Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 29
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 29
Orin 37 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 18 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 12-15 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Máa Mú àwọn “ohun rere” jáde láti inú ìṣúra rere tá a fi sí ìkáwọ́ wa.—Mát. 12:35á.
20 min: Máa Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Àtàwọn Ọmọ Rẹ Ní “Àwọn Ohun Rere.” (Mát. 12:35á) Ìjíròrò. Fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí a retí pé kí àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ọmọ wa ṣe: 1 Kọ́ríńtì 13:11; 1 Pétérù 2:2, 3. Ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti “tọ́” “wàrà . . . ọ̀rọ̀ náà” wò àti bí a ṣe lè ran àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣàlàyé ìlànà tó wà ní Máàkù 4:28. (Wo Ilé Ìṣọ́, December 15, 2014, ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 6 sí 8.) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó nírìírí tàbí òbí kan. Ní kí akéde náà sọ bó ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ tàbí ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Éfé. 4:13-15; wo Àpótí Ìbéèrè inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2014.
10 min: “Máa Ṣe Àjọpín ‘Àwọn Ohun Rere’ Nípa Ṣíṣe Aájò Àlejò (Mát. 12:35á).” Ìjíròrò. Àwọn àǹfààní tàbí ìrírí wo làwọn kan ti ní torí pé wọ́n ní ẹ̀mí aájò àlejò? Ní kí àwọn ará sọ bí a ṣe lè fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn ẹlòmíì, ní pàtàkì sí àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Sọ ètò tí ìjọ ti ṣe láti pèsè oúnjẹ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá.
Orin 124 àti Àdúrà