Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 22
Orin 15 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 17 ìpínrọ̀ 17 sí 23, àpótí tó wà lójú ìwé 177 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 9-11 (10 min.)
No. 1: Jóṣúà 9:16-27 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọkọ Kò Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Kí Aya Dí Òun Lọ́wọ́ Sísin Ọlọ́run—td 6D (5 min.)
No. 3: Ó Yẹ Kí Àwọn Ọ̀rẹ́ Wa Fẹ́ràn Ọlọ́run—lr orí 44 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Máa Mú àwọn “ohun rere” jáde láti inú ìṣúra rere tá a fi sí ìkáwọ́ wa.—Mát. 12:35á.
5 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
25 min: “Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2015 Máa Jẹ́ Kí Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Kọ́ni Sunwọ̀n Sí I.” Ìjíròrò látẹnu alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè yàn láti ka àwọn ìpínrọ̀ kan kó tó jíròrò wọn. Tẹnu mọ́ àtúnṣe tó bá Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 1, àkókò tí a ó máa fi bójú tó Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Bíbélì àti ìmọ̀ràn látẹnu Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́. Ẹ ka ìpínrọ̀ 7, lẹ́yìn tí ẹ bá ti jíròrò rẹ̀, kí alàgbà kan ṣe àṣefihàn kan tó máa jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. Kí alàgbà náà lo ohun tó wà ní ojú ìwé 14 nínú ìwé Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí òun àti ìdílé rẹ̀ ṣe àṣefihàn yìí bí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n lo àǹfààní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó dára jù lọ tí ètò Ọlọ́run ń fún wa ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, kí wọ́n sì máa lo ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run dáradára.
Orin 117 àti Àdúrà