ọ, kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà ná. Tìdùnnú-tìdùnnú ló máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó bá tọrọ rẹ̀.—Lúùkù 11:13; Fílí. 4:6, 7.

Jẹ́ kí ohun tó o ń retí pé wàá ṣe wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè nírìírí láti fi lè di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dá-ń-tọ́ àti olùkọ́ni tó gbó ṣáṣá. (Míkà 6:8) Bó o bá jẹ́ ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ forúkọ sílẹ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́, má rò pé ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ á kàn bẹ̀rẹ̀ sí dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa ṣiṣẹ́ lórí kókó ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀kan. Ka apá tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ìwé yìí. Tó bá ṣeé ṣe, ṣe àwọn iṣẹ́ àṣedánrawò tí a dámọ̀ràn síbẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ̀ nípa kókó tí ìmọ̀ràn yẹn ń sọ, kó o tó sọ ọ̀rọ̀ rẹ nínú ìjọ. Wàá sì rí i pé wàá máa tẹ̀ síwájú.

Bí A Ṣe Ń Múra Iṣẹ́ Ìwé Kíkà Sílẹ̀

Mímúra ìwé kíkà sílẹ̀ kò mọ sórí kéèyàn sáà ti lè pe ọ̀rọ̀ inú ìwé tí wọ́n ní kó kà sókè o. Gbìyànjú láti lóye ohun tí àkójọ ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí ní kedere. Gbàrà tí iṣẹ́ yẹn bá ti tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, kà á pẹ̀lú ète yẹn lọ́kàn. Gbìyànjú láti lóye kókó tí gbólóhùn kọ̀ọ̀kan ń sọ àti èrò tó wà nínú ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kí o fi lè gbé èrò yẹn jáde lọ́nà tó péye tó sì fi bí nǹkan ṣe rí lára hàn. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, wo ìwé atúmọ̀ èdè fún ìwádìí nípa ọ̀nà tí ó tọ́ láti gbà pe ọ̀rọ̀ tó ò bá mọ̀ tẹ́lẹ̀. Rí i pé àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn yé ọ dáadáa. Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn kéékèèké lọ́wọ́ láti ṣe èyí.

Ṣé apá kan nínú Bíbélì tàbí àwọn ìpínrọ̀ àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ ni wọ́n yàn fún ọ láti kà ni? Bí wọ́n bá ti ka ibi tí wọ́n yàn fún ọ yẹn sínú kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí kan lédè rẹ, ó lè jẹ́ ohun tó wúlò gan-an bí o bá tẹ́tí sí bí wọ́n ṣe kà á, kí o sì ṣàkíyèsí àwọn nǹkan bí, ìpè ọ̀rọ̀, kíka gbólóhùn ọ̀rọ̀, ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀, àti ìlò ohùn. Kí o sì wá gbìyànjú láti fi ànímọ́ wọ̀nyí kún ọ̀nà ìgbàkàwé tìrẹ.

Rí i dájú pé o fara balẹ̀ ka ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n yàn fún ọ láti ṣiṣẹ́ lé lórí tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀. Tún gbé e yẹ̀ wò bó bá ṣeé ṣe, lẹ́yìn tó o bá ti ka ibi tí wọ́n yàn fún ọ síta léraléra. Gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn tó o kà nínú ìwé yẹn sílò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Ọ̀pọ̀ àǹfààní ni o ní láti kàwé sétígbọ̀ọ́ àwọn ẹlòmíràn bí o bá wà lóde ẹ̀rí. Níwọ̀n bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ti lágbára láti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn padà, ó ṣe pàtàkì pé kó o kà á dáadáa. (Héb. 4:12) Má rò pé tó o bá kàn ti ṣe iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì nínú ilé ẹ̀kọ́, wàá ti dẹni tó ní gbogbo ànímọ́ téèyàn fi lè kàwé lọ́nà tó wọni lọ́kàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣì kọ̀wé sí Kristẹni alàgbà kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ alàgbà pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba.”—1 Tím. 4:13.

Mímúra Iṣẹ́ Tó Ní Ẹṣin Ọ̀rọ̀ àti Ìgbékalẹ̀

Bí wọ́n bá yan iṣẹ́ fún ọ nílé ẹ̀kọ́, tó béèrè pé kí o gbé e kalẹ̀ lọ́nà kan pàtó, báwo lo ṣe máa ṣe é ná?

Ohun pàtàkì mẹ́ta ló yẹ kí o gbé yẹ̀ wò: (1) ẹṣin ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní kó o sọ̀rọ̀ lé lórí, (2) ìgbékalẹ̀ tó o fẹ́ lò àti ẹni tẹ́ ẹ jọ máa sọ̀rọ̀, àti (3) kókó ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n ní kó o ṣiṣẹ́ lé lórí.

Ó yẹ kí o kó ìsọfúnni jọ nípa ẹṣin ọ̀rọ̀ tí wọ́n yàn fún ọ láti sọ̀rọ̀ lé lórí. Ṣùgbọ́n kó o tó lọ jìnnà lẹ́nu ṣíṣe ìyẹn, ronú dáadáa nípa ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ àti irú ẹni tí ẹ jọ máa sọ̀rọ̀, nítorí nǹkan wọ̀nyẹn máa ní ipa lórí irú ìsọfúnni tó o máa sọ̀rọ̀ lé lórí, àti ọ̀nà tó o máa gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀. Ìgbékalẹ̀ wo lo máa lò? Ṣé àṣefihàn nípa bó o ṣe máa wàásù ìhìn rere fún ẹni tó o mọ̀ lo fẹ́ ṣe ni? Tàbí o fẹ́ fi ohun tó lè ṣẹlẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bá ẹnì kan pàdé hàn? Ṣé ẹni yẹn dàgbà jù ọ́ ni tàbí kò tó ọ lọ́jọ́ orí? Kí ló lè jẹ́ ìṣarasíhùwà rẹ̀ nípa ẹṣin ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí? Kí ló lè ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tí o fẹ́ bá a sọ? Kí ni ohun tó o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ sún un láti ṣe? Ohun tó bá jẹ́ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí ni yóò jẹ́ kí o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe.

Ibo lo ti fẹ́ rí ìsọfúnni nípa ẹṣin ọ̀rọ̀ tí wọ́n yàn fún ọ láti sọ̀rọ̀ lé lórí? Ní ojú ewé 33 sí 38 nínú ìwé yìí, a sọ̀rọ̀ nípa “Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìwádìí.” Kà á, kí o sì wá lo ohun èlò ìṣèwádìí tó o bá lè rí lò. Lọ́pọ̀ ìgbà, kíákíá ni ìsọfúnni tó o máa rí kó jọ yóò ti pọ̀ ju ohun tó o nílò lọ. Kàwé tó pọ̀ tó kí o lè mọ̀ nípa àwọn ìsọfúnni tó o lè rí lò. Àmọ́, bí o ṣe ń kà á yẹn náà, má gbàgbé ìgbékalẹ̀ tó o fẹ́ lò àti ẹni tí ẹ jọ fẹ́ fọ̀rọ̀ wérọ̀. Sàmì sí àwọn kókó tó máa dára láti lò.

Kí o tó ṣètò bí o ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀, kí o sì tó yan àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó o máa wá lò níkẹyìn, wáyè ka ibi tí a ti ṣàlàyé nípa ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n yàn fún ọ láti ṣíṣẹ lé lórí. Ọ̀kan lára ìdí pàtàkì tí wọ́n fi yan iṣẹ́ náà fún ọ ni láti rí i pé o lo ìmọ̀ràn yẹn.

Bí o bá kárí ọ̀rọ̀ rẹ láàárín àkókò tí wọ́n yàn fún ọ, ọkàn rẹ á balẹ̀ pé o sọ ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí bí àkókò tó wà fún iṣẹ́ rẹ bá ti parí, wọ́n á jẹ́ kó o mọ̀. Ṣùgbọ́n bí a bá wà lóde ẹ̀rí, àkókò wíwò kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkan bàbàrà rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, bí o ṣe ń múra iṣẹ́ rẹ, máa rántí ìwọ̀n àkókò tó o ní láti lò, ṣùgbọ́n kíkọ́ni lọ́nà tó gbéṣẹ́ ni kó o túbọ̀ tẹra mọ́ o.

Ìmọ̀ràn Nípa Ìgbékalẹ̀ Ọ̀rọ̀. Ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tó wà lójú ewé 82, kí o sì yan ọ̀kan tí o máa lè lò lọ́nà tó gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, èyí tí yóò jẹ́ kó o lè lo ìsọfúnni tó wà nínú iṣẹ́ rẹ lọ́nà tó wúlò. Bí o bá tiẹ̀ jẹ́ ẹni tó ti pẹ́ nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí, kà á sí àǹfààní kan láti sapá láti fi ní àfikún òye sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.

Bí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run bá yan ìgbékalẹ̀ kan pàtó fún ọ, gbìyànjú láti rí i pé ìyẹn náà lo múra sílẹ̀. Ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó pọ̀ jù lọ sábà máa ń jẹ mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Bí o kò bá tíì bá irú ipò tí wọ́n ṣàpèjúwe yẹn pàdé rí lóde ẹ̀rí, ṣèwádìí lọ́dọ̀ àwọn akéde tó ti bá irú ipò yẹn pàdé kí o fi lè mọ ohun tó o máa ṣe. Bí ó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ lórí kókó tí wọ́n yàn fún ọ yẹn nígbà tó o bá wà ní irú ipò tó bá ìgbékalẹ̀ tó o máa lò nílé ẹ̀kọ́ mú. Ìyẹn á jẹ́ kí o lè ṣe ọ̀kan nínú ohun pàtàkì tó o tìtorí ẹ̀ ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́.

Nígbà Tí Iṣẹ́ Rẹ Bá Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Tààràtà

Bí o bá jẹ́ ọkùnrin, wọ́n lè yan ọ̀rọ̀ ṣókí fún ọ láti sọ fún ìjọ. Bí o bá fẹ́ múra ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, àwọn ohun tó jẹ́ kókó pàtàkì tó yẹ kí o gbé yẹ̀ wò dà bí àwọn tí a ti mẹ́nu kàn tẹ́lẹ̀ nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí iṣẹ́ tiwọn jẹ mọ́ ṣíṣe àṣefihàn. Ìyàtọ̀ pàtàkì tó kàn wà níbẹ̀ ni pé àwùjọ tí wọ́n ti fẹ́ sọ̀rọ̀ yẹn àti ọ̀nà tí wọ́n máa gbà sọ ọ́ yàtọ̀ síra.

Ohun tó ti dára ni pé kó o múra ọ̀rọ̀ rẹ lọ́nà tí gbogbo ẹni tó bá wà nínú àwùjọ yóò fi lè jàǹfààní látinú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà nínú àwùjọ ló ti mọ àwọn ohun tó jẹ́ òtítọ́ ìpìlẹ̀ inú Bíbélì. Wọ́n lè ti mọ̀ dáadáa nípa kókó tí a yàn fún ọ láti sọ̀rọ̀ lé lórí. Ronú nípa ohun tí wọ́n ti mọ̀ nípa kókó tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀nà tí o gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀ mú kí wọ́n jàǹfààní nǹkan kan bó ti wù kó mọ. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè lo kókó ọ̀rọ̀ mi láti fi mú kí èmi àti àwùjọ tó ń gbọ́ mi túbọ̀ mọyì Jèhófà fúnra rẹ̀ lọ́nà tó jinlẹ̀ sí i? Kí ni àpilẹ̀kọ yẹn sọ tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí òye ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run? Báwo ni ìsọfúnni yìí yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó yè kooro nínú ayé kan tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ti gbòde?’ (Éfé. 2:3) Ó gba ìwádìí ṣíṣe kí o tó lè rí ìdáhùn tó tẹ́rùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Nígbà tó o bá lo Bíbélì, má fọ̀rọ̀ mọ sórí kíka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn nìkan. Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o lò, kí o sì fi bí wọ́n ṣe lani lóye hàn. (Ìṣe 17:2, 3) Má ṣe gbìyànjú láti kárí ohun tó pọ̀ jù. Sọ ọ̀rọ̀ rẹ lọ́nà tí yóò fi rọrùn fún àwọn èèyàn láti rántí wọn.

Nígbà tó o bá ń múra sílẹ̀, ronú nípa bó o ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú. Má fojú kékeré wò ó. Fi bí o ṣe máa sọ̀rọ̀ dánra wò, kí o sọ ọ́ síta. Akitiyan tó o bá ṣe nídìí kíkẹ́kọ̀ọ́ àti fífi ìmọ̀ràn tó o gbà lórí onírúurú ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ sílò, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú dáadáa. Yálà o jẹ́ ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ni o, tàbí o jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ tó ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí, máa múra sílẹ̀ dáadáa, kí o lè fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ kí o sì fi bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe yẹ kó rí gan-an lára hàn. Bí o ṣe ń ṣe iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tá a bá yàn fún ọ nílé ẹ̀kọ́, má ṣe gbàgbé pé ńṣe lo fẹ́ lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún ọ láti fi bọlá fún Jèhófà.—Sm. 150:6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́