ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/03 ojú ìwé 6
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2004

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2004
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Mú Wa Gbára Dì fún Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nígbèésí Ayé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣèpàdé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìtọ́ni fún Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
    Ìtọ́ni Tó Wà fún Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
  • Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká àti Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 12/03 ojú ìwé 6

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2004

1 Jèhófà ń mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn lásánlàsàn láti ṣe iṣẹ́ kan tó ṣe pàtàkì jákèjádò ayé. Ọ̀nà kan tó ń gbà ṣe èyí jẹ́ nípasẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí à ń gbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ṣé ò ń kópa ní kíkún débi tí ipò rẹ yọ̀ǹda fún ọ dé? Ní oṣù January, àwọn ìyípadà díẹ̀ yóò wáyé láti lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ jàǹfààní sí i látinú àwọn ìṣètò yìí.

2 Lílo Àwọn Arákùnrin Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Olùrànlọ́wọ́ Agbani-nímọ̀ràn: Àwọn arákùnrin tí wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìtọ́ni àti kókó pàtàkì látinú Bíbélì mọrírì àwọn àkíyèsí tí olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn máa ń pe àfiyèsí wọn sí. Ní àwọn ìjọ tí àwọn alàgbà tó dáńgájíá tó pọ̀ tó bá wà, a lè máa lo àwọn arákùnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn lọ́dọọdún. Lọ́nà yìí, iṣẹ́ náà á lè di èyí tí à ń pín ṣe; àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé, àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun yóò jàǹfààní látinú ìrírí ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àtàwọn olùkọ́ tó dáńgájíá.

3 Ṣíṣètò Àkókò Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ: Bí àpéjọ àyíká ìjọ yín bá bọ́ sí ọ̀sẹ̀ àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ, nígbà náà kí a sún àtúnyẹ̀wò náà (àti ìyókù ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sẹ̀ náà) sí ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé àpéjọ àyíká, kí a sì gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọ̀sẹ̀ náà wá sí ọ̀sẹ̀ ìpàdé àyíká. Àmọ́ ṣá o, bó bá jẹ́ pé ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká ni àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ náà bọ́ sí, kò pọn dandan ká gbé gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sẹ̀ méjèèjì náà fúnra wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí a lo orin, ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àtàwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣètò rẹ̀. Kí a wá mú ọ̀rọ̀ ìtọ́ni (èyí tí a máa ń sọ lẹ́yìn ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ) látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú ni yóò tẹ̀ lé àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì. A lè ṣe ìyípadà nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn náà kó lè ṣeé ṣe láti ní yálà apá oníṣẹ̀ẹ́jú-mẹ́wàá mẹ́ta tàbí apá oníṣẹ̀ẹ́jú-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún méjì. (Kí a mú àwọn ìfilọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ kúrò.) Orin àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú látẹnu alábòójútó àyíká ni yóò tẹ̀ lé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn náà. Ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, a ó sọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àtàwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí a ti ṣètò rẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ yẹn, lẹ́yìn náà ni àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ yóò wá tẹ̀ lé e.

4 Máa ṣàmúlò àǹfààní kọ̀ọ̀kan tó o ní láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Bó o ti ń jàǹfààní látinú ìmọ̀ tóò ń rí gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ò ń fún ìjọ rẹ níṣìírí, ò ń kópa nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, o sì ń mú ìyìn wá fún Ẹni tó ni ìhìn àgbàyanu tí a gbọ́dọ̀ polongo náà.—Aísá. 32:3, 4; Ìṣí. 9:19.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́