Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká àti Àkànṣe
Bí ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí ṣe ń burú sí i, Jèhófà ń fún wa lókun “láti kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Títù 2:12) Àpéjọ àyíká àti àkànṣe tá à ń ṣe lọ́dọọdún jẹ́ ara àwọn ètò tí Jèhófà ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣe láti fi ràn wá lọ́wọ́. (Mát. 24:45) Láìsí àní-àní, àwọn àpéjọ yìí ń fún wa lókun gan-an!
Lọ́dún 2005, ọ̀nà tuntun la ó gbà ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ wa ká bàa lè máa rántí àwọn ohun tá a gbọ́ ká sì lè fi wọ́n sílò. Àwọn àpilẹ̀kọ kan wà ní ojú ìwé karùn-ún àti ìkẹfà àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Wọ́n á jẹ́ ká rí àpẹẹrẹ àwọn ohun tá a máa lọ gbádùn láwọn àpéjọ wọ̀nyí àti àwọn ìbéèrè tá a máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ohun tá a bá gbọ́ ní àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Kí ìjọ kọ̀ọ̀kan gbé ohun tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí yẹ̀ wò ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn nígbà tó bá kù díẹ̀ kí wọ́n lọ sí àwọn àpéjọ wọn àti kété lẹ́yìn tí wọ́n bá dé. Báwo ni wọ́n ṣe máa ṣe èyí?
Ní ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì ṣáájú kí ìjọ tó lọ sí àpéjọ àyíká, a ó sọ ọ̀rọ̀ ìṣẹ́jú mẹ́wàá lórí àpilẹ̀kọ náà, “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun” ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, láti fi mú kí àwọn ará máa wọ̀nà fún ohun tí wọ́n máa lọ gbádùn níbẹ̀. Ẹni tó máa sọ̀rọ̀ yìí yóò mẹ́nu kan àwọn ìbéèrè tá a máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tá a bá dé láti àpéjọ náà, yóò sì rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ láti fi múra sílẹ̀ fún àtúnyẹ̀wò náà.
Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn àpéjọ yìí, a óò lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ohun tá a gbọ́ ní ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà. Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé èyí, a óò tún lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ohun tá a gbọ́ ní ọjọ́ kejì àpéjọ yìí. Àwọn ìbéèrè tó wà nínú àkìbọnú yìí la máa lò fún àtúnyẹ̀wò yìí. Kí a ṣe àtúnyẹ̀wò náà lọ́nà tí ìjọ yóò fi rí àwọn kókó pàtàkì tí wọ́n lè fi sílò. Kí ìjọ bàa lè rí àyè ṣe àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ yìí, àwọn alàgbà lè ṣètò pé kí á dín àkókò tí a máa lò lórí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kù, tàbí kí á bójú tó wọn nígbà mìíràn, tàbí kẹ̀, kí á kúkú mú wọn kúrò.
Ìlànà yìí kan náà la máa lò fún àpéjọ àkànṣe, ó kàn jẹ́ pé ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò gbogbo ohun tá a gbádùn ní àpéjọ náà. Ó yẹ kí gbogbo wa tọ́jú àkìbọnú yìí, ká sì máa lò ó ká bàa lè jàǹfààní gan-an látinú ìtọ́ni dáradára tí Jèhófà ń pèsè.—Aísá. 48:17, 18.