Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 13
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 14 ìpínrọ̀ 17 sí 21, àti àpótí tó wà lójú ìwé 149
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 15-19
No. 1: 2 Kíróníkà 15:8-19
No. 2: Ṣé Wíwulẹ̀ Gba Jésù Gbọ́ Ti Tó Láti Rí Ìgbàlà? (td-YR 35D)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Buyì Kún Jèhófà Bá A Ṣe Ń Jọ́sìn Rẹ̀?
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Sọ fún àwọn ará pé kí wọ́n mú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2011 wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.
15 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2011. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ni kó sọ àsọyé yìí. Jíròrò àwọn ohun tó bá ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ yín látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọdún 2011. Ṣàlàyé ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Fún àwọn ará níṣìírí láti máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tá a bá yàn fún wọn, kí wọ́n máa lóhùn sí Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n sì máa fi àwọn àbá tí wọ́n bá rí gbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò.
15 min: “Oúnjẹ Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ọjọ́ tẹ́ ẹ máa lọ sí àpéjọ àkànṣe yín tẹ́ ẹ bá ti mọ̀ ọ́n.