Máa Ṣe Àjọpín “Àwọn Ohun Rere” Nípa Ṣíṣe Aájò Àlejò (Mát. 12:35a)
Ó dájú pé gbogbo wa la fẹ́ máa ṣe àjọpín “àwọn ohun rere” pẹ̀lú àwọn èèyàn torí pé à ń tẹ̀ lé “ipa ọ̀nà aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) Àwọn alàgbà ń mú ipò iwájú nínú gbígba àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá lálejò àti bíbójú tó ìnáwó ìrìn-àjò wọn. Àmọ́, ó ṣeé ṣé ká máa lọ́ tìkọ̀ láti fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn torí pé a kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan lọ́wọ́ tàbí kí àyà wa máa já pé a ò tó ẹni tó lè gba àwọn ẹlòmíì lálejò. Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn tí Jésù fún Màtá sọ́kàn, àá lè borí irú èrò bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 10:39-42) Jésù tẹnu mọ́ ọn pé ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àti ìṣírí ni “ìpín rere” tó máa ń wáyé téèyàn bá ṣàlejò kì í ṣe àsè rẹpẹtẹ tàbí ṣíṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́. Tí gbogbo wa bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò, a ó lè máa ṣe àjọpín “àwọn ohun rere” pẹ̀lú àwọn ara wa níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ.—3 Jòh. 5-8.