Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Mú Wa Gbára Dì fún Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nígbèésí Ayé
1 Ohun tó ń mú káwọn èèyàn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ni láti lọ gba ìtọ́ni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ọwọ́ wọn lè tẹ àwọn ohun tí wọ́n ń lépa nígbèésí ayé. Àmọ́, kí lohun téèyàn lè máa lépa tó ṣe pàtàkì ju yíyin ẹni náà gan-an tó jẹ́ Olùfúnni ní ìyè, àti ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa àwọn ète rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà rẹ̀? Kò sí nǹkan náà. Ète tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run wà fún ni láti múra wa sílẹ̀ ká lè fi ìgbàgbọ́ wa kọ́ àwọn mìíràn. Nítorí náà, bá a ti ń wá sí ilé ẹ̀kọ́ náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, à ń jèrè òye tó ń mú wa gbára dì fún àwọn ìgbòkègbodò tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé.
2 “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2003” wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù tó kọjá. Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí a óò ṣe máa darí ilé ẹ̀kọ́ náà wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. O lè fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sínú ẹ̀dà ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tìrẹ, má sì gbàgbé pé o ní láti máa mú ìwé yìí wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Gbé àwọn apá díẹ̀ yẹ̀ wò nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run fún ọdún 2003.
3 Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù January, ìpàdé yìí yóò máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún, èyí tí yóò dá lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan tàbí kókó kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwé kíkà, ìkẹ́kọ̀ọ́, tàbí kíkọ́ni. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ni yóò bójú tó àwọn ìjíròrò tó máa wáyé níbẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ yìí tàbí kó yan alàgbà mìíràn tó tóótun láti sọ àsọyé náà. Olùbánisọ̀rọ̀ náà lè jíròrò ohun tí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ náà túmọ̀ sí àti bó ṣe ṣe pàtàkì tó. Lẹ́yìn náà ni yóò wá ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ náà dáadáa nípa jíjíròrò àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ àti jíjẹ́ kí àwùjọ mọ bí a ṣe lè lo ànímọ́ náà, àmọ́ ohun tí yóò tẹnu mọ́ ní pàtàkì ni bí ṣíṣe èyí ṣe lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i.
4 Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní: Lẹ́ẹ̀kan sí i, à ń gba àwọn arákùnrin tá a fún ní ọ̀rọ̀ ìtọ́ni nímọ̀ràn láti “pe àfiyèsí sí ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ tí à ń jíròrò náà.” Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n á jẹ́ kí àwọn ará rí bí wọ́n ṣe lè fi ìsọfúnni náà sílò. Bí a bá yan iṣẹ́ yìí fún ọ, wo ojú ìwé 48 àti 49 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn àbá lórí bó o ṣe lè múra sílẹ̀, kó o sì ṣàyẹ̀wò àwọn ibi tá a tọ́ka sí nínú atọ́ka ìwé náà lábẹ́ ìsọ̀rí “Bí a ṣe máa fi ọ̀rọ̀ sílò.”
5 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà: Ká ní láwọn àkókò tó ti kọjá, kò ṣeé ṣe fún ọ láti tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, o ò ṣe pinnu pé o ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí ọ lọ́wọ́ lọ́dún yìí? Tó bá fi máa di ìparí ọdún 2003, àwọn tó bá tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà á ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì dé ìparí. A jíròrò àwọn àǹfààní tó wà nínú bíbẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ojú ìwé 10, ìpínrọ̀ 4.
6 Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Bíbélì Kíkà: A ti mú kí àkókò tá a fi ń bójú tó apá yìí gùn sí i, ó ti di ìṣẹ́jú mẹ́wàá, kó lè ṣeé ṣe fún àwùjọ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn orí tá a yàn fún kíkà lọ́sẹ̀ náà. Àwọn tá a fún ní iṣẹ́ náà kò gbọ́dọ̀ lò ju àkókò tá a yàn fún wọn lọ. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la ó máa ṣe é, títí kan ọ̀sẹ̀ àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Bó o ti ń ka àwọn orí tá a yàn, máa wo àwọn kókó tí yóò ṣe yín láǹfààní nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, àti nínú ìgbésí ayé rẹ. Àwọn ànímọ́ Jèhófà wo ló fara hàn nínú ọ̀nà tó gbà bá àwọn èèyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè lò? Kí làwọn ohun tó o rí kọ́ tó mú ìgbàgbọ́ rẹ lágbára sí i tó sì mú kí ìmọrírì tó o ní fún Jèhófà pọ̀ sí i? Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí kókó èyíkéyìí tó o bá rí nínú àwọn orí tá a yàn fún kíkà, kódà nínú àwọn ẹsẹ tí a yàn fún Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì láti kà pàápàá, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé arákùnrin tó máa bójú tó Bíbélì kíkà náà kò ní sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ náà.
7 Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì: Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kíkàwé ní gbangba ni yóò máa jẹ́ iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kejì. Inú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la ó ti máa fa gbogbo iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kejì yọ àyàfi ìwé kíkà tó bá kẹ́yìn nínú oṣù kọ̀ọ̀kan. Inú Ilé Ìṣọ́ la ti máa mú ìwé kíkà tó bá kẹ́yìn nínú oṣù jáde. Kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ka ibi tí a yàn fún un láìṣe ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tàbí sọ ọ̀rọ̀ ìparí. Lọ́nà yìí, yóò lè pe àfiyèsí pàtàkì sórí bó ṣe mọ̀wèé kà dáadáa sí.—1 Tím. 4:13.
8 Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta àti Ẹ̀kẹrin: Àwọn kan lára iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí tá a mú látinú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lè ní ìsọfúnni tó gùn ju ara wọn lọ; ẹṣin ọ̀rọ̀ nìkan làwọn mìíràn ní. Àwọn tá a yan iṣẹ́ tí ìsọfúnni rẹ̀ kò tó nǹkan fún, tàbí tó jẹ́ pé kìkì ẹṣin ọ̀rọ̀ nìkan la fún wọn, yóò ní àǹfààní láti kó iṣẹ́ wọn jọ fúnra wọn nípa ṣíṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni. Èyí lè jẹ́ kó rọrùn fún àwọn arábìnrin láti mú kí àlàyé wọn bá olùrànlọ́wọ́ wọn mu.
9 Àwọn Ìgbékalẹ̀ Ọ̀rọ̀: Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ojú ìwé 45, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè yan ìgbékalẹ̀ kan fúnni. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn arábìnrin lè wá yan ìgbékalẹ̀ kan látinú àwọn tá a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 82. Bí arábìnrin kan bá ń ní iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan lóṣù méjì-méjì, yóò ṣeé ṣe fún un láti lo onírúurú ìgbékalẹ̀ ọgbọ̀n náà fún ọdún márùn-ún. Kí àwọn arábìnrin tó bá yàn láti lo ìgbékalẹ̀ tó jẹ́ nọnba 30, ìyẹn ni “Ìgbékalẹ̀ mìíràn tó bá àgbègbè rẹ mu,” kọ ìgbékalẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ ìwé pélébé tá a fi fún wọn níṣẹ́ (S-89) tàbí sí ẹ̀yìn rẹ̀. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò kọ déètì tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí ojú ìwé 82 nínú ìwé rẹ̀, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìgbékalẹ̀ tó lò. Ó lè ṣe èyí ní àkókò kan náà tó ń máàkì ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ akẹ́kọ̀ọ́ náà.
10 Ìwé Ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ rẹ ti wà nínú ìwé rẹ. Wàá rí i ní ojú ìwé 79 sí 81. Látàrí èyí, wàá ní láti máa fún alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ní ìwé rẹ lẹ́yìn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tó o bá ṣe. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ní láti máa ṣe àkọsílẹ̀ àwọn kókó ìmọ̀ràn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń ṣiṣẹ́ lé lórí.
11 Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ: Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ni a ó máa ṣe ní ọlọ́rọ̀-ẹnu. Ẹ̀ẹ̀kan láàárín oṣù méjì-méjì ni yóò máa wáyé, yóò sì jẹ́ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Àwọn ìbéèrè tí a óò gbé yẹ̀ wò á máa jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Bí ọ̀sẹ̀ tá a ṣètò fún àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ bá bọ́ sí ọ̀sẹ̀ àpéjọ àyíká tàbí ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, kí a ṣe ìpàdé ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e ní ọ̀sẹ̀ náà, kí á sì gbé àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ lọ sí ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e.
12 Àwọn Àfikún llé Ẹ̀kọ́: Ní àwọn ìjọ táwọn tó forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ bá ti ju àádọ́ta lọ, àwọn alàgbà lè ṣètò láti lo àwọn ilé ẹ̀kọ́ mìíràn láfikún. “A lè máa ṣe gbogbo iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ tàbí kó jẹ́ iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìkẹta àti ìkẹrin nìkan la ó máa ṣe níbẹ̀.” (Ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 285) Ìdí tá a fi mú àbá tó kẹ́yìn yìí wá jẹ́ nítorí ti àwọn ìjọ tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ arábìnrin àmọ́ tó jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn arákùnrin ni wọ́n ní láti bójú tó àwọn iṣẹ́ oníwèé kíkà. Kí àwọn alàgbà yan àwọn arákùnrin tó tóótun láti máa darí àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí.
13 Olùrànlọ́wọ́ Agbani-Nímọ̀ràn: Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yan olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn kan láti máa fún àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń bójú tó kókó pàtàkì látinú Bíbélì àti ọ̀rọ̀ ìtọ́ni ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́. Arákùnrin tí àwọn alàgbà yóò yàn láti ṣe èyí gbọ́dọ̀ jẹ́ onírìírí, ẹnì tí àwọn alàgbà yòókù yóò lè tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tó bá fún wọn. Ìmọ̀ràn rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó ń gbéni ró, kí ó gbóríyìn fún ọ̀nà dáradára tí wọ́n gbà sọ̀rọ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ni, kó sì sọ ọ̀nà kan tàbí méjì tí wọ́n lè gbà ṣe dáadáa sí i. Kò pọn dandan pé kó máa fún arákùnrin kan tó ń sọ̀rọ̀ déédéé nímọ̀ràn ní gbogbo ìgbà tó bá ti ṣiṣẹ́. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí arákùnrin tá a yàn láti gbani nímọ̀ràn náà máa lo òye, kó sì mọ̀ pé àwọn arákùnrin tó ti ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn báyìí pàápàá ni a lè ràn lọ́wọ́ láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú.—1 Tím. 4:15.
14 Ohun Tó Yẹ Láti Kíyè Sí: Kí ló lè ran agbani-nímọ̀ràn kan lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ kó kíyè sí nínú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan? Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orí mẹ́tàléláàádọ́ta tí wọ́n ní nọ́ńbà nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́, àpótí kẹta níbẹ̀ máa ń ní àkópọ̀ kúkúrú kan nípa ohun tí agbani-nímọ̀ràn kan ní láti máa kíyè sí. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ tún ní láti máa kíyè sí àwọn ìránnilétí tàbí àwọn àbá mìíràn nínú ìwé náà, èyí tí yóò ràn án lọ́wọ́ láti tètè mọ bí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe ṣètò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ àti bí ìgbékalẹ̀ náà ṣe gbéṣẹ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí àwọn ìbéèrè tó wà lókè ojú ìwé 55 àtàwọn èdè ìsọ̀rọ̀ tó wà ní ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn ní ojú ìwé 163.
15 Kọ Ọ̀rọ̀ Sínú Àwọn Àlàfo: Láfikún sí àwọn àyè fífẹ̀ tí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní léteetí, ó tún ní àwọn àlàfo bíi mélòó kan tí a kò kọ nǹkan kan sí, èyí tá a ṣe fún ọ láti kọ àwọn àlàyé tìrẹ sí, nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àti nígbà tó o bá wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Wo ojú ìwé 77, 92, 165, 243, 246 àti 250.) Rí i dájú pé ò ń mú ìwé rẹ lọ́wọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tí àsọyé àkọ́kọ́ tó dá lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ bá ń lọ lọ́wọ́, máa fọkàn bá a lọ. Jẹ́ kí ìwé rẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ títí di ìparí ilé ẹ̀kọ́. Máa fọkàn sí àwọn àbá tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà ń mú wá. Máa kíyè sí àwọn ọ̀nà táwọn olùbánisọ̀rọ̀ ń gbà kọ́ni, àwọn ìbéèrè, àwọn àpẹẹrẹ, àwọn àkànlò èdè, àwọn àpèjúwe, àti àwọn ohun tá a lè fojú rí tí wọ́n lò, àti bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn kókó ọ̀rọ̀. Nípa kíkọ àwọn àkọsílẹ̀ tó máa wúlò fún ọ, wàá lè máa rántí àwọn kókó alárinrin tó o kó jọ ní ilé ẹ̀kọ́ náà, wàá sì lè máa lò wọ́n.
16 Jésù Kristi mọ̀ pé wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni àǹfààní tó dára jù lọ tí a lè nawọ́ rẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. Iṣẹ́ tó dìídì wá ṣe nìyẹn. (Máàkù 1:38) Ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run . . . nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Bíi ti àwọn tó ti kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà láti tẹ̀ lé e, ọwọ́ àwa náà dí gan-an nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà, a sì ń tiraka nígbà gbogbo láti mú kí “ẹbọ ìyìn” wa túbọ̀ máa jẹ́ ojúlówó sí i. (Héb. 13:15) Kí ọwọ́ wa lè tẹ góńgó tá à ń lépa yìí, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò máa kópa déédéé nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ tó máa ṣèrànwọ́ láti múra wa sílẹ̀ fún ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé.