Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2015 Máa Jẹ́ Kí Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Kọ́ni Sunwọ̀n Sí I
1 Onísáàmù náà, Dáfídì sọ pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà Àpáta mi àti Olùtúnniràpadà mi.” (Sm. 19:14) Àwa náà fẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ wa máa dùn mọ́ Jèhófà nínú torí pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti máa sọ òtítọ́ nínú ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí máa ń wáyé láwọn ìjọ tó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́fà [111,000] lọ kárí ayé. Ilé ẹ̀kọ́ yìí ti ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n wá láti ibi tó yàtọ̀ síra kárí ayé lọ́wọ́ kí wọ́n lè di òjíṣẹ́ tó tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti wàásù ìhìn rere, kí wọ́n sì lè kọ́ni pẹ̀lú ìyíniléròpadà, ọgbọ́n inú àti ìgboyà.—Ìṣe 19:8; Kól. 4:6.
2 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ọdún 2015 yóò ní àwọn àkòrí tá a mú jáde látinú ìwé “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” àti ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí à ń fi sóde. Láfikún sí i, a ti ṣe àtúnṣe sí àkókò tí a ó máa fi bójú tó Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Bíbélì àti Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 1. Àwọn àyípadà tá a ṣe yìí àtàwọn ìtọ́ni tó dá lórí bí a ó ṣe máa bójú tó àwọn iṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ló wà láwọn ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé èyí.
3 Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Bíbélì: Àwọn arákùnrin tá a bá yan apá yìí fún máa lo ìṣẹ́jú méjì láti sọ̀rọ̀ lórí kókó kan tó gbádùn mọ́ni tó sì bá ipò àwọn ará mu látinú Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ yẹn. Bí àwọn arákùnrin tó máa bójú tó iṣẹ́ yìí bá múra sílẹ̀ dáadáa, wọ́n á lè mú kókó táá wúlò fún àwọn ará jáde láàárín àkókò tó yẹ kí wọ́n fi ṣe iṣẹ́ yìí. Lẹ́yìn náà, àwùjọ máa lo ìṣẹ́jú mẹ́fà láti sọ ẹ̀kọ́ tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n rí kọ́ nínú Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ náà, bí a ti máa ń ṣe láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ó gba pé ká máa múra sílẹ̀, ká sì jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa dáhùn lọ́nà tó nítumọ̀ láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tó dára la fi ń kọ́ra yẹn, èyí á sì tún fún àwọn ẹlòmíì láyè láti sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́ nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe.
4 Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 1: Àkókò tá a yàn fún Bíbélì kíkà ti dín kù sí ìṣẹ́jú mẹ́ta tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ó máa kà sì ti dín kù. Kí àwọn tí a bá yan iṣẹ́ Bíbélì kíkà fún rí i dájú pé àwọn fi dánra wò léraléra, kí wọ́n kà á sókè, kí wọ́n sì fún bí wọ́n ṣe máa pe ọ̀rọ̀ lọ́nà tó tọ́ àti lọ́nà tí ọ̀rọ̀ á fi yọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu láfiyèsí, kí ohun tí wọ́n bá kà lè yéni yékéyéké. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ipa pàtàkì ni ìwé kíkà ń kó nínú ìjọsìn wa, ó yẹ kí gbogbo àwa èèyàn Jèhófà máa sapá láti kàwé dáradára. Inú wa dùn gan-an pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ wa ló mọ̀wé kà dáadáa! A gbóríyìn fún àwọn òbí bí wọ́n ṣe ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́ kí wọ́n lè mọ ìwé kà dáadáa.
5 Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 2: Arábìnrin la ó máa yan iṣẹ́ ìṣẹ́jú márùn-ún yìí fún. Kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a bá yàn fún un. Tí iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí bá dá lórí ìwé Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe iṣẹ́ yìí lọ́nà tó bá ipò tí a sábàá máa ń bá pàdé lóde ẹ̀rí àti onírúurú ọ̀nà tá a gbà ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ mu. Bí a ò bá kọ ibi tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa láti lè mọ ohun tó máa sọ. Akẹ́kọ̀ọ́ lè lo àwọn àfikún ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa yan olùrànlọ́wọ́ kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.
6 Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 3: Arákùnrin tàbí arábìnrin la ó máa yan iṣẹ́ ìṣẹ́jú márùn-ún yìí fún. Bó bá jẹ́ arábìnrin ló máa bójú tó iṣẹ́ yìí, kó tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 2. Bí a bá yan iṣẹ́ yìí fún arákùnrin, kó sọ ọ́ bí àsọyé, kó sì darí rẹ̀ sí àwùjọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà fún iṣẹ́ yìí ni kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣiṣẹ́ lé lórí, kó sì yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá iṣẹ́ náà mu.
7 Ọ̀nà Tuntun Tí Àwọn Arákùnrin Yóò Máa Gbà Ṣe Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 3: Tá a bá yan iṣẹ́ fún arákùnrin kan látinú ìwé Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó ṣe é bí ìjọsìn ìdílé tàbí bí ẹni pé ó wà lóde ẹ̀rí. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ni yóò yan olùrànlọ́wọ́ àti ìgbékalẹ̀ fún akẹ́kọ̀ọ́ bó ti máa ń ṣe. Kí ẹni tó máa ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ jẹ́ ara ìdílé akẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí arákùnrin kan nínú ìjọ. Ó lè lo àwọn àfikún ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹnú mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì tó tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, a ó máa yan iṣẹ́ yìí fún àwọn alàgbà. Wọ́n lè yan olùrànlọ́wọ́ àti ìgbékalẹ̀ fúnra wọn. Ó dájú pé yóò fún àwọn ará níṣìírí tí wọ́n bá rí bí àwọn alàgbà ṣe ń gbé ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yọ nínú iṣẹ́ tí àwọn àti ẹnì kan nínú ìdílé wọn tàbí arákùnrin míì jọ ṣe.
Wàá tẹ̀ síwájú tó o bá ń gba ìmọ̀ràn, tí o sì ń fi í sílò
8 Ìmọ̀ràn: Lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa fi ìṣẹ́jú méjì gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́, kó sì sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró lórí ohun tó kíyè sí pé ó dára nínú iṣẹ́ náà àti ìdí tí iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà fi wúlò. Kó máa lo ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láti fi ti ohun tó ń sọ lẹ́yìn. Tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ bá ń ké sí akẹ́kọ̀ọ́ kan, ó máa sọ àkòrí tó fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí, àmọ́ kò ní sọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ń ṣiṣẹ́ lé lórí fún àwùjọ. Lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ látọkàn wá, ó máa sọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ń ṣiṣẹ́ lé lórí, ó sì máa sọ ní pàtó ìdí tí akẹ́kọ̀ọ́ náà fi ṣe dáadáa lórí kókó náà tàbí kó fọgbọ́n ṣàlàyé ìdí tí yóò fi dára kí akẹ́kọ̀ọ́ náà túbọ̀ ṣiṣẹ́ lórí ibi tó kù sí nígbà míì.
9 Ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ akẹ́kọ̀ọ́ wà ní ojú ìwé 79 sí 81 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò kọ ohun tó yẹ sínú ìwé ìmọ̀ràn akẹ́kọ̀ọ́ náà, yóò sì béèrè lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ìdákọ́ńkọ́ bóyá ó ti ṣe ìdánrawò tó tan mọ́ kókó ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ tó ṣiṣẹ́ lé lórí wà. Bí ìpàdé bá parí tàbí nígbà míì, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ náà, ó sì tún lè fún un láwọn àbá tó máa wúlò. Ó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan fọwọ́ pàtàkì mú àfiyèsí tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ bá fún un ní ilé ẹ̀kọ́, torí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—1 Tím. 4:15.
10 Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ tàbí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ wà lójúfò kí wọ́n lè ta akẹ́kọ̀ọ́ lólobó tí ó bá kọjá àkókò tá a yàn fún iṣẹ́ rẹ̀, irú bíi kí wọ́n tẹ aago tàbí kí wọ́n dọ́gbọ́n fún un ní àmì kan táá jẹ́ kó mọ̀ pé àkókò rẹ̀ ti pé. Tí akẹ́kọ̀ọ́ bá ti rí àmì náà tàbí tó gbọ́ tí aago dún, ńṣe ni kó parí gbólóhùn tó ń sọ lẹ́nu kí ó sì kúrò lórí pèpéle.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 282, ìpínrọ̀ 4.
11 A rọ gbogbo àwọn tó bá dójú ìlà àwọn ohun tí a béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ di akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ pé kí wọ́n lọ forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 282, ìpínrọ̀ 6.) Ẹ̀kọ́ tí àwa èèyàn Jèhófà ń kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí ti jẹ́ ká lè máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa kọ́ni tìfẹ́tìfẹ́ àti pẹ̀lú ìdánilójú. Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà ń dùn bí gbogbo àwọn tó ń jàǹfààní ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń yìn ín!—Sm. 148:12, 13; Aísá. 50:4.