ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ojú ìwé 282-ojú ìwé 285
  • Ìlànà Fún Àwọn Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìlànà Fún Àwọn Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2015 Máa Jẹ́ Kí Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Kọ́ni Sunwọ̀n Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Mú Wa Gbára Dì fún Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nígbèésí Ayé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìtọ́ni fún Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
    Ìtọ́ni Tó Wà fún Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
  • Fiyè Sí “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ojú ìwé 282-ojú ìwé 285

Ìlànà Fún Àwọn Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́

ALÀGBÀ kan ni a máa ń yàn ṣe alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. Bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni a gbé ẹrù iṣẹ́ yìí lé lọ́wọ́, ìtara rẹ fún ilé ẹ̀kọ́ yìí àti bí o ṣe fúnra rẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìtẹ̀síwájú akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò kó ipa pàtàkì nínú bí ilé ẹ̀kọ́ yìí yóò ṣe ṣàṣeyọrí tó nínú ìjọ yín.

Lára ohun pàtàkì tó jẹ́ iṣẹ́ rẹ ni pé kí o máa darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú ìjọ yín. Má gbàgbé pé yàtọ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a bá yan iṣẹ́ fún nílé ẹ̀kọ́, àwùjọ tún máa ń wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Darí ilé ẹ̀kọ́ náà lọ́nà tí gbogbo ìjọ yóò fi lè gba ìránnilétí tó tani jí, tó wúlò tó sì jẹ mọ́, ó kéré tán, ọ̀kan nínú ohun tí ilé ẹ̀kọ́ yìí wà fún, tí a mẹ́nu kàn ní ojú ewé karùn-ún sí ìkẹjọ nínú ìwé ilé ẹ̀kọ́ yìí.

Ní ìfẹ́ sí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́, yálà èyí tí a yan iṣẹ́ ìwé kíkà fún, èyí tó máa ṣe iṣẹ́ tó jẹ mọ́ àṣefihàn, tàbí èyí tó máa sọ ọ̀rọ̀ tààràtà. Mú kí wọ́n máa fi ojú ribiribi wo iṣẹ́ tí a yàn fún wọn pé kì í ṣe iṣẹ́ kan lásán, ṣùgbọ́n kí wọ́n kà á sí àǹfààní kan tí wọ́n á fi lè tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà. Ohun tó dájú ni pé, ìsapá tiwọn fúnra wọn jẹ́ ọ̀kan lára ohun pàtàkì tí yóò mú kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú. Ṣùgbọ́n ó tún ṣe pàtàkì bákan náà pé kí o fi inúure nífẹ̀ẹ́ sí wọn, kí o mú kí wọ́n rí àǹfààní ìmọ̀ràn tí o bá fún wọn, kí o sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè lo irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Láti lè ṣe ìyẹn láṣeyọrí, ńṣe ni kó o tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí iṣẹ́ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò ṣe kí o lè ráyè pe àfiyèsí wọn sí ohun pàtàkì tí wọ́n lè ṣe láti tẹ̀ síwájú.

Rí i dájú pé o bẹ̀rẹ̀, o sì parí ilé ẹ̀kọ́ lásìkò. Fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa fífi ọ̀rọ̀ àkíyèsí rẹ mọ sáàárín àkókò tí a yàn fún un. Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá jẹ àkókò, kí ìwọ tàbí ẹni kan tí ń ràn ọ́ lọ́wọ́ fi àmì hàn án pé àkókò ti pé. Kí akẹ́kọ̀ọ́ parí gbólóhùn tó ń sọ lẹ́nu kí ó sì kúrò lórí pèpéle. Bí ẹni tó ń ṣe apá mìíràn nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn bá jẹ àkókò, kí ìwọ ké ọ̀rọ̀ àkíyèsí tìrẹ kúrú, lẹ́yìn ìpàdé kí o wá bá arákùnrin yẹn sọ̀rọ̀.

Bí o bá wà nípàdé, ìwọ ni kó darí ilé ẹ̀kọ́. Bí ó bá wá ṣẹlẹ̀ pé o kò ní wà níbẹ̀, kí alàgbà mìíràn tí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ti yàn tẹ́lẹ̀ bójú tó ilé ẹ̀kọ́ yẹn. Bí o bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ nínú ṣíṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ, kíkọ ìwé ìyanṣẹ́fúnni àti pípín in fúnni, tàbí wíwá ẹni tí yóò rọ́pò ẹni tó yẹ kó kópa nínú ilé ẹ̀kọ́, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yàn lè máa bá ọ ṣe nǹkan wọ̀nyẹn.

Gbígba Akẹ́kọ̀ọ́ Sílé Ẹ̀kọ́. Gba gbogbo akéde níyànjú láti forúkọ sílẹ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí. Àwọn yòókù tó bá ń dára pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé lè forúkọ sílẹ̀ bí wọ́n bá fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí Bíbélì ń kọ́ni tí wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristẹni. Bí ẹnì kan bá sọ pé òun fẹ́ forúkọ sílẹ̀, yìn ín dáadáa. Bí onítọ̀hún ò bá tíì di akéde, kí ìwọ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ní láti ṣe kí o tó lè forúkọ sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́, ó sì dára kí o bá a sọ̀rọ̀ yẹn níṣojú ẹni tó ń bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ (tàbí níṣojú òbí rẹ̀ tó jẹ́ onígbàgbọ́). Àwọn ohun kan náà tí à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi là ń béèrè lọ́wọ́ òun náà. Wọ́n wà lójú ewé 97 sí 99 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa. Rí i pé àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn tó wà nínú ilé ẹ̀kọ́ tí o ní lọ́wọ́ jẹ́ orúkọ àwọn tó wà níbẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́.

Lílo Ìwé Ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Sísọ. Ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ ti akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan wà nínú ìwé ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, lójú ewé 79 sí 81. Bí onírúurú àwọ̀ ibẹ̀ ṣe fi hàn, èyíkéyìí nínú kókó ìmọ̀ràn tó bẹ̀rẹ̀ láti 1 sí 17 ni a lè lò nígbà tí a bá yan iṣẹ́ ìwé kíkà fún akẹ́kọ̀ọ́ kan. Ní ti iṣẹ́ tó jẹ mọ́ àṣefihàn, a lé lo kókó ìmọ̀ràn èyíkéyìí yàtọ̀ sí 7, 52 àti 53. Tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ tààràtà ni, kókó ìmọ̀ràn èyíkéyìí ni a lè lò yàtọ̀ sí ti 7, 18 àti 30.

Bí a bá wá yan kókó ìmọ̀ràn kan fún akẹ́kọ̀ọ́, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ tàbí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ fi pẹ́ńsù kọ déètì sí àyè tí a ṣe sí ẹ̀gbẹ́ kókó yẹn lábẹ́ “Ọjọ́ Tí A Yàn Án fún Ọ” nínú ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ tó wà nínú ìwé akẹ́kọ̀ọ́. Bí akẹ́kọ̀ọ́ bá ti ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un tán, bi í léèrè ní ìdákọ́ńkọ́ bóyá ó ṣe ìdánrawò tó wà nísàlẹ̀ ibi tí a ti ṣàlàyé kókó ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ yẹn. Bí ó bá ti ṣe é, kí o fi àmì ó-gbà-á sínú àpótí tó wà nínú ìwé ìmọ̀ràn yẹn. Bí o bá máa dámọ̀ràn pé kí ó ṣì ṣiṣẹ́ lórí kókó ìmọ̀ràn kan náà, kò sídìí láti kọ àfikún àkíyèsí sínú ìwé ìmọ̀ràn yẹn; ńṣe ni kó o má wulẹ̀ kọ nǹkan kan síbi àyè “Ọjọ́ Tí O Yege.” Ìgbà tí ó bá tó ṣe tán láti kọjá sórí kókó mìíràn nìkan ni kí o tó fi àmì síbẹ̀. Láfikún sí i, tí akẹ́kọ̀ọ́ bá ti parí iṣẹ́ rẹ̀ kí á kọ ọjọ́ tó lo ìgbékalẹ̀ kan sí ojú ewé 82 nínú ìwé ti akẹ́kọ̀ọ́, ní apá òsì ibi tí ìgbékalẹ̀ tí akẹ́kọ̀ọ́ lò wà. Àyè tó wà nínú ìwé ìmọ̀ràn àti nínú ibi tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbékalẹ̀ wà yọ̀ǹda fún akẹ́kọ̀ọ́ láti lo kókó kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀mejì. Kí ìwé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wà lọ́dọ̀ wọn nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ.

Kókó ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ kan ṣoṣo ni kí o yàn fúnni lẹ́ẹ̀kan. Lóòótọ́, ohun tó sábà máa ń dára jù ni pé kí á máa yan kókó ìmọ̀ràn fúnni bí a ṣe tò wọ́n tẹ̀ léra. Ṣùgbọ́n, bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ń ṣe dáadáa lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, o lè gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ka àwọn ẹ̀kọ́ kan ní pàtó kí wọ́n sì fi wọ́n sílò láyè ara wọn. Kí o wá yan iṣẹ́ fún wọn lórí àwọn kókó tí o gbà pé yóò túbọ̀ jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ tẹ̀ síwájú nínú dídi sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti olùkọ́ni tó dá-ń-tọ́.

Kódà bí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá tiẹ̀ ti wà nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí láti ọdún tó ti pẹ́, ó ṣì lè jàǹfààní dáadáa látinú kíkọ́ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan kí ó sì fi í sílò. Tí o bá fẹ́ ran akẹ́kọ̀ọ́ tó nílò ìrànlọ́wọ́ níhà kan pàtó lọ́wọ́, o lè yan àwọn ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan pàtó fún wọn láti ṣiṣẹ́ lé lórí dípò kí o kàn ṣáà máa yan kókó ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn bí a ṣe tò wọ́n tẹ̀ léra.

Bí O Ṣe Máa Fúnni Nímọ̀ràn. Nígbà tí o bá ń fúnni nímọ̀ràn, máa lo àwọn àpẹẹrẹ àti ìlànà inú Bíbélì dáadáa. Ó yẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rí òye pé àwọn ìlànà gíga tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń darí ìmọ̀ràn tó ò ń fún àwọn àti ọ̀nà tó o gbà ń fún wọn.

Má gbàgbé pé “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” ni ìwọ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ jọ jẹ́. (2 Kọ́r. 1:24) Nítorí náà, ìwọ pẹ̀lú ní láti máa sapá láti tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ àti olùkọ́ni bí àwọn pẹ̀lú ṣe ń sapá. Kí ìwọ fúnra rẹ fara balẹ̀ ka ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, kí o fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò, kí o sì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn èèyàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

Bí o ṣe ń ṣe èyí, máa lépa bí o ṣe máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti dẹni tó ń kàwé geerege, láti di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dá-ń-tọ́ àti olùkọ́ni tó gbó ṣáṣá. Láti lè ṣe èyí, gbìyànjú láti ṣe ìrànlọ́wọ́ tó bá yẹ, kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè lóye ohun tí onírúurú ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ wọ̀nyí jẹ́ àti ìdí tí wọ́n fi ṣe pàtàkì àti bí wọ́n ṣe lè dẹni tó mọ̀ wọ́n lò. A ṣe ìwé yìí lọ́nà tí yóò jẹ́ kí o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ohun tó o máa ṣe yóò ju pé kí o kàn ka ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí jáde nìkan. Ńṣe ni kí o ṣàlàyé kókó tí ìwé yìí ń sọ àti bí a ṣe lè fi kókó yẹn sílò.

Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ṣe dáadáa lórí kókó kan, yìn ín. Ní ṣókí, sọ ìdí tí ohun tó ṣe fi múná dóko àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Bí ohun kan bá ṣì kù tó yẹ kó túbọ̀ kíyè sí, rí i dájú pé o jẹ́ kó mọ ìdí tó fi yẹ kí ó ṣe nǹkan náà. Ṣàlàyé bí yóò ṣe ṣe é. Sọ ojú abẹ níkòó, síbẹ̀ sọ ọ́ lọ́nà onínúure.

Mọ̀ dájú pé ìṣòro ńlá ló jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn pé kí wọ́n dìde láti máa sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. Bí ẹnì kan bá ń rò ó pé òun kò ṣe dáadáa, ó lè máa ronú pé bóyá lòun á tún gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ mọ́. Ṣe bíi ti Jésù, ẹni tí kò tẹ “esùsú kankan tí a ti pa lára” fọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò fẹ́ “òwú àtùpà kankan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú” pa. (Mát. 12:20) Gba bọ́ràn ṣe máa ń rí lára akẹ́kọ̀ọ́ náà rò. Nígbà tí o bá ń fún akẹ́kọ̀ọ́ nímọ̀ràn, ohun tó o máa wò mọ́ ọn lára ni bóyá ẹni tuntun ló jẹ́ tàbí ó jẹ́ akéde tó ti nírìírí. Yinni yinni kẹ́ni ṣèmíì ni wọ́n máa ń wí o, bí a bá fi tọkàntọkàn yin àwọn èèyàn dáadáa, ìyẹn lè mú kí wọ́n máa bá a lọ láti sa gbogbo ipá wọn.

Buyì kún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀nà tí ò ń gbà bá wọn lò. Róòmù 12:10 sọ fún wa pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” Ìmọ̀ràn yìí mà dára púpọ̀ fún agbani-nímọ̀ràn nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run o! Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá dàgbà jù ọ́ lọ, fara balẹ̀ lo ìtọ́ni tó wà ní 1 Tímótì 5:1, 2. Ṣùgbọ́n bí ọjọ́ orí ẹnì kan ṣe wù kó jẹ́, bí a bá fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún onítọ̀hún nímọ̀ràn nípa bí yóò ṣe ṣàtúnṣe nínú ọ̀nà tó ń gbà ṣe àwọn nǹkan, ó sábà máa ń rọrùn láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn ọ̀hún.—Òwe 25:11.

Nígbà tí o bá ń fún akẹ́kọ̀ọ́ nímọ̀ràn, tẹnu mọ́ ète tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yẹn wà fún. Ète yẹn kì í ṣe pé kéèyàn ṣáà ti ṣe dáadáa lórí kókó kan kí a lè yìn ín kí á sì wá sọ fún un pé kí ó bọ́ sórí kókó ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ mìíràn. Ète rẹ̀ kì í ṣe pé kéèyàn di olùbánisọ̀rọ̀ àti olùkọ́ni tí àwọn èèyàn yóò máa kan sárá sí. (Òwe 25:27) Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé ká lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tá a ní láti fi yin Jèhófà ká sì fi ran ọmọnìkejì wa lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà kí ó sì fẹ́ràn rẹ̀. Ohun tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí à ń gbà wà fún ni pé kí ó múra wa sílẹ̀ kí á lè ṣe iṣẹ́ tí Mátíù 24:14 àti 28:19, 20 sọ yanjú. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn tó bá tóótun nínú àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi lè wá dẹni tí a ó sọ pé kó wá máa bójú tó “agbo Ọlọ́run” nípa dídi ẹni tó ń sọ àsọyé àti ẹni tó ń kọ́ àwùjọ.—1 Pét. 5:2, 3.

Gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nímọ̀ràn pé láàárín ọjọ́ mélòó kan sígbà tí a bá yan kókó ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ tó kàn tí wọ́n máa ṣiṣẹ́ lé lórí fún wọn, kí wọ́n ka ibi tí ìwé ilé ẹ̀kọ́ wọn ti sọ̀rọ̀ lórí kókó náà. Rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò nígbà tí wọ́n bá ń múra iṣẹ́ wọn fún ilé ẹ̀kọ́, nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn ojoojúmọ́, nígbà tí wọ́n bá ń dáhùn nípàdé àti nígbà tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí.

Yíyan Iṣẹ́ Fúnni. Ó yẹ kí á ti ṣe èyí ó kéré tán ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ṣáájú àkókò. Tó bá ṣeé ṣe, kí á kọ iṣẹ́ tí a bá yàn fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan síwèé kí á sì fi fún un.

Àwọn alàgbà ni kí á yan apá tó bá jẹ mọ́ fífún ìjọ ní ìtọ́ni fún, ó sì dára kó jẹ́ àwọn tó máa lè bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó múná dóko, tàbí kí á yàn án fún ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ bí a ṣe ń kọ́ni dáadáa.

Láti mọ irú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó yẹ kí o yàn fún àwọn arákùnrin tàbí èyí tó yẹ kí o yàn fún arábìnrin, tẹ̀ lé ohun tí ìtọ́ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ bá wí. Bí àwọn arákùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kò bá fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, tí àwọn arábìnrin sì pọ̀ tó ń ṣe é, rí i pé ò ń fún àwọn arákùnrin láyè tó láti ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìwé kíkà.

Ronú nípa ipò tó yí ẹnì kọ̀ọ̀kan ká nígbà tí o bá ń yan iṣẹ́ fúnni. Ǹjẹ́ ohun tó o lè ṣe wà kí àwọn alàgbà kan tàbí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan má ṣe níṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan náà tí wọ́n bá níṣẹ́ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tàbí ní ọ̀sẹ̀ kan náà tí wọ́n máa sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn nínú ìjọ? Ǹjẹ́ ó lóhun tó o lè ṣe tó ò fi ní yanṣẹ́ fún arábìnrin kan láti ṣe ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan náà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ kékeré níṣẹ́, tó sì lè jẹ́ pé òun ló máa ràn án lọ́wọ́ láti múra iṣẹ́ yẹn? Ṣé kókó ọ̀rọ̀ tó yẹ ẹnì kan lo yàn fún un, pàápàá àwọn ọmọdé tàbí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí kò tíì ṣe ìrìbọmi? Ṣàyẹ̀wò láti rí i dájú pé iṣẹ́ tí o yàn yìí ṣeé fi ṣiṣẹ́ lórí kókó ìmọ̀ràn tónítọ̀hún ń ṣiṣẹ́ lé lórí.

Ní ti iṣẹ́ tí a ó yàn fún àwọn arábìnrin, àwọn fúnra wọn ni yóò yan irú ìgbékalẹ̀ tí wọn yóò lò níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tó wà lójú ewé 78 àti 82. Kí á yan olùrànlọ́wọ́ kan fún un, ṣùgbọ́n ó lè fi olùrànlọ́wọ́ mìíràn kún un. Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá lóun ń fẹ́ olùrànlọ́wọ́ kan tí yóò lè bá òun gbé irú ìgbékalẹ̀ kan pàtó yọ, kò sóhun tó burú nínú kí o gba tirẹ̀ rò.

Ilé Ẹ̀kọ́ Kejì. Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó forúkọ sílẹ̀ bá ju àádọ́ta lọ, o lè lo ibòmíràn láfikún gẹ́gẹ́ bí ilé ẹ̀kọ́ kejì, kí wọ́n lè máa ṣe àwọn apá tó jẹ́ iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀. A lè máa ṣe gbogbo iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ tàbí kó jẹ́ iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìkẹta àti ìkẹrin nìkan la ó máa ṣe níbẹ̀, ó sinmi lórí bí ipò inú ìjọ bá ṣe gbà.

Ilé ẹ̀kọ́ kejì ní láti ní agbani-nímọ̀ràn kan tó tóótun, ó dára kí ó jẹ́ alàgbà. Níbi tó bá ti pọn dandan a lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá tóótun níbẹ̀. Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ní láti fọwọ́ sí àwọn agbani-nímọ̀ràn tí a bá yàn wọ̀nyí. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbani-nímọ̀ràn yìí kí ó bàa lè jẹ́ pé ohun tá a ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣiṣẹ́ lé lórí ni wọ́n ṣiṣẹ́ lé láìka ibi yòówù tí wọ́n ti máa ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wọn sí.

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìwé Kíkà Àkànṣe. Bí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà bá rí i pé àwọn kan nínú ìjọ nílò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwé kíkà ní èdè tí à ń lò nínú ìjọ, o lè ṣètò fún èyí ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń wí yìí lè dá lórí kí wọ́n mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà tàbí kó dá lórí pé kí wọ́n túbọ̀ mọ ìwé kà lọ́nà tó já gaara.

Kò pọn dandan kí á máa ṣe èyí lásìkò kan náà tí à ń ṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Láti lè ṣèrànwọ́ fún wọn bó ṣe yẹ, ó lè gba àkókò ju ìwọ̀nba èyí tí a máa rí lò lásìkò tí ilé ẹ̀kọ́ ń lọ lọ́wọ́. Kí àwọn alàgbà ìjọ pinnu ohun tó yẹ ní ṣíṣe àti ìgbà tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yóò máa wáyé. Kí wọ́n ṣètò pé kí á máa kọ́ wọn pa pọ̀ tàbí kí á máa kọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, èyí sinmi lórí ohun tó bá ń fẹ́ àbójútó níbẹ̀.

Olùkọ́ tó tóótun ni kí ẹ lò. Ó dára kó jẹ́ pé arákùnrin tó mọ̀wèé kà dáadáa tó sì mọ èdè yẹn dunjú ni kí ẹ yàn kó ṣe iṣẹ́ yẹn. Bí kò bá sí arákùnrin kankan, àwọn alàgbà lè ní kí arábìnrin kan tó tóótun, tó sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere ṣèrànwọ́. Kí arábìnrin yẹn lo ìbòrí nígbà tí ó bá ń kọ́ wọn.—1 Kọ́r. 11:3-10; 1 Tím. 2:11, 12.

Ní Nàìjíríà, ìwé kékeré náà, How to Read and Write, ni a tẹ̀ jáde fún lílò lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ńṣe ni a pilẹ̀ ṣe àwọn ìwé yìí fún kíkọ́ni láti mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. A tún lè lo àwọn ohun èlò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn pẹ̀lú, ó sinmi lórí bí àwọn tó wá forúkọ sílẹ̀ níbẹ̀ ṣe mọ ìwé kà sí. Bí akẹ́kọ̀ọ́ bá ti tẹ̀ síwájú dáadáa, kí á gbà á níyànjú láti máa kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nínú ìjọ.

Bí o ti jẹ́ alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àǹfààní púpọ̀ ni ìjọ lè rí jẹ látọ̀dọ̀ rẹ. Múra sílẹ̀ dáadáa, kí o sì bójú tó iṣẹ́ tí a yàn fún ọ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun iyebíye tí Ọlọ́run gbé lé ọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn inú Róòmù 12:6-8 ti wí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́