‘Oúnjẹ Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu’
1. Báwo ni àwọn àpéjọ àkànṣe tá a ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí ṣe ran ìwọ àtàwọn míì lọ́wọ́?
1 Lẹ́yìn tá a bá dé láti àpéjọ àkànṣe, a sábà máa ń sọ pé, “Àwọn ọ̀rọ̀ tá a gbọ́ ní àpéjọ yẹn bọ́ sákòókò gan-an ni!” Alábòójútó àyíká kan sọ pé lẹ́yìn tí àwọn ará kan ní àyíká òun gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe, wọ́n sọ pé àwọn máa mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn gbòòrò sí i. Alábòójútó arìnrìn-àjò míì sọ pé: “Ó ràn wá lọ́wọ́ láti ronú lórí bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó bá a ṣe ń ronú lórí ohun tá a pinnu láti fi ìgbésí ayé wa ṣe.” Ẹlòmíì sọ pé, “Ọ̀pọ̀ àkéde ló sọ pé àpéjọ yìí ti rán àwọn létí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn túbọ̀ gbájú mọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn ni iṣẹ́ òjíṣẹ́.” Báwo ni àpéjọ àkànṣe ṣe ran ìwọ náà lọ́wọ́?
2. Kí ni àpéjọ àkànṣe wa ti ọdún 2011 dá lé?
2 Àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa gbọ́ ní àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2011 tún máa bọ́ sákòókò gan-an ni. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Sá Di Jèhófà,” a fà á yọ látinú Sáàmù 118:8, 9. Díẹ̀ rèé lára àwọn kókó tá a máa jíròrò: “Bí Jèhófà Ṣe Jẹ́ Odi Agbára Ní Àkókò Ìṣòro,” “Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n lè Fi Abẹ́ Ìyẹ́ Apá Jèhófà Ṣe Ibi Ààbò,” “Jẹ́ Ibi Ààbò Fáwọn Èèyàn Bíi Ti Jèhófà,” “Ẹ̀yin Èwe, Jèhófà Ni Kẹ́ Ẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé!” àti “Jèhófà Fi Párádísè Tẹ̀mí Tá A Wà Ṣe Ibi Ààbò fún Wa.”
3. Báwo la ṣe máa jàǹfààní tó kún rẹ́rẹ́ tá a bá wà ní àpéjọ náà?
3 Ká Lè Jàǹfààní: Tí wọ́n bá ti sọ ọjọ́ tẹ́ ẹ máa ṣe àpéjọ àkànṣe yín, kó o tètè bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ láti wà níbẹ̀, kó o sì pe àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti bá ẹ lọ. Kó lè ṣeé ṣe fún wa láti “so èso pẹ̀lú ìfaradà,” a ní láti fi àwọn ohun tá a gbọ́ sọ́kàn. (Lúùkù 8:15) Torí náà, tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, kó o sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó pàtàkì àti àwọn ìtọ́ni tó o pinnu láti lò nígbèésí ayé rẹ àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lẹ́yìn àpéjọ, kí ìwọ àti ìdílé rẹ jọ jíròrò ohun tẹ́ ẹ kọ́ ní àpéjọ náà, kẹ́ ẹ sì ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà ṣiṣẹ́ lórí ìsọfúnni náà.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fojú sọ́nà fún àpéjọ àkànṣe wa tó ń bọ̀?
4 Bíi ti oúnjẹ aládùn tó ṣara lóore, a ti ronú nípa ohun tó máa ṣe àwọn ará láǹfààní, a sì ti fìfẹ́ ṣètò àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2011. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún ìsapá rẹ láti wà ní àpéjọ náà, kó o sì jàǹfààní látinú ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ èyí tí ẹrú olóòótọ́ ń pèsè láti bọ́ àwọn Kristẹni yó nípa tẹ̀mí.—Mát. 24:45.